Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awọn Òṣìṣẹ́ Ninu Ọgbà Àjàrà

Awọn Òṣìṣẹ́ Ninu Ọgbà Àjàrà

Orí 97

Awọn Òṣìṣẹ́ Ninu Ọgbà Àjàrà

JESU ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pe: “Ọpọlọpọ tí wọn ṣaaju yoo kẹhin, ẹni ikẹhin yoo sì ṣaaju.” Nisinsinyi oun ṣàkàwé eyi nipa sísọ ìtàn kan. “Ijọba awọn ọrun,” ni oun bẹ̀rẹ̀, “dabi ọkunrin kan, baale-ile kan, ẹni tí ó jádelọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀ lati háyà awọn òṣìṣẹ́ fun ọgbà àjàrà rẹ̀.”

Jesu nbaa lọ pe: “Nigba ti [baale-ile naa] ti fohùnṣọ̀kan pẹlu awọn òṣìṣẹ́ naa fun owó dinari kan fun ọjọ kan, ó rán wọn jade sínú ọgbà àjàrà rẹ̀. Ní jíjádelọ ní nǹkan bii wakati kẹta, ó rí awọn miiran tí wọn ńdúró láìrí iṣẹ́ ṣe ní ibi ọjà; awọn wọnyi ni oun sì wí fun, ‘Ẹyin pẹlu, ẹ lọ sínú ọgbà àjàrà, ohun yoowu tí ó bá sì bá ìdájọ́ òdodo mu emi yoo fifun yin.’ Nitori naa wọn lọ. Ó sì tún jádelọ ní nǹkan bii wakati kẹfa ati ẹkẹsan-an ó sì ṣe bakan-naa. Nikẹhin, ní nǹkan bii wakati kọkanla ó jádelọ ó sì rí awọn miiran tí wọn dúró, ó sì wí fun wọn pe, ‘Eeṣe tí ẹyin fi dúró níhìn-ín ní gbogbo ọjọ láìrí iṣẹ́ ṣe?’ Wọn wi fun un pe, ‘Nitori ẹnikankan kò háyà wa.’ Ó wí fun wọn pe, ‘Ẹyin pẹlu ẹ lọ sínú ọgbà àjàrà.’”

Baale ile naa, tabi ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà naa, ni Jehofa Ọlọrun, ọgbà àjàrà naa sì orílẹ̀-èdè Isirẹli. Awọn òṣìṣẹ́ ninu ọgbà àjàrà naa jẹ́ awọn eniyan tí a múwá sínú majẹmu Ofin; niti pàtó wọn jẹ́ awọn Juu wọnni tí ńgbé ní awọn ọjọ awọn apọsiteli. Àdéhùn owó-ọ̀yà ni a nṣe pẹlu kìkì awọn òṣìṣẹ́ tí ńlo ọjọ ní kíkún. Owó-ọ̀yà naa jẹ́ dinari kan fun iṣẹ́ ọjọ́ kan. Niwọn bi “wakati kẹta” ti jẹ́ agogo mẹsan-an òwúrọ̀, awọn tí a pè ní wakati kẹta, kẹfa, kẹsan-an, ati ikọkanla ṣiṣẹ́, fun kìkì wakati mẹsan-an, mẹfa, mẹta, ati ẹyọkan.

Awọn òṣìṣẹ́ ti o lo wakati mejila, tabi odidi ọjọ kan, dúró fún awọn aṣaaju Juu tí ọwọ́ wọn ńdí nigba gbogbo ninu iṣẹ́ ti o jẹmọ ìsìn. Wọn kò dabi awọn ọmọ-ẹhin Jesu, awọn tí ó jẹ́ pe, fun eyi ti o pọ julọ ninu igbesi-aye wọn, wọn ńṣiṣẹ́ apẹja tabi awọn iṣẹ́ àjókòótì miiran fun oúnjẹ òòjọ́. Ìgbà ìkórè 29 C.E. ni “baale ile” naa ṣẹ̀ṣẹ̀ ran Jesu Kristi lati kó awọn wọnyi jọ lati jẹ́ ọmọ-ẹhin rẹ̀. Wọn tipa bayii di “ẹni ikẹhin,” tabi awọn òṣìṣẹ́ ti o lo wakati mọkanla ninu ọgbà àjàrà naa.

