Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awọn Agbéraga ati Awọn Onirẹlẹ

Awọn Agbéraga ati Awọn Onirẹlẹ

Orí 39

Awọn Agbéraga ati Awọn Onirẹlẹ

LẸHIN mimẹnukan awọn ìwà-ẹ̀yẹ Johanu Arinibọmi, Jesu yí àfiyèsí sí awọn ènìyàn agbéraga, tí kò duro sojukan tí wọn yí i ka. “Ìran-ènìyàn yii,” ni oun polongo, “dabi awọn ọmọ kéékèèké tí wọn jókòó ní ibi ọjà tí wọn ké jáde sí awọn alájùmọ̀-ṣeré wọn, wipe, ‘Awa fọn fèrè fun yin, ṣugbọn ẹyin kò jó; awa pohùnréré ẹkún, ṣugbọn ẹyin kò lu araayin ninu ẹ̀dùn-ọkàn.’”

Ki ni Jesu ní lọ́kàn? Oun ṣàlàyé: “Johanu wá kò jẹ bẹẹ ni kò sì mu, sibẹ awọn ènìyàn wipe, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù’; Ọmọkunrin ènìyàn wá ó ńjẹ ó sì ńmu, sibẹ awọn ènìyàn wipe, ‘Wòó! Alájẹkì ènìyàn tí ó sì fi araarẹ̀ fun mímu ọtí waini, ọ̀rẹ́ awọn agbowó-òde ati awọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’”

Ó ṣòro lati tẹ́ awọn ènìyàn naa lọ́rùn. Ohunkohun kò wù wọn. Johanu ti gbé igbesi-aye ìfìgbádùn du ara-ẹni ti ìsẹ́ra ẹni gẹgẹ bi Nasiri kan, ní ìbáramu pẹlu ipolongo angẹli naa pe “kò gbọdọ mu ọtí waini ati ọtí líle rárá.” Sibẹ awọn ènìyàn naa sọ pe oun ni ẹ̀mí èṣù. Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, Jesu gbé bí ènìyàn eyikeyii miiran, láìfi ìfìgbádùn du ara-ẹni ṣèwàhù lọnakọna, sibẹ wọn fẹ̀sùn kàn án pe o jẹ alaṣeju.

Ẹ wo bi o ṣe ṣoro lati wú awọn eniyan naa lori tó! Wọn dabi awọn alájùmọ̀ ṣeré, tí awọn kan lára wọn kọ̀ lati dáhùnpadà pẹlu ijó nigba ti awọn ọmọde yooku ńfọn fèrè tabi pẹlu ẹ̀dùn ọkàn nigba ti awọn ẹlẹgbẹ́ wọn pohùnréré ẹkún. Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu wipe: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nipa awọn iṣẹ́ rẹ̀.” Bẹẹni, ẹ̀rí naa—awọn iṣẹ́—mú kí ó ṣe kedere pe awọn ẹ̀sùn lòdìsí Johanu ati Jesu jẹ́ èké.

Jesu nbaa lọ lati yà awọn ìlú-ńlá mẹta naa Korasini, Bẹtisaida, ati Kapanaomu sọtọ fun ibawi, níbi tí oun ti ṣe pupọ julọ lara awọn iṣẹ alágbára rẹ̀. Bí oun bá ti ṣe awọn iṣẹ́ wọnni ní ìlú Foẹniṣia ti Tire ati Sidoni, Jesu wipe, awọn ìlú wọnyi ìbá ti ronúpìwàdà ninu aṣọ ọ̀fọ̀ ati eérú. Ní dídá Kapanaomu lẹbi, eyi tí o hàn gbangba pe ó fi ṣe ibujokoo lákòókò iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀, Jesu polongo pe: “Yoo ṣeéfaradà fun ilẹ̀ Sodomu ní Ọjọ́ Ìdájọ́ jù fun yin lọ.”

Jesu lẹhin naa yin Baba rẹ̀ ọ̀run ní gbangba. A sún un lati ṣe bẹẹ nitori Ọlọrun fi awọn otitọ ti ẹ̀mí ti o ṣeyebíye pamọ́ fun awọn ọlọgbọ́n ati aronúmòye ṣugbọn o ṣí awọn nǹkan yíyanilẹ́nu wọnyi payá fun awọn onirẹlẹ, fun awọn ọmọ-ọwọ́, gẹgẹ bi a ti lè sọ ọ́.

Nigbẹhin, Jesu fúnni ní ìkésíni fífanimọ́ra naa: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹyin tí ńṣe làálàá tí ẹrù sì wọ̀ lọ́rùn, emi yoo sì tù yin lára. Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yin kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nitori ọlọ́kàn-tútù ati onirẹlẹ ní ọkàn-àyà ni emi, ẹyin yoo sì rí ìtura fun ọkàn yin. Nitori àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.”

Bawo ni Jesu ṣe ńfúnni ní ìtura? Ó ńṣe bẹẹ nipasẹ pípèsè òmìnira kuro ninu ìsinrú awọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ eyi tí awọn aṣaaju isin ti fi di ẹrù ru awọn ènìyàn, eyi tí ó ní ninu, fun apẹẹrẹ, pípa awọn ìlànà Sabaati akánilọ́wọ́kò mọ́. Oun tún fi ọ̀nà ìtura hàn fun awọn wọnni tí wọn nímọ̀lára ìnilára ẹrù wiwuwo ti ìjẹgaba nipa awọn alaṣẹ ìṣèlú ati fun awọn wọnni tí wọn nímọ̀lára ẹrù ti awọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nipasẹ ẹ̀rí-ọkàn kan tí a pọ́n lójú. O ṣí bí ẹ̀ṣẹ̀ awọn ẹni tí a pọ́n lójú ṣe lè di eyi tí a dárí rẹ̀ jì wọn ati bí wọn ṣe lè gbádùn ìbátan ṣíṣeyebíye kan pẹlu Ọlọrun.

Àjàgà onínúrere tí Jesu fifúnni jẹ́ ti ìyàsímímọ́ patapata fun Ọlọrun, lílè sin Baba wa ọ̀run oníyọ̀ọ́nú, ati aláàánú. Ẹrù fífúyẹ́ tí Jesu fifún awọn wọnni tí wọn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ṣíṣègbọràn sí awọn nǹkan tí Ọlọrun beere fun fun iwalaaye, tí wọn jẹ́ awọn òfin Rẹ̀ tí a kọsílẹ̀ sinu Bibeli. Ṣíṣe ìgbọràn sí awọn wọnyi kò si nira rara. Matiu 11:16-30; Luuku 1:15; 7:31-35; 1 Johanu 5:3.

▪ Bawo ni awọn ènìyàn agbéraga ti kò duro sojukan akoko Jesu ṣe dabi awọn ọmọde?

▪ Ki ni o sún Jesu lati yin Baba rẹ̀ ọ̀run?

▪ Ọ̀nà wo ni a gbà di ẹrù ru awọn ènìyàn, ìtura wo sì ni Jesu fifúnni?