Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awọn Ọmọ-ẹhin Ńjiyàn bí Ikú Jesu ti Ńsúnmọ́lé

Awọn Ọmọ-ẹhin Ńjiyàn bí Ikú Jesu ti Ńsúnmọ́lé

Orí 98

Awọn Ọmọ-ẹhin Ńjiyàn bí Ikú Jesu ti Ńsúnmọ́lé

JESU ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wà nítòsí Odò Jọdani, níbi tí wọn ti sọdá lati àgbègbè Peria sí Judia. Ọpọ awọn miiran ńrìnrìn àjò pẹlu wọn lọ sí Irekọja 33 C.E., eyi tí ó kù kìkì nǹkan bii ọsẹ kan.

Jesu ńrìn lọ niwaju awọn ọmọ-ẹhin, wọn sì ṣe kàyéfì sí ìpinnu aláìṣojo rẹ̀. Rántí pe ní awọn ọsẹ diẹ ṣaaju nigba ti Lasaru kú tí Jesu sì ńfẹ́ lati lọ lati Peria sí Judia, Tomasi fun awọn yooku ní ìṣírí pe: “Ẹ jẹ́ kí awa naa lọ, kí a lè bá a kú pẹlu.” Rántí pẹlu pe lẹhin tí Jesu jí Lasaru dìde, Sanhẹdrin wéwèé lati pa Jesu. Abájọ tí awọn ọmọ-ẹhin fi bẹ̀rù gidigidi bí wọn ti tún ńpadà wọ Judia nisinsinyi.

Lati múra wọn silẹ fun ohun tí nbẹ niwaju, Jesu pe awọn 12 naa síbi ìkọ̀kọ̀ kan ó sì sọ fun wọn pe: “Awa niyii nihin-in, ti a nlọ siwaju sí Jerusalẹmu, a o sì fi Ọmọkunrin ènìyàn lé awọn olórí alufaa ati awọn akọwe lọwọ, wọn yoo sì dá a lẹ́bi ikú wọn yoo sì fi i lé awọn eniyan orilẹ-ede lọwọ, wọn yoo sì fi i ṣe yẹ̀yẹ́, wọn yoo sì tutọ́ sí i lára wọn yoo sì nà-án ní pàṣán wọn yoo sì pa á ṣugbọn ọjọ mẹta lẹhin naa oun yoo dide.”

Eyi ni ìgbà kẹta ní awọn oṣu lọọlọọ tí Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nipa ikú ati ajinde rẹ̀. Ani bí ó tilẹ jẹ́ pe wọn fetisilẹ sí i, wọn kò mòye rẹ̀. Boya nitori pe wọn gbàgbọ́ ninu ìmúpadàbọ̀ ijọba Isirẹli sórí ilẹ̀-ayé, tí wọn sì ńwo iwájú fun gbígbádùn ògo ati ọlá ninu ijọba kan lórí ilẹ̀-ayé pẹlu Kristi.

Lára awọn arìnrìn àjò tí wọn ńlọ fun Irekọja naa ni Salome wà, iya apọsiteli Jakọbu ati Johanu. Jesu ti pe awọn ọkunrin wọnyi ní “Awọn Ọmọkunrin Ààrá” (NW), láìsí iyèméjì nitori ìhùwàsí wọn amúbíiná. Fun àkókò kan awọn meji wọnyi ti lépa lati di ẹni yíyọrí ọlá ninu Ijọba Kristi, wọn sì ti sọ ìfẹ́-ọkàn wọn di mímọ̀ fun iya wọn. Obinrin naa tọ Jesu wá nisinsinyi nitori tiwọn, ó tẹríba niwaju rẹ̀, ó sì beere fun ojúrere kan.

“Ki ni iwọ ńfẹ́?” ni Jesu beere.

Obinrin naa dáhùnpadà pe: “Ṣeleri pe kí awọn ọmọkunrin mi mejeeji wọnyi lè jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ ati ọ̀kan ní ọwọ́ òsì rẹ, ninu ijọba rẹ.”

Ní mímọ̀ orísun ibeere naa, Jesu sọ fun Jakọbu ati Johanu pe: “Ẹyin ọkunrin wọnyi kò mọ̀ ohun tí ẹyin nbeere fun. Ẹyin ha lè mu aago tí emi maa tóó mu bí?”

