Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awọn Ifarahan Siwaju Sii

Awọn Ifarahan Siwaju Sii

Orí 129

Awọn Ifarahan Siwaju Sii

AWỌN ọmọ-ẹhin ṣi rẹwẹsi sibẹ. Wọn ko loye ijẹpataki iboji ṣiṣofo naa, bẹẹ si ni wọn kò gba irohin awọn obinrin naa gbọ́. Nigba ti o ya ni ọjọ Sunday, Kleopa ati ọmọ-ẹhin miiran fi Jerusalẹmu silẹ lọ si Ẹmausi, nibi ti o jinna tó nǹkan bii ibusọ meje.

Ní oju ọna, nigba ti wọn njiroro awọn iṣẹlẹ ọjọ naa, ajeji kan darapọ mọ́ wọn. O beere pe, “Ki ni kókó ọrọ wọnyi ti ẹ njiyan le lori laaarin araayin bi ẹ ti nrin lọ?”

Awọn ọmọ-ẹhin naa duro, oju wọn rẹwẹsi, Kleopa si fesipada pe: “Iwọ ha ngbe ní iwọ nikan gẹgẹ bi atipo ní Jerusalẹmu nipa bẹẹ tí o kò mọ awọn nǹkan ti wọn ti ṣẹlẹ ninu rẹ̀ ni awọn ọjọ wọnyi?” O beere pe, “Awọn nǹkan wo?”

“Awọn nǹkan nipa Jesu ti Nasarẹti,” ni wọn dahun. “Awọn olori alufaa wa ati awọn oluṣakoso fi í lé idajọ iku lọwọ tí wọn sì kàn án mọ́gi. Ṣugbọn awa nreti pe ọkunrin yii ni ẹni naa ti a kadara lati dá Isirẹli nídè.’

Kleopa ati alabaakẹgbẹ rẹ̀ ṣalaye awọn iṣẹlẹ ayanilẹnu ọjọ naa—irohin nipa iran ti o ga ju ti ẹda lọ ti awọn angẹli ati iboji ṣiṣofo—ṣugbọn lẹhin naa wọn jẹwọ iyalẹnu jijinlẹ wọn nipa itumọ awọn nǹkan wọnyi. Ajeji naa ba wọn wipe: “Óò ẹyin alailoye ti ẹ si lọra ni ọkan lati gba gbogbo ohun ti awọn wolii sọ gbọ! Ko ha jẹ́ ọranyan fun Kristi lati jiya nǹkan wọnyi ki o si wọ inú ogo rẹ̀?” Lẹhin naa oun tumọ awọn ayọka lati inú ọrọ ẹsẹ iwe mímọ́ ti o niiṣe pẹlu Kristi fun wọn.

Nikẹhin wọn de eti Ẹmausi, ajeji naa ṣe bii ẹni ti o ṣi nba irin àjò niṣo. Ni fifẹ lati gbọ sii, awọn ọmọ-ẹhin naa rọ̀ ọ́ pe: “Duro pẹlu wa, nitori o ti nsunmọ alẹ.” Nitori naa o duro fun ounjẹ. Bi o ti gbadura ti o si bu akara ti o si nà án si wọn, wọn mọ̀ daju pe oun niti gidi ni Jesu ti o gbé ara ẹda eniyan wọ. Ṣugbọn lẹhin naa oun nù mọ́ wọn loju.

Nisinsinyi wọn loye idi ti ajeji naa fi mọ pupọ tobẹẹ! Wọn beere pe, “Ọkan aya wa kò ha gbina bi o ti nba wa sọrọ ni oju ọna, ti o si nṣi awọn Iwe Mimọ payá fun wa ni kikun?” Laijafara, wọn dide wọn sì yara pada lọ si Jerusalẹmu, nibi ti wọn ti ri awọn apọsiteli ati awọn wọnni tí wọn pejọ pẹlu wọn. Ṣaaju ki Kleopa ati ẹnikeji rẹ̀ tó le sọ ohun kan, awọn yooku rohin pẹlu irusoke pe: “Niti tootọ Oluwa ti ji dide o si fi ara han Simoni!” Lẹhin naa awọn meji naa rohin bi Jesu ti farahan wọn pẹlu. Eyi jẹ́ igba kẹrin laaarin ọjọ naa ti oun ti farahan awọn ẹni ọtọọtọ laaarin awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

