Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbẹ Tẹmpili Wò Lẹẹkan Sii

Bíbẹ Tẹmpili Wò Lẹẹkan Sii

Orí 103

Bíbẹ Tẹmpili Wò Lẹẹkan Sii

JESU ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ lo alẹ́ wọn kẹta ní Bẹtani lati ìgbà tí wọn ti dé lati Jẹriko. Nisinsinyi ìmọ́lẹ̀ owurọ Monday, Nisan 10, bá wọn lójú ọ̀nà lọ sí Jerusalẹmu. Ebi npa Jesu. Nitori naa nigba ti ó tajúkán ti ó sì rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí ó ní ewé daradara, ó rìn lọ sibẹ lati ríi boya ọ̀pọ̀tọ́ diẹ wà lórí rẹ̀.

Awọn ewé igi naa tètè yọ ṣaaju akoko, niwọn bi àsìkò fun ọ̀pọ̀tọ́ kì yoo dé títí di June, tí ó sì jẹ́ pe apa ipari oṣu March ni a sì wà yii. Bí ó ti wù kí ó rí, ní kedere Jesu rò pe niwọn bi awọn ewé rẹ̀ ti tètè yọ, ó ṣeeṣe kí awọn ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ tètè so pẹlu. Ṣugbọn oun ní ìjákulẹ̀. Awọn ewé naa ti fun igi naa ní ìrísí tí ntannijẹ. Nitori eyi Jesu gégùn-ún fun igi naa, ní wiwi pe: “Kí ẹnikankan maṣe jẹ èso lati orí rẹ mọ́ titilae.” Awọn àbájáde igbesẹ ti Jesu gbe ati ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ ni a wa mọ̀ ni owurọ ọjọ keji.

Ní rírìn nìṣó, Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ dé Jerusalẹmu láìpẹ́. Ó lọ sí tẹmpili, eyi ti ó ti ṣèbẹ̀wò sí ní ọ̀sán àná. Lonii, bí ó ti wù kí ó rí, oun gbégbèésẹ̀, gan-an gẹgẹ bi ó ti ṣe ní ọdun mẹta ṣaaju nigba tí oun wá sí Ìrékọjá ní 30 C.E. Awọn wọnni tí wọn ńtà tí wọn sì ńrà ninu tẹmpili naa ni Jesu lé jade ó sì sojú tábìlì awọn tí nṣe pàṣípààrọ̀ owó ati ìjókòó awọn wọnni tí ńta àdàbà dé. Kò tilẹ yọnda kí ẹnikẹni gbé ohun èèlò kankan là tẹmpili kọja.

Ní dídá awọn wọnni tí wọn nṣe pàṣípààrọ̀ owó tí wọn sì ńta awọn ẹranko ninu tẹmpili lẹ́bi, ó sọ pe: “A kò ha ti kọ ọ́ pe: ‘Ilé adura ni a o maa pe ilé mi fun gbogbo awọn orílẹ̀-èdè’? Ṣugbọn ẹyin ti sọ ọ́ di ihò awọn ọlọ́ṣà.” Ọlọ́ṣà ni wọn nitori pe wọn fi dandangbọ̀n beere fun iye owó gọbọi lọwọ awọn wọnni tí wọn kò ní yíyàn keji ju kí wọn ra awọn ẹranko tí wọn nílò fun ìrúbọ lọwọ wọn. Nitori naa Jesu wò awọn ìṣòwò iṣẹ́-ajé yii gẹgẹ bi irú ìlọ́nilọ́wọ́gbà tabi ìjanilólè kan.

Nigba ti awọn olórí alufaa, awọn akọwe òfin, ati awọn ògúnnágbòǹgbò ninu awọn eniyan naa gbọ́ ohun tí Jesu ti ṣe, wọn wá ọ̀nà lẹẹkan sii lati pa á. Wọn tipa bẹẹ fi ẹ̀rí hàn pe wọn ti kọja atunṣe. Sibẹ, wọn kò mọ bí wọn ṣe lè pa Jesu, niwọn bi gbogbo awọn eniyan ti ńdúró yí i ká lati gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Yàtọ̀ sí awọn Juu abínibí, awọn Keferi pẹlu tún wá sí Irekọja naa. Wọn jẹ́ awọn aláwọ̀ṣe, tí ó tumọsi pe wọn ti yipada sí isin awọn Juu. Awọn Giriiki kan bayii, tí wọn jẹ́ awọn aláwọ̀ṣe ní kedere, tọ Filipi wá nisinsinyi, wọn sì sọ pe awọn fẹ́ rí Jesu. Filipi lọ bá Anderu, boya lati beere yálà irúfẹ́ ipade kan bẹẹ yoo baamu. Ní kedere Jesu ṣì wà ní tẹmpili, níbi tí ó ti ṣeeṣe fun awọn Giriiki naa lati rí i.

