Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Farisi kan Ṣe É Lálejò

Farisi kan Ṣe É Lálejò

Orí 83

Farisi kan Ṣe É Lálejò

JESU ṣì wà ninu ilé sàràkí Farisi kan ó sì ṣẹ̀ṣẹ̀ mú ọkunrin kan tí ó ńjìyà lọwọ ògùdùgbẹ̀ láradá. Bí ó ti ńṣàkíyèsí awọn àlejò ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọn ńyan awọn ibi giga ní ìdí ounjẹ naa, ó fi ẹ̀kọ́ kan kọ́ni nipa ìrẹ̀lẹ̀.

“Nigba ti ẹnikan bá pè ọ sí ibi àsè ìgbéyàwó kan,” Jesu lẹhin naa ṣàlàyé pe, “maṣe dùbúlẹ̀ síbi giga julọ. Boya oun lè ti pe ẹnikan tí ó tayọ jù ọ ní àkókò naa, ẹni tí ó sì pe iwọ ati oun yoo wá yoo sì wí fun ọ pe, ‘Jẹ́ kí ọkunrin yii jókòó sí ibẹ̀.’ Nigba naa ni iwọ yoo fi ìtìjú dìde lati jókòó sí ibi rírẹlẹ̀ julọ.”

Nitori naa Jesu fúnni ní imọran pe: “Nigba ti a bá pè ọ, lọ kí o sì jokoo ní ibi rírẹlẹ̀ julọ, pe nigba ti ọkunrin tí ó pè ọ́ bá dé oun yoo wí fun ọ, ‘Ọ̀rẹ́, gòkè sí i.’ Nigba naa iwọ yoo ní ọlá ní iwaju gbogbo awọn àlejò ẹlẹgbẹ́ rẹ.” Ní pipari ọrọ naa, Jesu wipe: “Nitori olukuluku ẹni tí ó gbé araarẹ̀ ga ni a o rẹ̀ sílẹ̀ ẹni tí ó bá sì rẹ araarẹ̀ silẹ ni a o gbéga.”

Lẹhin eyi, Jesu bá Farisi tí ó késí i naa sọ̀rọ̀ tààràtà ó sì ṣàpèjúwe bí a ṣe lè pèsè ounjẹ kan tí ó ní ìtóye gidi lọ́dọ̀ Ọlọrun. “Nigba ti iwọ bá gbé oúnjẹ tabi oúnjẹ alẹ́ kalẹ̀, maṣe pe awọn ọ̀rẹ́ rẹ tabi awọn arakunrin rẹ̀ tabi awọn ẹbí rẹ tabi awọn ọlọ́rọ̀ aládùúgbò rẹ. Boya nigba miiran wọn tún lè késí iwọ naa pẹlu ní ìdapádà yoo sì di ìsanpadà fun ọ. Ṣugbọn nigba ti iwọ bá se àsè, pe awọn òtòṣì ènìyàn, amúkùn-ún, arọ, afọ́jú; iwọ yoo sì láyọ̀, nitori wọn kò ní ohun kankan tí wọn yoo fi san an padà fun ọ.”

Pípèsè irúfẹ́ ounjẹ kan bẹẹ fun awọn ti o ku diẹ kí-à-tó fun yoo mú ayọ̀ wá fun olùpèsè rẹ̀ nitori, gẹgẹ bi Jesu ṣe ṣàlàyé fun olùgbàlejò rẹ̀, “A o san an padà fun ọ ninu ajinde awọn olódodo.” Àpèjúwe Jesu nipa ounjẹ títóye yii pe irú ounjẹ miiran wá sí ọkàn àlejò ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan. “Aláyọ̀ ni ẹni naa tí ó jẹ oúnjẹ ninu ijọba Ọlọrun,” ni àlejò yii wí. Sibẹ, kii ṣe gbogbo ènìyàn ni ó ka ìrètí aláyọ̀ yẹn sí iyébíye lọna tí ó tọ̀nà, gẹgẹ bi Jesu ti nbaa lọ lati fihàn nipasẹ àkàwé kan.

“Ọkunrin kan bayii gbé ounjẹ alẹ́ títóbi kan kalẹ̀, ó sì késí ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sì rán ẹrú rẹ̀ jáde . . . lati wí fun awọn tí a késí pe, ‘Ẹ wá, nitori pe nisinsinyi awọn nǹkan ti wà ní sẹpẹ́.’ Ṣugbọn gbogbo wọn ní àpapọ̀ bẹrẹsii tọrọ gááfárà. Ekinni wí fun un, ‘Mo ra pápá kan ó sì yẹ kí emi jáde lọ kí emi sì rí i; mo bẹ̀ ọ́, Ṣe gááfárà fun mi.’ Òmíràn sì wipe, ‘Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún mo sì ńlọ lati lọ yẹ̀ wọn wò; mo bẹ̀ ọ́, Ṣe gááfárà fun mi.’ Òmíràn sibẹ sì tun wipe, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé aya kan níyàwó ati nitori ìdí eyi emi kò lè wá.’”

