Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awọn Ọmọ-ẹhin Jesu Akọkọ

Awọn Ọmọ-ẹhin Jesu Akọkọ

Orí 14

Awọn Ọmọ-ẹhin Jesu Akọkọ

LẸHIN 40 ọjọ́ ninu aginju, Jesu pada wá sọdọ Johanu, ti o ti baptisi rẹ̀. O farahan gbangba pe, nigba ti Jesu nsunmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, Johanu na ọwọ́ sí i ó sì ṣe sáàfúlà fun awọn ti o wà nibẹ pe: “Wòó, Ọ̀dọ́ agutan Ọlọrun, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ! Eyi ni ẹni tí mo ti wi pe, ọkunrin kan nbọ wá lẹhin mi, ẹni tí ó pọ̀ jù mi lọ: nitori tí ó ti wà ṣiwaju mi.” Bi o tilẹ jẹ pe Johanu ju Jesu mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lọ lọ́jọ́ orí, Johanu mọ̀ pe Jesu ti wà ṣiwaju rẹ̀ gẹgẹ bi ẹni ẹ̀mí ní ọ̀run.

Sibẹ, ní ọsẹ diẹ ṣiwaju, nigba ti Jesu wá fun baptisi, o farahan gbangba pe Johanu kò mọ́ daju pe Jesu ni yoo jẹ́ Mesaya naa. “Emi kò sì mọ̀ ọ́n,” ni Johanu jẹ́wọ́sọ, “ṣugbọn ki a lè fi i hàn fun Isirẹli, nitori naa ni emi ṣe wá tí mo nfi omi baptisi.”

Johanu tẹsiwaju lati ṣalaye fun awọn olùgbọ́ rẹ̀ ohun ti o ṣẹlẹ nigba ti oun baptisi Jesu: “Mo rí ẹmi sọkalẹ lati ọrun wá bí àdàbà, ó sì bà lé e. Emi kò sì mọ̀ ọ́n: ṣugbọn ẹni tí ó rán mi wá, lati fi omi baptisi, oun naa ni o wí fun mi pe, Lori ẹni tí iwọ bá rí, ti Ẹmi sọkalẹ sí, tí ó sì bà lé e, oun naa ni ẹni ti nfi Ẹmi Mimọ baptisi. Emi sì ti rí i, emi sì ti njẹrii pe, Eyi ni Ọmọ Ọlọrun.”

Ni ọjọ ti o tẹle e Johanu duro pẹlu meji lára awọn ọmọ ẹhin rẹ̀. Lẹẹkan sii, bi Jesu ti sunmọ ọn, o wipe: “Wòó Ọ̀dọ́ agutan Ọlọrun!” Lẹhin eyi, awọn ọmọ ẹhin Johanu Arinibọmi meji wọnyi tẹle Jesu. Ọkan ninu wọn ni Anderu, ti o sì daju gbangba pe ekeji ni ẹni naa gan-an ti o ṣe akọsilẹ awọn ohun wọnyi, ẹni ti a tún npe ni Johanu pẹlu. Johanu yii, ni ibamu pẹlu awọn itọkafihan, tún jẹ́ mọ̀lẹ́bí Jesu, o hàn gbangba pe o jẹ́ ọmọkunrin arabinrin Maria, Salome.

Ni yiyipada tí ó sì rí Anderu ati Johanu ti ntẹle e lẹhin, Jesu beere pe: “Ki ni ẹyin ńwá?”

“Rabi,” ni wọn beere, “nibo ni iwọ ngbe?”

“Ẹ wá wòó,” ni Jesu dahun.

O jẹ́ nǹkan bii aago mẹrin ọ̀sán, Anderu ati Johanu sì wà pẹlu Jesu fun iyoku ọjọ́ naa. Lẹhin naa a ru Anderu lọkan soke gidigidi debi ti oun fi yárakánkán lọ wá arakunrin rẹ̀, ẹni ti a npe ni Peteru. “Awa ti ri Mesaya,” ni oun sọ fun un. Ó sì mú Peteru lọ sọdọ Jesu. Boya ni akoko kan naa ni Johanu rí arakunrin rẹ̀ Jakọbu tí ó sì mú un tọ Jesu wá; sibẹ, bi o ti jẹ́ àṣà rẹ̀, Johanu kò mẹnukan isọfunni yii nipa ara rẹ̀ ninu akọsilẹ Ihinrere rẹ̀.

Ni ọjọ ti o tẹle e, Jesu rí Filipi, ẹni ti o wá lati Bẹtisaida, ilu kan naa ti Anderu ati Peteru ti wá ni ipilẹṣẹ. Ó késí i pe: “Maa tọ̀ mí lẹhin.”

Nigba naa ni Filipi rí Nataniẹli, ẹni ti a tun npe ni Batolomiu, ó sì wipe: “Awa ti ri ẹni tí Mose ninu òfin, ati awọn wolii ti kọwe rẹ̀, Jesu ti Nasarẹti, ọmọ Josẹfu.” Nataniẹli nṣe iyemeji. “Ohun rere kan ha lè ti Nasarẹti jade?” ni oun beere.

“Wá wòó,” ni Filipi rọ̀ ọ́. Nigba ti wọn nbọwa sọdọ Jesu, Jesu wí nipa Nataniẹli pe: “Wòó, ọmọ Isirẹli nitootọ, ninu ẹni tí ẹ̀tàn kò sí!”

“Nibo ni iwọ ti mọ̀ mí?” ni Nataniẹli beere.

“Kí Filipi tó pè ọ́, nigba ti iwọ wà labẹ igi ọ̀pọ̀tọ́, mo ti rí ọ,” ni Jesu dahunpada.

Kayefi gbáà ni o jẹ́ fun Nataniẹli. “Rabi [ti o tumọsi Olukọ], iwọ ni Ọmọ Ọlọrun, iwọ ni Ọba Isirẹli,” ni oun sọ.

“Nitori mo wi fun ọ pe, mo rí ọ labẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ ni iwọ ṣe gbàgbọ́?” ni Jesu beere. “Iwọ yoo rí ohun ti o pọ̀ ju iwọnyi lọ.” Nigba naa ni oun ṣeleri pe: “Loootọ, loootọ ni mo wi fun yin, Ẹyin yoo rí ọrun ṣi silẹ, awọn angẹli Ọlọrun yoo sì maa gòkè, wọn yoo sì maa sọkalẹ sori Ọmọ eniyan.”

Kété lẹhin eyi, Jesu, pẹlu awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí, fi Afonifoji Jọdani silẹ wọn sì rin irin ajo lọ sí Galili. Johanu 1:29-51.

▪ Awọn wo ni ọmọ ẹhin Jesu akọ́kọ́?

▪ Bawo ni a ṣe mú Peteru ati boya Jakọbu pẹlu, mọ Jesu?

▪ Ki ni o fun Nataniẹli ni idaniloju pe Jesu ni Ọmọkunrin Ọlọrun?