Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awọn Ọgbà-àgùtàn ati Olùṣọ́-àgùtàn

Awọn Ọgbà-àgùtàn ati Olùṣọ́-àgùtàn

Orí 80

Awọn Ọgbà-àgùtàn ati Olùṣọ́-àgùtàn

JESU wá sí Jerusalẹmu fun Àjọ-àríyá Ìyàsímímọ́, tabi Hanuka, àjọ-àríyá kan tí ó ńṣe ayẹyẹ àtúnyàsímímọ́ tẹmpili fun Jehofa. Ní 168 B.C.E., ní nǹkan bii 200 ọdun ṣaaju, Antiochus IV Epiphanes ti ṣẹ́gun Jerusalẹmu tí ó sì ti sọ tẹmpili naa ati pẹpẹ rẹ̀ di alaimọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ọdun mẹta lẹhin naa Jerusalẹmu ni a ṣẹ́gun tí a sì tún tẹmpili naa yàsímímọ́ lẹẹkan sí i. Lẹhin naa, ayẹyẹ ìtúnyàsímímọ́ ọdọọdun ni a ṣe.

Àjọ-àríyá Ìyàsímímọ́ yii ṣẹlẹ̀ ní Chislev 25, oṣu awọn Juu tí ó ṣe rẹ́gí pẹlu apá ikẹhin November ati apá àkọ́kọ́ December ninu kalẹnda wa òde-òní. Nipa bayii, kìkì ohun tí ó fi diẹ lé ní ọgọrun-un ọjọ́ ni ó ṣẹ́kù títí di ìgbà Àjọ-ìrékọjá ṣíṣepàtàkì naa ti 33 C.E. Nitori pe ó jẹ́ àsìkò ojú ọjọ́ títútù, apọsiteli Johanu pè é ní “ìgbà òtútù.”

Jesu nisinsinyi lò àkàwé kan ninu eyi tí ó ti mẹ́nubà awọn ọgbà-àgùtàn mẹta ati ipa-iṣẹ́ rẹ̀ gẹgẹ bi Olùṣọ́-àgùtàn Rere naa. Ọgbà-àgùtàn àkọ́kọ́ tí oun sọ̀rọ̀ nipa rẹ̀ ni a fihàn yàtọ̀ gẹgẹ bi ìṣètò majẹmu Òfin Mose. Òfin naa ṣiṣẹ́ gẹgẹ bi ògiri kan, tí ó ya awọn Juu sọ́tọ̀ kuro ninu awọn àṣà tí ńsọnidìbàjẹ́ ti awọn enìyàn wọnni tí kò sí ninu majẹmu àkànṣe yii pẹlu Ọlọrun. Jesu ṣàlàyé pe: “Lóòótọ́ dajudaju ni mo wí fun yin, Ẹni tí kò bá gba ẹnu ilẹ̀kùn wọ inú ọgbà-àgùtàn ṣugbọn tí ó gun òkè gba ibòmíràn kan, ẹni yẹn ni olè ati olùpiyẹ́. Ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ẹnu ilẹ̀kùn wọlé ni olùṣọ́ awọn àgùtàn.”

Awọn miiran ti wá tí wọn ti sọ pe awọn jẹ́ Mesaya naa, tabi Kristi, ṣugbọn wọn kii ṣe olùṣọ́-àgùtàn tootọ naa nipa awọn ẹni tí Jesu nbaa lọ lati sọ pe: “Olùṣọ́ naa ṣílẹ̀kùn fun ẹni yii, awọn àgùtàn sì fetisilẹ sí ohùn rẹ̀, oun sì pe awọn àgùtàn tirẹ̀ ní orukọ ó sì dà wọn jáde. . . . Wọn kì yoo tọ àjèjì lẹ́hìn lọnakọna ṣugbọn wọn yoo sá kuro lọ́dọ̀ rẹ̀, nitori wọn kò mọ ohùn awọn àjèjì.”

“Olùṣọ́nà” ọgbà-àgùtàn àkọ́kọ́ naa ni Johanu Arinibọmi. Gẹgẹ bi olùṣọ́nà, Johanu ‘ṣílẹ̀kùn fun’ Jesu nipa fifi i hàn yatọ fun awọn àgùtàn ìṣàpẹẹrẹ wọnni tí oun yoo dà jáde lọ sí pápá. Awọn àgùtàn wọnyi tí Jesu pè ní orukọ tí ó sì ṣamọ̀nà jáde ni a gbà lẹhin naa sinu agbo-àgùtàn miiran, gẹgẹ bi oun ti ṣàlàyé pe: “Lóòótọ́ dajudaju mo wí fun yin, emi ni ilẹ̀kùn awọn àgùtàn,” iyẹn ni pe, ilẹ̀kùn ọgbà-àgùtàn titun kan. Nigba ti Jesu dá majẹmu titun naa silẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tí ó sì tú ẹ̀mí mímọ́ lati ọ̀run jáde sórí wọn ní Pẹntikọsti tí ó tẹle e, a gbà wọn sínú ọgbà-àgùtàn titun yii.

