Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Lórí Ìkọ̀sílẹ̀ ati Lórí Ìfẹ́ fun Awọn Ọmọ

Awọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Lórí Ìkọ̀sílẹ̀ ati Lórí Ìfẹ́ fun Awọn Ọmọ

Orí 95

Awọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Lórí Ìkọ̀sílẹ̀ ati Lórí Ìfẹ́ fun Awọn Ọmọ

JESU ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wà loju ọ̀nà wọn sí Jerusalẹmu lati pésẹ̀ si Irekọja 33 C.E. Wọn sọdá Odò Jọdani wọn sì gba ojú ọ̀nà naa tí ó la àgbègbè Peria kọja. Jesu wà ni Peria ní ìwọ̀n ọsẹ diẹ ṣaaju, ṣugbọn lẹhin naa a pè é lọ sí Judia nitori pe Lasaru ọ̀rẹ́ rẹ̀ ńṣàìsàn. Nigba tí ó wà ní Peria, Jesu bá awọn Farisi sọ̀rọ̀ nipa ìkọ̀sílẹ̀, nisinsinyi pẹlu wọn tún mú kókó naa jáde fun àfiyèsí lẹẹkan sii.

Láàárín awọn Farisi ìrònú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni o wà nipa ìkọ̀sílẹ̀. Mose sọ pe obinrin kan ni a lè kọ̀sílẹ̀ nitori ‘ohun àléébù kan níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.’ Awọn kan gbàgbọ́ pe eyi ńtọ́kasí kìkì iwa alaimọ. Ṣugbọn awọn miiran rò pe “ohun àléébù” ní awọn láìfí kéékèèké ninu pẹlu. Nitori naa, lati dan Jesu wò, awọn Farisi beere pe: “Ó ha bófinmu kí ọkunrin kọ aya rẹ̀ silẹ lori ọ̀ràn gbogbo?” Wọn gbagbọ pe ohunkohun ti Jesu ba sọ yoo kó o sínú ìṣòro pẹlu awọn Farisi tí wọn ni ojú ìwòye tí ó yàtọ̀.

Jesu bojuto ibeere naa pẹlu ọgbọ́n ti o pẹtẹri, ko fọ̀rànlọ èrò ẹ̀dá-ènìyàn eyikeyii, ṣugbọn ní títọ́ka padà sí ìṣètò igbeyawo ni ìpilẹ̀ṣẹ̀. “Eyin kò ti kà á,” ni ó beere, “pe ẹni tí ó dá wọn nigba àtètèkọ́ṣe ó dá wọn ti akọ ti abo, Ó sì wipe, ‘Nitori eyi ni ọkunrin yoo ṣe fi bàbá ati ìyá rẹ̀ silẹ, yoo fà mọ́ aya rẹ̀; awọn mejeeji a sì di ara kan.’ Nitori naa wọn kii ṣe meji mọ́ bikoṣe ara kan. Nitori naa ohun tí Ọlọrun bá so ṣọ̀kan, kí eniyan kí ó maṣe yà wọn.”

Jesu fihàn pe ète ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ọlọrun ni ipilẹṣẹ ni pe kí awọn olùjọṣègbéyàwó wà papọ̀, pe kí wọn maṣe gba ìkọ̀sílẹ̀. Bí eyi bá rí bẹẹ, awọn Farisi fèsì pe, “eeṣe tí Mose fi aṣẹ fun wa, wipe, kí a fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fun un, kí á sì kọ̀ ọ́ silẹ?”

“Nitori líle àyà yin ni Mose ṣe jẹ́ fun yin lati maa kọ aya yin silẹ,” ni Jesu dáhùn, “ṣugbọn lati ìgbà àtètèkọ́ṣe wá kò rí bẹẹ.” Bẹẹni, nigba ti Ọlọrun fìdí ọ̀pá-ìdiwọ̀n tootọ múlẹ̀ fun ìgbéyàwó ninu ọgbà Edeni, kò ṣe ìpèsè kankan fun ìkọ̀sílẹ̀.

Jesu nbaa lọ lati sọ fun awọn Farisi pe: “Mo sì wi fun yin, ẹnikẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣe pe nitori àgbèrè [lati inu Giriiki, por·neiʹa], tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ó ṣe panṣaga.” Oun nipa bẹẹ fihàn pe por·neiʹa, tí ó jẹ́ ìwà pálapàla takọtabo ti o lékenkà, ni kìkì ìdí kanṣoṣo tí Ọlọrun fọwọ́sí fun ìkọ̀sílẹ̀.

