Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Burẹdi Tootọ Lati Ọrun”

“Burẹdi Tootọ Lati Ọrun”

Orí 54

“Burẹdi Tootọ Lati Ọrun”

ỌJỌ́ tí ó ṣaaju naa ti kún fun awọn ìṣẹ̀lẹ̀ nitootọ. Jesu ti bọ́ ẹgbẹẹgbẹrun lọna iṣẹ-iyanu, ó sì ti yẹra fun ìgbìdánwò awọn ènìyàn naa lati fi i jẹ ọba. Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn ó rìn kọjá lórí Òkun Galili oníjì; ó yọ Peteru ninu ewu; ẹni tí ó bẹrẹsii rì nigba ti ó rìn lórí omi tí ìjì ńbì síwá bì sẹ́hìn, ó sì mú ìgbì parọ́rọ́ lati gba awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ là kuro lọwọ rírì.

Nisinsinyi awọn ènìyàn naa ti Jesu ti bọ́ lọna iṣẹ́-ìyanu ní àríwá ìlà-oòrùn Òkun Galili ríi nítòsí Kapanaomu wọn sì béèrè pe: “Nigba wo ni iwọ dé ìhín?” Ní bíbá wọn wí lọna lílekoko, Jesu sọ pe wọn ti wá lati wá a kiri kìkì nitori pe wọn ṣèrètí ounjẹ jíjẹ ọ̀fẹ́ miiran. Oun rọ̀ wọn lati ṣiṣẹ́, kii ṣe fun ounjẹ tí ńṣègbé, ṣugbọn ounjẹ tí ńwà fun ìyè ainipẹkun. Nitori naa awọn ènìyàn naa béèrè pe: “Ki ni awa yoo ṣe lati ṣe awọn iṣẹ́ Ọlọrun?”

Jesu dárúkọ kìkì iṣẹ́ kanṣoṣo tí ó ní ìníyelórí gíga jùlọ. “Eyi ni iṣẹ́ Ọlọrun,” ni oun ṣàlàyé, “pe kí ẹ lò ìgbàgbọ́ ninu ẹni tí Ẹni yii rán wá.”

Awọn ènìyàn naa, bí ó ti wù kí ó rí, kò lò ìgbàgbọ́ ninu Jesu, láìka gbogbo awọn iṣẹ́-ìyanu tí oun ti ṣe sí. Láì ṣeé gbàgbọ́, àní lẹhin gbogbo awọn nǹkan yíyanilẹ́nu tí oun ti ṣe, wọn beere pe: “Nigba naa, ki ni iwọ ńṣe gẹgẹ bi iṣẹ́ àmì kan kí awa lè rí i kí a sì gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ wo ni iwọ ńṣe? Awọn babanla wa jẹ mana ní aginjù, gan-an gẹgẹ bi a ti kọ ọ́ pe, ‘Ó fi burẹdi lati ọ̀run wá fun wọn jẹ.’”

Ní ìdáhùnpadà sí ibeere wọn fun àmì kan, Jesu mú Orísun awọn ìpèsè iṣẹ́-ìyanu ṣe kedere, ní wiwi pe: “Mose kò fun yin ní burẹdi lati ọ̀run wa, ṣugbọn Baba mi ni ó fun yin ní burẹdi tootọ lati ọ̀run wá. Nitori burẹdi Ọlọrun ni ẹni naa tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá tí ó sì fi ìyè fun ayé.”

“Oluwa,” ni awọn ènìyàn naa wí, “maa fun wa ní burẹdi yii nigba gbogbo.”

“Emi ni burẹdi yii,” ni Jesu ṣàlàyé. “Ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi ebi kì yoo pa á rárá, ẹni tí ó bá sì lò ìgbàgbọ́ ninu mi òùngbẹ kì yoo gbẹ ẹ́ mọ́ rárá. Ṣugbọn mo ti wi fún yin, Ẹyin tilẹ ti rí mi sibẹ ẹyin kò sì gbàgbọ́. Olukuluku ohun tí Baba fun mi yoo tọ̀ mi wá, ẹni naa tí ó bá sì tọ̀ mi wá emi kì yoo lé e sọnù lọnakọna; nitori pe emi ti sọ̀kalẹ̀ lati ọ̀run wá, kii ṣe lati ṣe ìfẹ́-inú ti araami, bikoṣe ìfẹ́-inú ẹni tí ó rán mi. Eyi ni ìfẹ́-inú ẹni tí ó rán mi, pe kí emi má sọ ohunkohun nù ninu ohun gbogbo tí oun ti fun mi ṣugbọn kí emi jí i dìde ní ọjọ́ ikẹhin. Nitori eyi ni ìfẹ́-inú Baba mi, pe kí olukuluku ẹni tí ó bá rí Ọmọkunrin tí ó sì lò ìgbàgbọ́ ninu rẹ̀ lè ní ìyè ainipẹkun.”