Wo awọn àwáwí tí kò lẹ́sẹ̀nílẹ̀ tí iwọnyẹn jẹ́! Pápá kan tabi ẹran ọ̀sìn ni a maa ńyẹ̀wò bí ó ti saba maa ńrí ṣaaju kí á tó rà wọn, nitori naa kò sí kánjúkánjú kankan nitootọ lati wò wọn lẹhin naa. Lọna tí ó farajọra, ìgbéyàwó ẹnikan kò gbọdọ ṣèdíwọ́ fun un lati tẹ́wọ́gbà irúfẹ́ ìkésíni pàtàkì kan bẹẹ. Nitori naa ní gbígbọ́ nipa awọn àwáwí wọnyi, ọ̀gá naa bínú ó sì pàṣẹ fun ẹrú rẹ̀ pe:

“‘Jáde lọ kiakia sí awọn ọ̀nà fífẹ̀ ati awọn ọ̀nà tóóró ní ìlú-ńlá, kí o sì múwá síhìn-ín awọn òtòṣì ati awọn amúkùn-ún ati awọn afọ́jú ati arọ.’ Láìpẹ́ ẹrú naa wipe, ‘Ọ̀gá, mo ti ṣe ohun tí ẹ pàṣẹ, sibẹ àyè ṣì nbẹ.’ Ọ̀gá naa sì wí fun ẹrú naa, ‘Jáde lọ sí awọn ojú ọ̀nà ati awọn ibi tí a fi ọgbà yíká, kí o sì sọ ọ́ di àpàpàǹdodo fun wọn lati wọlé wá, kí ilé mi ba lè kún. . . . Kò sí ọ̀kan ninu awọn ọkunrin wọnni tí a késí tí yoo tọ́wò ninu ounjẹ alẹ́ mi.’”

Ọ̀ràn wo ni àkàwé naa ṣàpèjúwe? Ó dára, “ọ̀gá” tí ó ńpèsè ounjẹ naa dúró fun Jehofa Ọlọrun; “ẹrú naa” tí ó nawọ́ ìkésíni jẹ́, Jesu Kristi; “ounjẹ alẹ́ títóbi naa,” sì jẹ́ awọn àǹfààní lati wà ní ìlà fun Ijọba awọn ọrun.

Awọn ẹni àkọ́kọ́ ti o gbà ìkésíni naa lati wà ní ìlà fun Ijọba naa, ṣaaju gbogbo awọn yooku, jẹ́ awọn aṣaaju-isin Juu ti ọjọ́ Jesu. Bí ó ti wù kí ó rí, wọn ṣá ìkésíni naa tì. Nipa bayii, bẹ̀rẹ̀ pàápàá ní Pẹntikọsti 33 C.E., ìkésíni keji ni a nawọ́ rẹ̀ jáde sí awọn ẹni rírẹlẹ̀ ati awọn tí a tẹ́ḿbẹ́lú ninu orílẹ̀-èdè Juu. Ṣugbọn awọn tí wọn dáhùnpadà kò tó lati kún awọn ibi-àyè 144,000 naa ninu Ijọba ọ̀run ti Ọlọrun. Nitori naa ní 36 C.E., ọdun mẹta aabọ lẹhin naa, ìkésíni kẹta tí ó sì kẹ́hìn ni a nawọ́ rẹ̀ sí awọn aláìkọlà tí kii ṣe Juu, ìkójọpọ̀ awọn ẹni bẹẹ sì nbaa lọ títí di ọjọ́ wa. Luuku 14:1-24.

▪ Ẹ̀kọ́ wo nipa ìrẹ̀lẹ̀ ni Jesu fi kọ́ni?

▪ Bawo ni olùgbàlejò kan ṣe lè pèsè ounjẹ kan tí ó ní ìtóye lọ́dọ̀ Ọlọrun, eeṣe tí yoo sì fi mú ayọ̀ bá a?

▪ Eeṣe tí àwáwí awọn àlejò tí a késí naa fi jẹ́ aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀?

▪ Ki ni àkàwé Jesu nipa “ounjẹ alẹ́ títóbi” naa dúró fun?