Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́-àpèrán Aláàánú kan Sí Judia

Iṣẹ́-àpèrán Aláàánú kan Sí Judia

Orí 89

Iṣẹ́-àpèrán Aláàánú kan Sí Judia

NÍ AWỌN ọsẹ diẹ ṣaaju, láàárín àkókò Àjọ-àríyá Ìyàsímímọ́ ní Jerusalẹmu, awọn Juu gbìyànjú lati pa Jesu. Nitori naa ó rìnrìn àjò lọ sí àríwá, tí ó hàn kedere pe ó jẹ́ àgbègbè kan tí kò jìnnà sí Òkun Galili.

Lẹnu aipẹ yii, o ti ńkọrísí guusu lẹẹkan sí i síhà Jerusalẹmu, tí ó nwaasu lọ lójú ọ̀nà ninu awọn abúlé Peria, àgbègbè kan ní ìlà-oòrùn Odò Jọdani. Lẹhin sísọ àkàwé kan nipa ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa ati Lasaru, ó ńbáa nìṣó ní kíkọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ní awọn nǹkan tí oun ti fi kọ́ni ṣaaju nigba tí ó wà ní Galili.

Fun apẹẹrẹ, oun sọ pe yoo jẹ́ àǹfààní jù fun ẹnikan “bí a bá so ọlọ kan mọ́ ọn ní ọrùn kí á sì jù ú sínú òkun” ju kí ó ṣokùnfà ìkọ̀sẹ̀ fun ọ̀kan ninu “awọn ẹni kéékèèké” ti o jẹ ti Ọlọrun. Ó tẹnumọ́ ọn pẹlu ìdí fun ìdáríjì, ní ṣíṣàlàyé pe: “Bí [arakunrin kan] bá tilẹ ṣẹ̀ ọ́ nigba meje lóòjọ́ tí ó sì padà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ ní ìgbà meje, wipe, ‘Mo ronúpìwàdà,’ iwọ gbọdọ dáríjì í.”

Nigba ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ beere pe, “Fikún ìgbàgbọ́ wa,” Jesu dáhùn pe: “Bí ẹyin bá ní ìgbàgbọ́ ìwọ̀n hóró musitadi kan, ẹ o sọ fun igi mulibẹri dúdú yii, ‘Ṣídìí kí á sì gbìn ọ́ sínú òkun!’ yoo sì ṣègbọràn si yin.” Nitori naa kódà ìgbàgbọ́ kekere kan lè ṣàṣeparí awọn ohun ńláǹlà.

Tẹle eyi, Jesu ròhìn ọ̀ràn kan tí ó ṣẹlẹ̀ tootọ ninu igbesi-aye tí ó ńṣàkàwé ẹ̀mí-ìrònú títọ̀nà tí iranṣẹ Ọlọrun olodumare. “Ta ni ninu yin tí ó ní ẹrú kan tí ńtúlẹ̀ tabi tí ńtọ́jú agbo ẹran,” ni Jesu ṣàlàyé, “tí yoo wí fun un nigba ti ó bá dé lati pápá, ‘Wá síhìn-ín kíámọ́sá kí o sì rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì’? Kàkà bẹẹ, oun kì yoo ha wí fun un pe, ‘Múra nǹkan silẹ kí emi jẹ oúnjẹ alẹ́ mi, kí o sì wọ épírọ́ọ̀nù rẹ lati ṣèrànṣẹ́ fun mi títí emi yoo fi jẹ tí emi yoo sì mu tán’? Oun kò ní dúpẹ́ lọwọ ẹrú naa nitori ó ṣe awọn ohun tí a yàn fun un, oun yoo ṣe bẹẹ bí? Bẹẹ gẹ́gẹ́ ẹyin, pẹlu, nigba ti ẹ bá ti ṣe gbogbo awọn ohun tí a yàn fun yin, ẹ wipe, ‘Awa jẹ ẹrú aláìdára-fún-ohunkohun. Ohun tí a ṣe ni o yẹ ki awa ṣe.’” Nipa bayii, awọn iranṣẹ Ọlọrun kò gbọdọ nímọ̀lára láé pe wọn ńṣe Ọlọrun ní ojúrere nipa ṣíṣiṣẹ́ sìn ín. Kàkà bẹẹ, wọn gbọdọ maa ranti àǹfààní tí wọn ní lati jọ́sìn rẹ̀ gẹgẹ bi mẹmba agbo-ilé rẹ̀ tí a fún ní ohun àfúnniṣọ́.

