Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Dídá Awọn Olùfisùn Rẹ̀ Lóhùn

Dídá Awọn Olùfisùn Rẹ̀ Lóhùn

Orí 30

Dídá Awọn Olùfisùn Rẹ̀ Lóhùn

NIGBA ti awọn aṣaaju ìsìn Juu fẹ̀sùn kan Jesu fun ṣíṣàìmú Sabaati ṣẹ, ó dáhùn pe: “Baba mi ti ńṣiṣẹ́ titi di isinsinyi, emi sì ńṣiṣẹ́.”

Ní ìlòdìsí ohun ti awọn Farisi naa sọ, iṣẹ́ Jesu kii ṣe iru eyi tí òfin Sabaati kàléèwọ̀. Iṣẹ́ iwaasu ati ìmúniláradá rẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ àyànfúnni kan lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun, ati ní àfarawé apẹẹrẹ Ọlọrun, oun nbaa lọ lati maa ṣe é lojoojumọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ìdáhùn rẹ̀ mú kí awọn Juu tubọ bínú sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, tí wọn sì ńwá ọ̀nà lati pa á. Eeṣe?

Ó jẹ́ nitori pe nisinsinyi kii ṣe pe wọn gbàgbọ́ pe Jesu ńṣàìmú Sabaati ṣẹ nikan ni ṣugbọn wọn ka sisọ rẹ̀ ti jíjẹ́ Ọmọkunrin Ọlọrun ni taarata sí ohun tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ òdì. Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu kò bẹ̀rù ó sì dá wọn lóhùn siwaju sí i nipa ìbátan olójúrere rẹ̀ pẹlu Ọlọrun. “Baba ni ifẹni fun Ọmọkunrin,” ni oun wí, “ó sì fi ohun gbogbo tí oun tìkáraarẹ̀ ńṣe hàn án.”

“Gan-an gẹgẹ bi Baba ti ńjí òkú dìde,” ni Jesu nbaa lọ, “bẹẹ ni Ọmọkunrin pẹlu ńsọ awọn wọnni tí oun bá fẹ́ di ààyè.” Nitootọ, Ọmọkunrin ti ńgbé awọn òkú dìde nipa tẹmi nisinsinyi! “Ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi tí ó sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́,” ni Jesu wí, “ti rekọja lati inú ikú sí ìyè.” Bẹẹni, oun nbaa lọ: “Wakati naa ńbọ̀, nisinsinyi sì ni, nigba ti awọn òkú yoo gbọ́ ohùn Ọmọkunrin Ọlọrun awọn wọnni tí wọn bá sì ṣe ìgbọràn yoo yè.”

Bí ó tilẹ jẹ́ pe kò sí akọsilẹ kankan pe Jesu ti gbé ẹnikẹni dìde kuro ninu òkú niti gidi sibẹsibẹ, oun sọ fun awọn ti o fẹsun kan an pe irú ajinde kuro ninu òkú kan bẹẹ niti gidi yoo wáyé. “Kí ẹnu maṣe yà yin sí eyi,” ni oun wí, “nitori wakati naa nbọ ninu eyi tí gbogbo awọn wọnni tí nbẹ ninu ibojì iranti yoo gbọ́ ohùn rẹ̀ wọn yoo sì jáde wá.”

Títí di àkókò yii, Jesu kò tíì ṣàpèjúwe ní gbangba rara ipa-iṣẹ́ rẹ̀ pàtàkì ninu ète Ọlọrun ní irúfẹ́ ọ̀nà tí ó dáyàtọ̀ kedere ati ní pàtó kan bẹẹ. Ṣugbọn awọn ti o fẹsun kan Jesu ní awọn ẹ̀rí tí ó ju tirẹ̀ lọ nipa awọn nǹkan wọnyi. “Ẹyin ti rán ènìyàn sí Johanu,” ni Jesu rán wọn létí, “oun sì ti jẹ́rìí sí otitọ.”

Ní ọdun meji péré ṣaaju, Johanu Arinibọmi sọ fun awọn aṣaaju isin Juu wọnyi nipa Ẹni naa tí ńbọ̀ lẹhin rẹ̀. Ní rírán wọn létí iyì gíga tí wọn ti fi ìgbà kan ní fun Johanu ẹni tí wọn fisẹ́wọ̀n nisinsinyi, Jesu sọ pe: “Ẹyin sì ńfẹ́ fun àkókò kukuru lati maa yọ gidigidi ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.” Jesu pe eyi padà sinu èrò inú wọn ní ìrètí lati ràn wọn lọwọ, bẹẹni, lati gbà wọn là. Sibẹ oun kò gbáralé ẹ̀rí Johanu.

“Awọn iṣẹ́ naa tìkáraawọn tí emi ńṣe [tí ó ní ninu iṣẹ́ ìyanu tí oun ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe tán] jẹ́rìí nipa mi pe Baba ni ó rán mi.” Ṣugbọn yàtọ̀ sí iyẹn, Jesu nbaa lọ: “Baba tí ó rán mi tìkáraarẹ̀ ti jẹ́rìí nipa mi.” Ọlọrun jẹ́rìí nipa Jesu, fun apẹẹrẹ, nigba iribọmi rẹ̀, ni wiwi pe: “Eyi ni Ọmọkunrin mi, olùfẹ́.”

Niti tootọ, awọn ti o nfẹsun kan Jesu kò ní àwíjàre fun ṣíṣá a tì. Iwe Mimọ naa gan-an tí wọn sọ pe awọn ńyẹ̀wò jẹ́rìí nipa rẹ̀! “Bí ẹ bá ti gba Mose gbọ́ ẹyin ìbá gbà mí gbọ́,” ni Jesu pari ọ̀rọ̀ rẹ̀, “nitori pe ẹni yẹn kọ̀wé nipa mi. Ṣugbọn bí ẹ kò bá gba ìwé ẹni yẹn gbọ́, bawo ni ẹ ṣe lè gba awọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́?” Johanu 5:17-47; 1:19-27; Matiu 3:17.

▪ Eeṣe tí iṣẹ́ Jesu kò fi ru òfin Sabaati?

▪ Bawo ni Jesu ṣe ṣàpèjúwe ipa-iṣẹ́ rẹ̀ pàtàkì ninu ète Ọlọrun?

▪ Lati fihàn pe oun ni Ọmọkunrin Ọlọrun, ẹ̀rí ta ni Jesu tọ́kasí?