Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Awọn Ihin-iṣẹ Lati Ọrun Wá

Awọn Ihin-iṣẹ Lati Ọrun Wá

Orí 1

Awọn Ihin-iṣẹ Lati Ọrun Wá

GBOGBO Bibeli latokedelẹ jẹ ihin-iṣẹ kan lati ọrun, ti Bàbá wa ọrun ti pèsè fun ìtọ́ni wa. Bi o ti wu ki o ri, awọn ihin-iṣẹ pataki meji ni a mú wá ni nǹkan bii 2,000 ọdun sẹhin lati ọwọ́ angẹli kan ẹni ti “o maa nduro niwaju Ọlọrun.” Orukọ rẹ̀ ni Geburẹli. Ẹ jẹ ki a ṣe ayẹwo awọn ayika ipo awọn ibẹwo pataki meji wọnyi sori ilẹ̀ ayé.

Ọdun naa jẹ́ 3 B.C.E. Ni awọn òké Judia, ti o ṣeeṣe ki o ma jinna pupọ lati Jerusalẹmu, ni alufaa Jehofa kan ngbe ti orukọ rẹ̀ ńjẹ́ Sekaraya. Oun ti di arúgbó, bakan naa sì ni iyawo rẹ̀, Elisabẹti. Wọn kò sì ni awọn ọmọ. Sekaraya nṣe ipa tirẹ̀ ninu iṣẹ isin alufaa ninu tẹmpili Ọlọrun ni Jerusalẹmu. Lojiji Geburẹli farahan ni apá ọtun pẹpẹ tùràrí.

Sekaraya bẹru gidigidi. Ṣugbọn Geburẹli paná awọn ibẹru rẹ̀, o sọ pe, “Ma bẹru, Sekaraya, nitori ti adura rẹ̀ ti gbà; Elisabẹti aya rẹ̀ yoo sì bí ọmọkunrin kan fun ọ, iwọ yoo sì sọ orukọ rẹ̀ ni Johanu.” Geburẹli nbaa lọ lati kede pe Johanu “yoo pọ̀ niwaju Oluwa, [“Jehofa,” NW],” ati pe oun yoo “pese eniyan ti a murasilẹ de Oluwa [“Jehofa,” NW].”

Bi o ti wu ki o ri, Sekaraya kò lè gba eyi gbọ́. O dabi ohun ti kò lè ṣeeṣe pe oun ati Elisabẹti yoo ni ọmọ kan ni ọjọ ori wọn. Nitori naa Geburẹli sọ fun un pe: “Iwọ yoo yadi, iwọ kì yoo sì lè fọhùn, titi ọjọ naa tí nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹ, nitori iwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́.”

O dara, laaarin akoko yii, awọn eniyan ti o wà ni òde nṣe kayefi nipa ìdí ti Sekaraya fi pẹ tobẹẹ ninu tẹmpili. Nigba ti o jade lẹhin ọ rẹhin, oun kò lè sọrọ ṣugbọn o nfi kiki awọn ọwọ́ rẹ̀ ṣe àmì, wọn sì mọ̀ pe o ti ri ohun kan ti o ju ti ẹ̀dá lọ.

Lẹhin ti Sekaraya pari akoko iṣẹ isin tẹmpili rẹ̀, o pada sile. Laipẹ lẹhin naa o ṣẹlẹ nitootọ—Elisabẹti lóyún! Bi o ti nduro de asiko ti yoo bi ọmọ rẹ̀, Elisabẹti fi ara pamọ ni ile kuro lọdọ awọn eniyan fun oṣu marun-un.

Lẹhin naa Geburẹli farahan lẹẹkan sii. Ta ni oun sì sọ̀rọ̀ sí? Eyi jẹ́ si ọdọmọbinrin kan ti a kò tii gbe ni iyawo ti orukọ rẹ̀ njẹ Maria lati ilu Nasarẹti. Ihin-iṣẹ wo ni oun mu wa ni akoko yii? Fetisilẹ! “Iwọ ti ri ojurere lọdọ Ọlọrun,” ni Geburẹli sọ fun Maria. “Sá sì kiyesii, iwọ yoo lóyún ninu rẹ, iwọ yoo sì bi ọmọkunrin kan, iwọ yoo sì pe orukọ rẹ̀ ni Jesu.” Geburẹli fikun un pe: “Oun yoo pọ̀, Ọmọ Ọga Ogo Julọ ni a sì maa pè é: . . . yoo sì jọba ni ile Jakọbu titi aye; ijọba rẹ̀ kì yoo sì ni ipẹkun.”

Awa lè ni idaniloju pe Geburẹli kà á si anfaani lati mu awọn ihin-iṣẹ wọnyi wá. Bi a ti nka pupọ sii nipa Johanu ati Jesu, awa yoo ríi kedere siwaju sii ìdí ti awọn ihin iṣẹ wọnyi lati ọrun wa fi ṣe pataki tobẹẹ. 2 Timoti 3:16; Luuku 1:5-33.

▪ Awọn ihin iṣẹ pataki meji wo ni a mú wá lati ọrun?

▪ Ta ni ẹni ti o mú awọn ihin iṣẹ wọnyi wá, awọn wo ni a sì jíṣẹ́ wọnyi fun?

▪ Eeṣe ti awọn ihin iṣẹ naa fi ṣoro tobẹẹ lati gbàgbọ́?