Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Baptism Jesu

Baptism Jesu

Orí 12

Baptism Jesu

NI NǸKAN bii oṣu mẹfa lẹhin ti Johanu ti bẹrẹsii waasu, Jesu, ti o jẹ́ ẹni 30 ọdun nisinsinyi, wá sọdọ rẹ̀ ní Jọdani. Fun ìdí wo ni? Lati ṣe ibẹwo ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ ni bi? Jesu ha wulẹ nifẹẹ lati mọ bí iṣẹ Johanu ntẹsiwaju ni? Rárá, Jesu sọ fun Johanu pe ki o baptisi oun.

Lẹsẹkẹsẹ ni Johanu lodisi i: “Emi ni a ba baptisi lọdọ rẹ, iwọ sì tọ̀ mí wá?” Johanu mọ̀ pe Jesu mọ̀lẹ́bí oun jẹ́ akanṣe Ọmọkunrin Ọlọrun. Họwu, Johanu ti fò sókè pẹlu ayọ̀ ninu ikùn iya rẹ̀ nigba ti Maria, ti oyún Jesu nbẹ ninu rẹ̀, ṣe ibẹwo sọdọ wọn! Laisi aniani Elisabẹti iya Johanu sọ fun un nipa eyi lẹhin akoko naa. Oun sì ti tún nilati sọ fun un pẹlu nipa ikede angẹli naa nipa ìbí Jesu ati nipa ifarahan awọn angẹli sí awọn oluṣọ agutan ni òru ọjọ́ ti a bí Jesu.

Nitori naa Jesu kii ṣe àjèjì sí Johanu. Johanu sì mọ̀ pe baptisi oun kii ṣe fun Jesu. O wà fun awọn wọnni ti wọn ronupiwada ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ṣugbọn Jesu kò ní ẹ̀ṣẹ̀. Sibẹ, laika ilodisi Johanu sí, Jesu tẹpẹlẹmọ ọn pe: “Jọ̀wọ́ rẹ̀ bẹẹ ná, nitori bẹẹ ni o yẹ fun wa lati mú gbogbo òdodo ṣẹ.”

Eeṣe ti o fi tọna fun Jesu lati ṣe baptisi? Nitori baptisi Jesu jẹ àmì, kii ṣe fun ironupiwada kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀, bikoṣe ti yiyọnda araarẹ̀ lati wá ṣe ifẹ inu Baba rẹ̀. Jesu ti jẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà, ṣugbọn nisinsinyi akoko naa ti dé fun un lati bẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ ti Jehofa Ọlọrun rán an wá sí ayé lati wa ṣe. Njẹ o rò pe Johanu reti ohun àjèjì eyikeyii lati ṣẹlẹ nigba ti o nbaptisi Jesu bí?

O dara, Johanu rohin lẹhin ìgbà naa pe: “Ẹni ti o rán mi wá, lati fi omi baptisi, oun naa ni o wí fun mi pe, Lori ẹni tí iwọ ba ríi, ti Ẹmi sọkalẹ si, ti o sì ba le e, oun naa ni ẹni ti nfi ẹmi mimọ baptisi.” Nitori naa Johanu nreti lati rí ẹmi Ọlọrun kí ó bà lé ẹnikan ti oun baptisi. Boya, nitori ìdí eyi, ẹnu kò yà á pupọ nigba ti, bí Jesu ti ngoke wá lati inu omi, Johanu rí ‘ẹmi Ọlọrun ti o sọkalẹ bí àdàbà, ti o sì bà lé e.’

Ṣugbọn ohun ti o ju eyiini lọ ni o ṣẹlẹ nigba ti a baptisi Jesu. “Ọ̀run ṣí sílẹ̀ fun un.” Ki ni eyi tumọsi? Lọna ti o hàn gbangba eyi tumọsi pe nigba ti a nbaptisi rẹ̀, agbára iranti iwalaaye rẹ̀ ní ọrun ṣaaju ki o to di eniyan padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nipa bayii, Jesu nisinsinyi ranti iwalaaye rẹ̀ ní kíkún gẹgẹ bi ọmọkunrin ẹ̀mí Jehofa Ọlọrun, papọ pẹlu gbogbo awọn ohun ti Ọlọrun sọ fun un ní ọ̀run lakooko wíwà rẹ̀ ṣaaju kí ó tó di eniyan.

Ní afikun, nigba baptisi rẹ̀, ohùn kan lati ọ̀run wá polongo pe: “Eyi ni ọmọkunrin mi, aayo olufẹ, ẹni ti mo tẹwọgba.” Ohùn ta ni eyi? Ohùn Jesu fúnraarẹ̀ ha ni bí? Dajudaju bẹẹkọ! Ti Ọlọrun ni. Dajudaju, Jesu jẹ́ Ọmọkunrin Ọlọrun, kii ṣe Ọlọrun fúnraarẹ̀, gẹgẹ bi awọn eniyan kan ti sọ.

Bi o ti wu ki o ri, Jesu jẹ́ eniyan ọmọkunrin Ọlọrun kan, gan-an gẹgẹ bi ọkunrin akọkọ, Adamu ti jẹ́. Ọmọ-ẹhin naa Luuku, lẹhin ti o ṣapejuwe baptisi Jesu, kọwe pe: “Jesu tìkáraarẹ̀ ńtó bí ẹni ìwọ̀n ọgbọ̀n ọdun, ó jẹ́ (bí a ti ṣe pè é) ọmọ Josẹfu, tii ṣe ọmọ Eli, . . . tii ṣe ọmọ Dafidi, . . . tii ṣe ọmọ Aburahamu, . . . tii ṣe ọmọ Noa, . . . tii ṣe ọmọ Adamu, tii ṣe ọmọ Ọlọrun.”

Gẹgẹ bi Adamu ti jẹ́ eniyan ‘ọmọkunrin Ọlọrun,’ bẹẹ naa ni Jesu jẹ́. Jesu ni ọkunrin titobilọla julọ naa ti o tíì gbé ayé rí, eyi ti o hàn gbangba nigba ti a ṣayẹwo igbesi aye Jesu. Bi o ti wu ki o ri, nigba baptisi rẹ̀, Jesu wọnu ipo ibatan titun kan pẹlu Ọlọrun, ni didi Ọmọkunrin tẹmi Ọlọrun pẹlu. Ọlọrun nisinsinyi pè é pada sí ọ̀run, gẹgẹ bi a ti lè sọ ọ́, nipa mímú un bẹrẹ ipa ọna kan ti yoo ṣamọna rẹ̀ sí fifi iwalaaye eniyan rẹ̀ titilae ninu irubọ nititori ẹda araye ti a ti dá lẹbi ikú. Matiu 3:13-17; Luuku 3:21-38; 1:34-36, 44; 2:10-14; Johanu 1:32-34; Heberu 10:5-9.

▪ Eeṣe ti Jesu kii fi ṣe àjèjì sí Johanu?

▪ Niwọn bi oun kò ti dá ẹ̀ṣẹ̀ rí, eeṣe ti a fi baptisi Jesu?

▪ Loju iwoye ohun ti Johanu mọ̀ nipa Jesu, eeṣe ti oun ti lè má ni iyalẹnu nigba ti ẹmi Ọlọrun bà lé Jesu?