Ní mimọ pe ìgbéyàwó nilati jẹ́ ìrẹ́pọ̀ wíwà títílọ pẹlu kìkì ìdí yii fun ìkọ̀sílẹ̀, a sun awọn ọmọ-ẹhin lati wipe: “Bí ọ̀ràn ọkunrin bá rí bayii sí aya rẹ̀, kò ṣàǹfààní lati gbé ìyàwó.” Kò sí iyèméjì kankan nibẹ pe ẹnikan tí ó ńgbèrò ìgbéyàwó nilati ronú gidigidi nipa ìwàtítílọ ìdè ìgbéyàwó!

Jesu tẹsiwaju lati sọ̀rọ̀ nipa wiwa ni àpọ́n. Oun ṣalaye pe a bi awọn ọmọdekunrin kan ní ìwẹ̀fà, ti wọn kò sì tipa bẹẹ dáńgájíá fun ìgbéyàwó nitori àìdàgbà nipa ti ara fun ìbálòpọ̀ takọtabo. Awọn miiran ni awọn eniyan ti sọ di ìwẹ̀fà, ní fífi pẹlu ìkà sọ wọn di aláìlágbára ìbálòpọ̀ takọtabo. Nikẹhin, awọn kan tẹ̀ ìfẹ́-ọkàn lati gbéyàwó ati lati gbádùn ìbálòpọ̀ takọtabo rì kí wọn baa lè fi araawọn láìkùsíbìkan fun awọn ohun tí wọn niiṣe pẹlu Ijọba awọn ọ̀run lẹkun-unrẹrẹ sí i. ‘Jẹ́ kí ẹni tí ó lè wá àyè fun [ipò-àpọ́n] wá àyè fun un,’ ni Jesu pari ọrọ rẹ̀.

Awọn eniyan nisinsinyi bẹrẹsii mú awọn ọmọ wọn wá sí ọ̀dọ̀ Jesu. Awọn ọmọ-ẹhin, bí ó ti wù kí ó rí, dá awọn ọmọ naa lẹ́bi pẹlu ìkanra wọn sì gbìyànjú lati lé wọn lọ, láìsí iyèméjì wọn fẹ́ lati daabobo Jesu kuro lọwọ másùnmáwo tí kò pọndandan. Ṣugbọn Jesu wipe: “Ẹ jẹ́ kí awọn ọmọ kekere ki o wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nitori ti iru wọn ni ijọba Ọlọrun. Lóòótọ́ ni mo wí fun yin, Ẹnikẹni tí kò bá gbà ijọba Ọlọrun bí ọmọ kekere, kì yoo lè wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”

Awọn ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n rere wo ni Jesu pèsè níhìn-ín! Lati wọnu Ijọba Ọlọrun, awa gbọdọ ṣàfarawé ìrẹ̀lẹ̀ ati ṣíṣeékọ́lẹ́kọ̀ọ́ awọn ọmọ kéékèèké. Ṣugbọn apẹẹrẹ Jesu tún ṣàkàwé bí ó ti ṣe pàtàkì tó, pàápàá ní pàtàkì fun awọn òbí, lati lò àkókò pẹlu awọn ọmọ wọn. Jesu nisinsinyi fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fun awọn ọmọde nipa gbígbé wọn sí apá rẹ̀ tí ó sì súre fun wọn. Matiu 19:1-15; Deutaronomi 24:1; Luuku 16:18; Maaku 10:1-16; Luuku 18:15-17.

▪ Ojú ìwòye tí o yàtọ̀ síra wo ni awọn Farisi ní lórí ìkọ̀sílẹ̀, bawo ni wọn sì ṣe gbìdánwò lati dán Jesu wò?

▪ Bawo ni Jesu ṣe bójútó ìsapá awọn Farisi lati dán an wò, ki ni o sì fifúnni gẹgẹ bi ìdí kanṣoṣo fun ìkọ̀sílẹ̀?

▪ Eeṣe tí awọn ọmọ-ẹhin Jesu fi sọ pe kò lọ́gbọ́nnínú lati gbéyàwó, ìdámọ̀ràn wo ni Jesu sì pèsè?

▪ Ki ni Jesu fi kọ́ wa nipasẹ awọn ìbálò rẹ̀ pẹlu awọn ọmọde kéékèèké?