Ní ṣíṣàlàyé ipa-iṣẹ́ rẹ̀ siwaju sí i, Jesu wipe: “Emi ni ilẹ̀kùn; ẹni yoowu tí ó bá gbà ọ̀dọ̀ mi wọlé ni a ó gbàlà, yoo sì wọlé yoo sì jáde yoo sì rí pápá koríko. . . . Emi ti wá kí wọn baa lè ní ìyè kí wọn sì ní in ní ọpọlọpọ. . . . Emi ni olùṣọ́-àgùtàn rere, emi sì mọ awọn àgùtàn mi awọn àgùtàn mi sì mọ̀ mí, gan-an gẹgẹ bi Baba ti mọ̀ mi tí emi sì mọ Baba; emi sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nitori awọn àgùtàn.”

Láìpẹ́ sí àkókò naa, Jesu ti tu awọn ọmọlẹhin rẹ̀ nínú, ní wiwi pe: “Má bẹ̀rù, agbo kekere; nitori dídùn inú Baba yin ni lati fi ijọba fun yin.” Agbo kekere yii, tí iye wọn nikẹhin wa jẹ́ 144,000, wá sínú ọgbà-àgùtàn titun, tabi ikeji yii. Ṣugbọn Jesu nbaa lọ lati maa ṣàlàyé pe: “Emi sì ní awọn àgùtàn miiran, tí kii ṣe ti ọgbà-ẹran yii; awọn wọnni pẹlu ni emi gbọdọ múwá, wọn yoo sì fetisilẹ sí ohùn mi, wọn yoo sì di agbo kan, olùṣọ́-àgùtàn kan.”

Niwọn bi “awọn àgùtàn miiran” naa “kìí tií ṣe ti ọgbà-ẹran yii,” wọn gbọdọ jẹ́ ti ọgbà-ẹran miiran, ẹkẹta kan. Awọn ọgbà-ẹran meji tí ó kẹhin wọnyi tabi awọn ọgbà agbo-ẹran àgùtàn, ní awọn kádàrá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. “Agbo kekere” naa tí ó wà ninu ọgbà-ẹran kan yoo jọba pẹlu Kristi ní ọ̀run, tí “awọn àgùtàn miiran” tí nbẹ ninu ọgbà-ẹran keji yoo gbé ninu Paradise ilẹ̀-ayé. Sibẹ, láìka wíwà tí wọn wà ninu awọn ọgbà-ẹran meji sí, awọn àgùtàn naa kò ní owú kankan, bẹẹ sì ni wọn kò nímọ̀lára pe a ya wọn sọtọ, nitori gẹgẹ bi Jesu ti wí, wọn “di agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́-àgùtàn kan.”

Olùṣọ́-àgùtàn Rere naa, Jesu Kristi, fi pẹlu ìfẹ́-inú fi iwalaaye rẹ̀ fun awọn ọgbà-ẹran àgùtàn mejeeji yii. “Mo fi i lélẹ̀ nipa àtinúdá araami,” ni oun wí. “Mo ní ọlá-àṣẹ lati fi i lélẹ̀, mo sì ní ọlá-àṣẹ lati tún rí i gbà. Aṣẹ lórí eyi ni mo gbà lati ọ̀dọ̀ Baba mi.” Nigba ti Jesu sọ eyi, ìyapa kan ṣẹlẹ̀ láàárín awọn Juu.

Ọpọlọpọ ninu àwùjọ naa sọ pe: “Ó ní ẹ̀mí-èṣù ó sì ti ya wèrè. Eeṣe tí ẹyin fi nfetisilẹ sí i?” Ṣugbọn awọn miiran dáhùnpadà pe: “Iwọnyi kii ṣe awọn ọ̀rọ̀ ọkunrin ẹlẹmii-eṣu kan.” Lẹhin naa, ní títọ́ka lọna tí ó hàn gbangba sí oṣu melookan sẹhin nigba tí ó mú ọkunrin naa tí a bí ní afọ́jú láradá, wọn fikun un pe: “Ẹ̀mí-èṣù kan kò lè la ojú awọn afọ́jú ènìyàn, ó lè ṣe bẹẹ bí?” Johanu 10:1-22; 9:1-7; Luuku 12:32; Iṣipaya 14:1, 3; 21:3, 4; Saamu 37:29, NW.

▪ Ki ni Àjọ-àríyá Ìyàsímímọ́, nigba wo ni a sì ńṣe ayẹyẹ rẹ̀?

▪ Ki ni ọgbà-àgùtàn àkọ́kọ́ jẹ́, ta sì ni olùṣọ́nà rẹ̀?

▪ Bawo ni olùṣọ́nà naa ṣe ṣílẹ̀kùn fun Olùṣọ́-àgùtàn, inú ki ni a sì gba awọn àgùtàn naa sí lẹhin naa?

▪ Awọn wo ni wọn parapọ̀ jẹ́ awọn ọgbà-ẹran meji ti Olùṣọ́-àgùtàn Rere naa, agbo meloo ni wọn sì dà?