“Awa lè mú un,” ni wọn dahun. Àní bí ó tilẹ jẹ́ pe Jesu ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fun wọn pe oun dojúkọ inúnibíni bíbanilẹ́rù ati ìfìyà ikú jẹni níkẹhìn, bí ó ti hàn gbangba wọn kò mòye rẹ̀ pe eyi ni ohun tí oun nílọ́kàn nipa “aago” naa tí oun yoo mu láìpẹ́.

Bí ó tilẹ rí bẹẹ, Jesu sọ fun wọn pe: “Nitootọ ẹyin yoo mu aago mi, ṣugbọn jíjókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi ati ní ọwọ́ òsì mi yii kii ṣe temi lati fifúnni, ṣugbọn o jẹ ti awọn wọnni tí a ti pèsè rẹ̀ silẹ fun lati ọ̀dọ̀ Baba mi.”

Nigba tí ó ṣe awọn apọsiteli mẹ́wàá yooku mọ̀ nipa ohun tí Jakọbu ati Johanu ti beere, inú sì bí wọn. Boya ohùn Jakọbu ati Johanu ti ròkè ninu ìjiyàn iṣaaju láàárín awọn apọsiteli nipa ẹni tí ó tobi julọ. Ohun tí wọn beere fun nisinsinyi fihan pe wọn kò tíì fi ìmọ̀ràn tí Jesu fun wọn lórí kókó yii silo. Lọna tí ó baninínújẹ́, ìfẹ́ wọn fun ipo olori ṣì lágbára sibẹsibẹ.

Nitori naa lati bójútó àríyànjiyàn tí ó ṣẹlẹ kẹhin yii ati kùnrùngbùn tí ó ti dá sílẹ̀, Jesu pe awọn 12 naa papọ̀. Ní fífún wọn nímọ̀ràn tìfẹ́tìfẹ́, ó wipe: “Ẹyin mọ̀ pe awọn alakooso awọn orilẹ-ede a maa jẹgaba lórí wọn awọn eniyan ńlá a sì maa fagbára lo ọlá-àṣẹ lori wọn. Eyi kò rí bẹẹ láàárín yin; ṣugbọn ẹni yoowu tí ó bá fẹ́ di ẹni nla laaarin yin gbọdọ jẹ iranṣẹ yin, ẹni yoowu tí ó bá sì fẹ́ lati jẹ ẹni ekinni laaarin yin gbọdọ jẹ ẹru yin.”

Jesu ti fi apẹẹrẹ tí ó yẹ kí wọn ṣàfarawé lélẹ̀, gẹgẹ bi oun ti ṣalaye: “Gan-an gẹgẹ bi Ọmọkunrin eniyan ti wá kii ṣe kí a maa ṣeranṣẹ fun un, bikoṣe lati ṣeranṣẹ, ati lati fi ọkàn rẹ̀ funni ni ìràpadà ni pàṣípààrọ̀ fun ọpọlọpọ.” Kii ṣe kìkì pe Jesu ti ṣèránṣẹ́ fun ire awọn ẹlomiran nikan ni ṣugbọn oun yoo ṣe bẹẹ títí dé oju iku fun aráyé! Awọn ọmọ-ẹhin nílò ìtẹ̀sí kan naa bii ti Kristi yẹn ti fífẹ́ lati ṣiṣẹ́sìn dípò kí a ṣiṣẹ́sìn wọn ati lati jẹ́ ẹni kíkéré jù dípò wíwà ní ipò olórí. Matiu 20:17-28; Maaku 3:17; 9:33-37; 10:32-45; Luuku 18:31-34; Johanu 11:16.

▪ Eeṣe tí awọn ọmọ-ẹhin fi bẹru gidigidi nisinsinyi?

▪ Bawo ni Jesu ṣe múra awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ silẹ fun ohun tí nbẹ niwaju?

▪ Ibeere wo ni a fi síwájú Jesu, bawo ni ó sì ṣe kàn awọn apọsiteli yooku?

▪ Bawo ni Jesu ṣe bójútó ìṣòro naa tí ó wà láàárin awọn apọsiteli rẹ̀?