Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awọn Ifarahan Ikẹhin, ati Pẹntikọsi 33 C.E.

Awọn Ifarahan Ikẹhin, ati Pẹntikọsi 33 C.E.

Orí 131

Awọn Ifarahan Ikẹhin, ati Pẹntikọsi 33 C.E.

JESU ṣeto fun gbogbo awọn apọsiteli rẹ mọkanla lati pade rẹ lori oke kan ni Galili ni akoko pato kan. O farahan bí ẹni pe awọn ọmọ-ẹhin miiran ni a sọ fun nipa ipade naa, apapọ awọn eniyan ti wọn ju 500 ni wọn si pejọ. Iru apejọpọ alayọ wo ni eyi jasi nigba ti Jesu farahan ti o si bẹrẹ sii kọ́ wọn!

Laaarin awọn nǹkan miiran, Jesu ṣalaye fun awọn ogunlọgọ titobi naa pe Ọlọrun ti fun oun ni gbogbo aṣẹ ni ọrun ati ni ilẹ-aye. O gba wọn niyanju pe, “Ẹ lọ ki ẹ si sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin, ki ẹ maa baptisi wọn ni orukọ Baba ati ti Ọmọkunrin ati ti ẹmi mimọ, ki ẹ maa kọ wọn lẹkọọ lati kiyesi ohun gbogbo ti mo ti palaṣẹ fun yin.”

Ro o wò ná! Awọn ọkunrin, awọn obinrin, ati awọn ọmọde gbogbo wọn gba iṣẹ kan naa yii lati ṣajọpin ninu iṣẹ sisọni di ọmọ-ẹhin. Awọn alatako yoo gbiyanju lati dá wiwaasu ati kikọni wọn duro, ṣugbọn Jesu tù wọn ninu pe: ‘Ẹ wòó! Emi wà pẹlu yin ni gbogbo ọjọ titi de opin eto awọn nǹkan.’ Jesu wà pẹlu awọn ọmọlẹhin rẹ nipasẹ ẹmi mimọ, lati ran wọn lọwọ lati mu iṣẹ-ojiṣẹ wọn ṣẹ.

Lapapọ, Jesu farahan láàyè fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ fun sáà 40 ọjọ tẹle ajinde rẹ̀. Laaarin awọn ifarahan wọnyi, o fun wọn ni itọni nipa Ijọba Ọlọrun, o tẹnumọ ohun ti awọn ẹru-iṣẹ wọn jẹ́ gẹgẹ bi ọmọ-ẹhin rẹ̀. Ni akoko kan o tilẹ farahan Jakọbu ọmọ iya rẹ o si mu dá alaigbagbọ tẹlẹri yii loju pe Oun nitootọ ni Kristi.

Nigba ti awọn apọsiteli ṣi wà ni Galili, lọna ti o hàn gbangba Jesu fun wọn ni itọni lati pada si Jerusalẹmu. Nigba ti o npade pọ pẹlu wọn nibẹ, o sọ fun wọn pe: “Ẹ maṣe kuro ni Jerusalẹmu, ṣugbọn ẹ maa duro de ohun ti Baba ti ṣeleri, eyi ti ẹ gbọ nipa rẹ lẹnu mi; nitori Johanu, nitootọ, fi omi baptisi, ṣugbọn a o fi ẹmi mimọ baptisi yin laipẹ lẹhin eyi.”

Lẹhin naa Jesu pade pọ̀ pẹlu awọn apọsiteli rẹ lẹẹkan sii o si ṣamọna wọn jade kuro ni ilu lọ jinna titi de Bẹtani, eyi ti o wà lori gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ iha ila-oorun Òkè Olifi. Lọna ti o yanilẹnu, laika ohun gbogbo ti o ti sọ nipa gbigbera lọ si ọrun rẹ laipẹ si, sibẹ wọn gbagbọ pe Ijọba rẹ ni a o fi idi rẹ mulẹ lori ilẹ-aye. Nitori naa wọn beere pe: “Oluwa, iwọ ha nda Ijọba naa padabọ sipo fun Isirẹli ni akoko yii bi?”