Jesu mọ̀ pe iwọnba ọjọ́ diẹ ni ó kù fun oun lati walaaye, nitori naa oun ṣàkàwé ipò rẹ̀ lọna rere pe: “Wakati naa ti dé tí a o ṣe Ọmọkunrin eniyan lógo. Lóòótọ́ dajudaju ni mo wi fun yin, Àyàfi bí hóró àlìkámà kan bá bọ́ sí ilẹ̀ tí ó sì kú, ó wà ní kìkì hóró kan; ṣugbọn bí ó bá kú, nigba naa yoo so èso pupọ.”

Ìníyelórí hóró àlìkámà kan kéré pupọ. Sibẹ, ki ni bí a bá fi sínú erùpẹ̀ ilẹ̀ tí ó sì “kú,” ní píparí iwalaaye rẹ̀ gẹgẹ bi irúgbìn kan? Lẹhin naa yoo hù jáde tí yoo sì dàgbà di pòròpórò kan láìpẹ́ tí ó mú ọpọlọpọ awọn hóró àlìkámà jáde. Bakan naa, Jesu wulẹ jẹ eniyan pípé kan. Ṣugbọn bí ó bá kú ninu ìṣòtítọ́ sí Ọlọrun, oun yoo di ọ̀nà fun pípín iye ainipẹkun fun awọn eniyan olùṣòtítọ́ tí wọn ní ẹ̀mí ìfara-ẹni rúbọ kan naa tí oun ní. Nipa bayii, Jesu sọ pe: “Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọkàn rẹ̀ pa á run, ṣugbọn ẹni tí ó bá kórìíra ọkàn rẹ̀ ninu ayé yii yoo daabobo o fun ìyè ainipẹkun.”

Ní kedere Jesu kò ronú kìkì nipa araarẹ̀, nitori ó ṣalaye siwaju sii pe: “Bí ẹnikẹni yoo bá ṣe iranṣẹ fun mi, jẹ́ kí ó tọ̀ mi lẹhin, níbi tí emi bá sì wà nibẹ ni òjíṣẹ́ mi yoo wà pẹlu. Bí ẹnikẹni yoo bá ṣèránṣẹ́ fun mi, Baba yoo dá a lọ́lá.” Ẹ wò irú èrè yíyanilẹ́nu fun títẹ̀lé Jesu ati ṣíṣe iranṣẹ fun un tí eyi jẹ́! Ó jẹ́ èrè ìbọláfúnni lati ọ̀dọ̀ Baba lati kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹlu Kristi ninu Ijọba naa.

Ní ríronú nipa ìjìyà ńláǹlà ati ikú onírora tí ó ńdúró dè é, Jesu nbaa lọ pe: “Nisinsinyi ọkàn mi dààmú, ki ni emi yoo sì wí? Baba, gbà mi là kuro ninu wakati yii.” Kìkì bí ohun naa tí ńdúró dè é bá lè ṣee yẹ̀ silẹ! Ṣugbọn, bẹẹkọ, gẹgẹ bi oun ti wí pe: “Ìdí niyii tí mo ṣe wá sí wakati yii.” Jesu wà ní ìfohùnṣọ̀kan pẹlu gbogbo ìṣètò Ọlọrun pátá, tí ó ní ninu ikú ìrúbọ tirẹ̀ fúnraarẹ̀. Matiu 21:12, 13, 18, 19; Maaku 11:12-18; Luuku 19:45-48; Johanu 12:20-27.

▪ Eeṣe tí Jesu fi retí lati rí awọn ọ̀pọ̀tọ́ kódà bí ó tilẹ jẹ́ pe kii ṣe àsìkò niyẹn fun wọn?

▪ Eeṣe tí Jesu fi pe awọn wọnni tí wọn ńtajà ní tẹmpili ní “awọn ọlọ́ṣà”?

▪ Ní ọ̀nà wo ni Jesu fi dabi hóró àlìkámà kan tí ó kú?

▪ Bawo ni Jesu ṣe nímọ̀lára nipa ìjìyà ati ikú tí ó dúró dè é?