Jesu lojiji ṣe ifarahan karun-un, ani bi o tilẹ jẹ pe awọn ilẹkun ni a tipa nitori pe awọn ọmọ-ẹhin wà ninu ibẹru awọn Juu, ó wọle, ó sì duro laaarin wọn gan-an, o si wipe: “Alaafia fun yin.” A dáyà já wọn, ni riro pe wọn ti ri ẹmi kan. Nitori naa, ni ṣiṣalaye pe oun kii ṣe ìran abàmì, Jesu wipe: “Eeṣe ti ẹ fi ńdààmú, eesitiṣe ti iyemeji fi dide ninu ọkan-aya yin? Ẹ wo awọn ọwọ́ mi ati awọn ẹsẹ̀ mi, pe emi funraami ni; ẹ fọwọba mi ki ẹ si ri, nitori ẹmi kò ni ẹran ati egungun gan-an gẹgẹ bi ẹ ti ri pe emi ni.” Sibẹ, wọn lọra lati gbagbọ.

Lati ran wọn lọwọ lati loye pe oun ni Jesu nitootọ, o beere pe: “Ẹ ni ohun kan nibẹ lati jẹ bí?” Lẹhin titẹwọgba ègé ẹja sísè ti o si jẹ ẹ, o wipe: “Iwọnyi ni ọrọ mi ti mo sọ fun yin nigba ti mọ ṣi wa pẹlu yin [ṣaaju iku mi], pe gbogbo nǹkan ti a ti kọ sinu ofin Mose ati ninu awọn Wolii ati awọn Saamu nipa mi ni a gbọdọ múṣẹ.”

Nitootọ, ni biba ohun ti o jásí ikẹkọọ Bibeli lọ pẹlu wọn, Jesu kọ wọn pe: “Ni ọ̀nà yii ni a ti kọ ọ́ pe Kristi yoo jiya yoo si dide laaarin awọn oku ni ọjọ kẹta, ati lori ipilẹ orukọ rẹ a o waasu ironupiwada fun idariji ẹṣẹ ninu gbogbo awọn orilẹ-ede—bẹrẹ lati Jerusalẹmu, ẹyin yoo jẹ́ ẹlẹrii awọn nǹkan wọnyi.”

Fun idi kan Tomasi kò si ni ipade irọlẹ ọjọ Sunday pataki yii. Nitori naa ni awọn ọjọ ti o tẹle e, awọn yooku fi idunnu sọ fun un pe: “Awa ti ri Oluwa!”

Tomasi yarí pe: “Ayafi bi emi ba rí àpá iṣo ni ọwọ rẹ̀, ti mo si ki ika ọwọ mi bọ àpá iṣo naa ti mo si ki ọwọ mi bọ ẹgbẹ rẹ̀, dajudaju emi ki yoo gbagbọ.”

O dara, ni ọjọ mẹjọ lẹhin naa awọn ọmọ-ẹhin tun pade ninu ile. Nisinsinyi Tomasi wà pẹlu wọn. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ilẹkun ni a tipa, Jesu duro laaarin wọn lẹẹkan sii o si wipe: “Alaafia fun yin.” Lẹhin naa, ni yiyijusi Tomasi, o kesi i pe: “Fi ika ọwọ rẹ sihin-in, si wo o awọn ọwọ mi, si mu ọwọ rẹ ki o si kì í bọ ẹgbẹ mi, kí o si dẹkun jijẹ alaigbagbọ.”

Tomasi ké soke pe, “Oluwa mi ati Ọlọrun mi!”

Jesu beere pe, “Nitori pe iwọ ti ri mi ṣe iwọ ti gbagbọ? Alayọ ni awọn wọnni ti ko rí ti wọn sì gbagbọ.” Luuku 24:11, 13-48; Johanu 20:19-29.

▪ Iwadii wo ni ajeji kan ṣe lọdọ awọn ọmọ-ẹhin meji loju ọna sí Ẹmausi?

▪ Ki ni ajeji naa sọ ti o mu ki ọkan-aya awọn ọmọ-ẹhin gbina ninu wọn?

▪ Bawo ni awọn ọmọ-ẹhin ṣe loye ẹni ti ajeji naa jẹ?

▪ Nigba ti Kleopa ati ekeji rẹ pada sí Jerusalẹmu, irohin arunisoke wo ni wọn gbọ?

▪ Ifarahan karun un wo ni Jesu ṣe fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki ni o si waye lakooko naa?

▪ Ki ni o ṣẹlẹ ni ọjọ kẹjọ lẹhin ifarahan karun un Jesu, bawo si ni Tomasi ṣe gbagbọdaju nikẹhin pe Jesu ti walaaye?