Nikẹhin, ọjọ iṣẹ́ afàmìṣàpẹẹrẹ naa dópin pẹlu ikú Jesu, àkókò sì dé lati sanwó fun awọn òṣìṣẹ́ naa. Òfin ìdiwọ̀n àràmàǹdà naa lati kọkọ sanwò fun ẹni ti o kẹhin ni a tẹle, gẹgẹ bi a ti ṣalaye pe: “Nigba ti ó sì di alẹ́, ọ̀gá ti o ni ọgba àjàrà naa wi fun ọkunrin olùbójútó rẹ̀, ‘Pe awọn òṣìṣẹ́ naa kí o sì san owó-ọ̀yà wọn fun wọn, bẹrẹ lati ọ̀dọ̀ ẹni ikẹhin lọ dé ọ̀dọ̀ ẹni iṣaaju.’ Nigba ti awọn ọkunrin ti wakati kọkanla dé, olukuluku wọn gba owó dinari kan. Nitori naa, nigba ti awọn ti iṣaaju dé, wọn rò pe awọn yoo gba ju bẹẹ lọ; ṣugbọn awọn pẹlu gba owó-iṣẹ́ ni iye dinari kan. Bí wọn ti gbà á tán wọn bẹrẹsii kùn sí baale ile naa wọn sì wipe, ‘Awọn wọnyi tí wọn kẹhin ṣe iṣẹ́ wakati kan; sibẹ ó mú wọn bá wa dọ́gba awa tí a faradà ẹrù ìnira ọjọ́ naa ati ooru gbígbóná!’ Ṣugbọn ní ìfèsìpadà o sọ fun ọ̀kan ninu wọn pe, ‘Àwé, emi kò ṣe àìtọ́ kankan sí ọ. Iwọ fohùnṣọ̀kan pẹlu mi fun owó dinari kan, iwọ kò ṣe bẹẹ bí? Gba eyi tí ó jẹ́ tìrẹ kí o sì maa lọ. Mo fẹ́ lati fún ẹni ikẹhin yii bakan naa bíi tìrẹ. Kò ha bá òfin mu fun mi lati ṣe ohun tí mo fẹ́ pẹlu awọn nǹkan tí wọn jẹ́ temi? Tabi ojú rẹ ha di burúkú nitori pe mo jẹ́ ẹni daradara?’” Ní ipari ọrọ rẹ̀, Jesu ṣàtúnsọ kókó kan tí ó ti sọ ni iṣaaju pe: “Ní ọ̀nà yii awọn ẹni ikẹhin yoo di ẹni iṣaaju, awọn ẹni iṣaaju yoo sì dì ẹni ikẹhin.”

Gbígba owó dinari ṣẹlẹ, kii ṣe nigba ikú Jesu, bikoṣe ní Pẹntikọsti 33 C.E., nigba ti Kristi, “ọkunrin olùbójútó” naa, tú ẹmi mímọ́ jáde sórí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Awọn ọmọ-ẹhin Jesu wọnyi dabi “ẹni ikẹhin,” tabi awọn òṣìṣẹ́, ti o ṣiṣẹ fun wakati mọkanla. Owó dinari naa kò dúró fún ẹ̀bùn ẹmi mimọ fúnraarẹ̀. Owó dinari naa jẹ́ ohun kan tí ó wà fun awọn ọmọ-ẹhin lati lò níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé. Ó jẹ́ ohun ìgbẹ́mìíró fun wọn, iye ainipẹkun wọn. Ó jẹ́ àǹfààní jíjẹ́ mẹmba Isirẹli tẹmi, tí a fi òróró yàn lati waasu nipa Ijọba Ọlọrun.

Laipẹ awọn wọnni tí a háyà lákọ̀ọ́kọ́ ṣàkíyèsí pe awọn ọmọ-ẹhin Jesu ni a ti sanwó fun, wọn sì rí wọn tí wọn ńlò dinari afàmìṣàpẹẹrẹ naa. Ṣugbọn wọn ńfẹ́ pupọ sii ju ẹmi mimọ ati awọn àǹfààní Ijọba tí ó sopọ̀ mọ́ ọn. Kíkùn ati àtakò wọn jẹ́ inúnibíni sí awọn ọmọ-ẹhin Kristi, awọn òṣìṣẹ́ “ẹni-ikẹhin” ninu ọgbà àjàrà naa.

Ìmúṣẹ́ ọ̀rúndún kìn-ínní yẹn ha jẹ́ kìkì ìmúṣẹ àkàwé Jesu bí? Bẹẹkọ, àwùjọ awọn àlùfáà Kristẹndọmu ní ọ̀rúndún ogún yii, nítorí awọn ipò ati ẹrù-iṣẹ́ wọn, ti jẹ́ “ẹni iṣaaju” tí a háyà fun iṣẹ́ ninu ọgbà àjàrà afàmìṣàpẹẹrẹ Ọlọrun. Wọn ka awọn oniwaasu olùṣèyàsímímọ́ tí o darapọ mọ́ Watch Tower Bible and Tract Society sí “ẹni ikẹhin” lati ní iṣẹ́ àyànfúnni eyikeyii tí ó lẹ́sẹ̀nílẹ̀ ninu iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun. Ṣugbọn, niti tootọ, awọn wọnyi gan-an, tí àwùjọ awọn àlùfáà tẹ́ḿbẹ́lú, ni wọn rí dinari gbà—ọlá ṣíṣiṣẹ́sìn gẹgẹ bi awọn ikọ̀ ẹni àmì-òróró ti Ijọba Ọlọrun ní ọrun. Matiu 19:30–20:16, NW.

▪ Ki ni ọgbà àjàrà naa dúró fún? Awọn wo sì ẹni ti ó ni ọgbà àjàrà naa ati awọn òṣìṣẹ́ ti o ṣiṣẹ fun wákàtí méjìlá ati fun wákàtí kan dúró fún?

▪ Nigba wo ni ọjọ́ iṣẹ́ ìṣàpẹẹrẹ naa dópin, nigba wo sì ni a san owó naa?

▪ Ki ni sísan dinari naa dúró fún?