Bí ó ti hàn kedere ó jẹ́ ní àkókò kúkúrú lẹhin tí Jesu fúnni ní àkàwé yii ni oníṣẹ́ kan dé. Maria ati Mata, awọn arabinrin Lasaru, tí wọn ńgbé ní Bẹtani ti Judia, ni wọn sì rán an. “Oluwa, wòó! ẹni tí iwọ fẹ́ràn ńṣàìsàn,” ni oníṣẹ́ naa ròhìn.

Jesu fèsìpadà pe: “Òpin ìlépa àìsàn yii kii ṣe ikú, ṣugbọn ó wà fun ògo Ọlọrun, kí a ba lè ṣe Ọmọkunrin Ọlọrun lógo nipasẹ rẹ̀.” Lẹhin dídúró fun ọjọ meji níbi tí ó wà, Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Ẹ jẹ́ kí a tún lọ sí Judia.” Bí ó ti wù kí ó rí, wọn rán an létí pe: “Rabi, láìpẹ́ yii gan-an awọn ara Judia ńwá ọ̀nà lati sọ ọ́ ní òkúta, iwọ o ha sì tún lọ sibẹ bí?”

“Wakati mejila ojúmọmọ ní nbẹ, tabi bẹẹkọ?” Jesu beere ní ìfèsìpadà. “Bí ẹnikẹni bá rìn ní ojúmọmọ kì yoo kọlù ohunkohun, nitori oun rí ìmọ́lẹ̀ ayé yii. Ṣugbọn bí ẹnikẹni bá rìn ní alẹ, oun a kọlù nǹkankan, nitori ìmọ́lẹ̀ kò sí ninu rẹ̀.”

Ohun tí Jesu ní lọ́kàn ní kedere ni pe “wakati ojúmọmọ,” tabi àkókò tí Ọlọrun ti yàn fun iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé, kò tíì kọjá lọ, títí wọn yoo sì fi ṣe bẹẹ, ẹnikẹni kò lè pa á lára. Ó jẹ́ ọ̀ranyàn fun un lati lò àkókò kukuru “ojúmọmọ” tí ó ṣẹ́kù fun un dé ẹkunrẹrẹ, niwọn bi “òru” yoo dé nígbẹ̀hìn nigba ti awọn ọ̀tá rẹ̀ yoo ti pa á.

Jesu fikun un pe: “Lasaru ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣugbọn emi yoo rìnrìn àjò lọ sibẹ lati jí i dìde ninu oorun.”

Bí ó ti hàn kedere pe wọn ronú pe Lasaru ńsinmi ninu oorun ati pe eyi jẹ́ àmì rere kan pe ara rẹ̀ yoo dá, awọn ọmọ-ẹhin naa dáhùnpadà pe: “Oluwa, bí ó bá ti lọ sinmi, ara rẹ̀ yoo dá.”

Nigba naa ni Jesu sọ fun wọn ní ṣàkó pe: “Lasaru ti kú, mo sì yọ̀ nítìtorí yin pe emi kò sí nibẹ, kí ẹyin lè gbàgbọ́. Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí á lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.”

Ní mimọ pe ó ṣeeṣe kí a pa Jesu ní Judia, sibẹ tí wọn fẹ́ lati tẹle e lẹhin, Tomasi fun awọn ọmọ-ẹhin ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ìṣírí pe: “Ẹ jẹ́ kí awa pẹlu lọ, kí a lè bá a kú.” Nitori naa lábẹ́ ìfi ẹ̀mí araawọn wewu, awọn ọmọ-ẹhin ba Jesu rin pẹlu ninu iṣẹ́-àpèrán aláàánú yii sí Judia. Luuku 13:22; 17:1-10, NW; Johanu 10:22, 31, 40-42; 11:1-16, NW.

▪ Nibo ni Jesu ti nwaasu lẹnu aipẹ yii?

▪ Awọn ẹ̀kọ́ wo ni Jesu tún sọ, ipò wo tí ó ṣẹlẹ nitootọ ninu igbesi-aye sì ni oun ṣàpèjúwe rẹ̀ lati ṣàkàwé kókó wo?

▪ Ìhìn wo ni Jesu gbà, ki ni oun sì ní lọ́kàn nipa “ojúmọmọ” ati “alẹ́”?

▪ Ki ni Tomasi ní lọ́kàn nigba ti ó sọ pe, ‘Ẹ jẹ́ kí awa lọ kí a lè bá a kú’?