Dipo ki o gbiyanju lẹẹkan sii lati tun oju iwoye òdì wọn ṣe, Jesu wulẹ dahun pe: “Kii ṣe ti yin lati ni imọ awọn akoko tabi awọn asiko ti Baba ti fi si abẹ aṣẹ oun tikaaraarẹ.” Lẹhin naa, ni titẹnumọ iṣẹ ti wọn gbọdọ ṣe lẹẹkan sii, o wipe: “Ẹyin yoo gba agbara nigba ti ẹmi mimọ ba de sori yin, ẹ o si jẹ ẹlẹrii mi ni Jerusalẹmu ati ni gbogbo Judia ati Samaria ati titi de ibi ti o jinna julọ ni ilẹ-aye.”

Nigba ti wọn si nwo o, Jesu bẹrẹ sii gbera soke si iha ọrun, ati lẹhin naa awọsanmọ bo o kuro loju wọn. Lẹhin bibọ ara ẹran rẹ kalẹ, oun goke re ọrun gẹgẹ bi ẹni ẹmi kan. Bi awọn 11 naa ti nbaa lọ ni bibojuwo oke ọrun, awọn ọkunrin 2 ti wọn wọ ẹwu funfun farahan lẹgbẹẹ wọn. Awọn angẹli ti wọn gbe awọ eniyan wọ wọnyi beere pe: “Ẹyin eniyan Galili, eeṣe ti ẹ fi duro ti ẹ sì nwo oke ọrun? Jesu yii ti a gbà soke kuro lọdọ yin si oke ọ̀run yoo wá bayii ni iru ọna kan naa bi ẹ ti ri ti nlọ si oke ọrun.”

Iru ọna eyi ti Jesu ṣẹṣẹ gbà fi ilẹ-aye silẹ jẹ laisi afẹfẹyẹyẹ itagbangba, awọn ọmọlẹhin rẹ oluṣotitọ nikan ni wọn si mọ̀. Nitori naa oun yoo pada ni iru ọna kan naa—laisi afẹfẹyẹyẹ itagbangba, awọn ọmọlẹhin rẹ oluṣotitọ nikan ni yoo foye mọ pe o ti pada o si ti bẹrẹ wiwà nihin in rẹ ninu agbara Ijọba.

Nisinsinyi awọn apọsiteli naa sọkalẹ lọ si isalẹ Òkè Olifi, wọn la Afonifoji Kidironi kọja, wọn si wọnu Jerusalẹmu lẹẹkan sii. Wọn wa nibẹ ni igbọran si aṣẹ Jesu. Ọjọ mẹwaa lẹhin naa, nigba Ayẹyẹ awọn Juu ti Pẹntikọsi 33 C.E., nigba ti nǹkan bi 120 awọn ọmọ-ẹhin pejọ ninu yara oke ni Jerusalẹmu, ariwo kan gan-an bii afẹfẹ iji lile bo ile naa lojiji. Awọn ahọn ti o dabi ti ina farahan, o si bà lori ọkọọkan awọn wọnni ti wọn wà nibẹ, gbogbo awọn ọmọ-ẹhin naa si bẹrẹsii sọ oniruuru ede. Eyi ni itujade ẹmi mimọ ti Jesu ti ṣeleri! Matiu 28:16-20, NW; Luuku 24:49-52, NW; 1 Kọrinti 15:5-7; Iṣe 1:3-15; 2:1-4, NW.

▪ Awọn wo ni Jesu fun ni itọni idagbere ni ori oke kan ni Galili, ki si ni awọn itọni wọnyi?

▪ Itunu wo ni Jesu pese fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, bawo ni oun yoo si ṣe wà pẹlu wọn?

▪ Bawo ni o ti pẹ to ti Jesu farahan awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẹhin ajinde rẹ̀, ki ni o si fi kọ wọn?

▪ Si ẹni wo, ti o han pe ko tii di ọmọ-ẹhin sibẹ, ni Jesu farahan?

▪ Awọn ipade ikẹhin meji wo ni Jesu ni pẹlu awọn apọsiteli rẹ, ki ni o si ṣẹlẹ ni awọn akoko wọnyi?

▪ Bawo ni o ti jẹ pe Jesu yoo pada ni iru ọna kan naa ti oun gba lọ?

▪ Ki ni o ṣẹlẹ ni Pẹntikọsi 33 C.E.?