Nihin-in ni awọn Juu ti bẹrẹsii kùnsínú sí Jesu nitori oun wipe, “Emi ni burẹdi tí ó sọkalẹ lati ọ̀run wa.” Wọn kò rí ohunkohun ninu rẹ̀ tí ó rekọja ọmọkunrin awọn òbí ẹ̀dá-ènìyàn ati nitori naa bii awọn ènìyàn Nasarẹti, wọn takò ó, ní wiwi pe: “Jesu ọmọkunrin Josẹfu kọ ni eyi, baba ati iya ẹni tí awa mọ̀? Bawo ni oun ṣe wí nisinsinyi pe, ‘emi ti sọ̀kalẹ̀ lati ọ̀run wá’?”

“Ẹ́ dẹ́kun kíkùn láàárín araayin,” ni Jesu dáhùnpadà. “Kò sí ènìyàn tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi àyàfi bí Baba, àní tí ó rán mi, bá fà á; emi yoo sì jí i dìde ní ọjọ ikẹhin. A ti kọ ọ́ ninu awọn Wolii pe, ‘Gbogbo wọn ni a ó sì kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lati ọ̀dọ̀ Jehofa.’ Olukuluku ẹni tí ó ti gbọ́ lati ọ̀dọ̀ Baba tí ó sì kẹ́kọ̀ọ́ ńwá sí ọ̀dọ̀ mi. Kii ṣe pe ènìyàn kankan ti rí Baba, àfi ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá; ẹni yii ni ó ti rí Baba. Lóòótọ́ dajudaju mo wí fun un yin, Ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní ìyè ainipẹkun.”

Ní bíbá ọ̀rọ̀ rẹ lọ, Jesu sọ lẹẹkan sí i pe: “Emi ni burẹdi ìyè. Awọn babanla yin jẹ mana ní aginjù wọn sì kú sibẹsibẹ. Eyi ni burẹdi tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ẹnikẹni lè jẹ ninu rẹ̀ kí ó má sì kú. Emi ni burẹdi ìyè tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá; bí ẹnikẹni bá jẹ ninu burẹdi yii yoo walaaye titilae.” Bẹẹni, nipa lílò ìgbàgbọ́ ninu Jesu, ẹni naa tí Ọlọrun rán jáde wá, awọn ènìyàn lè ní ìyè ainipẹkun. Kò sí mana, tabi burẹdi kankan, ti ó lè pèsè iyẹn!

O dabi ẹni pe ìjíròrò naa nipa burẹdi tí ó ti ọ̀run wá bẹ̀rẹ̀ kété lẹhin tí awọn ènìyàn naa ti rí Jesu nítòsí Kapanaomu. Ṣugbọn ó nbaa nìṣó ó sì dé òtéńté lẹhin ìgbà naa nigba tí Jesu fi ńkọ́ni ninu sinagọgu ní Kapanaomu. Johanu 6:25-51, 59; Saamu 78:24; Aisaya 54:13; Matiu 13:55-57.

▪ Awọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni wọn ṣaaju ìjíròrò Jesu nipa burẹdi tí ó ti ọ̀run wá?

▪ Lójú ìwòye ohun tí Jesu ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, eeṣe tí ibeere fun àmì kan fi jẹ́ ohun tí kò bọ́sí i rárá?

▪ Eeṣe tí awọn Juu fi kùn sínú sí ìjẹ́wọ́ Jesu pe oun ni burẹdi tootọ lati ọ̀run?

▪ Nibo ni ìjíròrò naa nipa burẹdi tí ó ti ọ̀run wá ti ṣẹlẹ̀?