Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́-òjíṣẹ́ ní Tẹmpili Parí

Iṣẹ́-òjíṣẹ́ ní Tẹmpili Parí

Orí 110

Iṣẹ́-òjíṣẹ́ ní Tẹmpili Parí

JESU ṣe ìfarahàn rẹ̀ ikẹhin ni tẹmpili. Niti tootọ, oun npari iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ itagbangba lori ilẹ̀-ayé àyàfi awọn ìṣẹ̀lẹ̀ lakooko ìgbẹ́jọ́ ati ìfìyà ikú jẹni rẹ ní ọjọ́ mẹta lẹhin naa. Nisinsinyi oun nbá ìbáwí mímúná rẹ̀ fun awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi nìṣó.

Ní igba mẹta sii oun ṣe sáàfúlà pe: “Ègbé ni fun yin ẹyin akọ̀wé ati ẹyin Farisi, àgàbàgebè!” Lákọ̀ọ́kọ́ oun pòkìkí ègbé le wọn nitori wọn ńfọ “òde ife ati ti àwo oúnjẹ mọ́, ṣugbọn ninu wọn kún fun ìpiyẹ́ ati àìmọníwọ̀n.” Nitori naa oun fun wọn ní ìṣílétí pe: “Ẹ kọ́kọ́ fọ̀ inu ife ati ti àwo oúnjẹ mọ́, kí òde rẹ̀ lè di mímọ́tónítóní pẹlu.”

Lẹhin naa oun kede ègbé sori awọn akọ̀wé ati awọn Farisi fun ìjẹrà ninu ati ìdíbàjẹ́ tí wọn gbiyanju lati fi pamọ nipa ẹ̀mí-ìsìn ìhà-òde. Oun wipe, “Ẹyin dabi awọn isà-òkú tí a fi ẹfun kùn, níhà òde wọn farahàn nitootọ bi ẹlẹ́wà ṣugbọn ninu wọn kún fun egungun awọn òkú eniyan ati gbogbo iru oriṣi àìmọ́.”

Nikẹhin, àgàbàgebè wọn farahàn kedere ninu ìfẹ́ wọn lati kọ́ ibojì fun awọn wolii ati lati ṣe é lóge lati fà àfiyèsí sí awọn iṣẹ́ àánú tiwọn funraawọn. Sibẹ, gẹgẹ bi Jesu ti ṣí i payá, wọn jẹ́ “ọmọkunrin awọn wọnni tí wọn ṣìkàpa awọn wolii.” Nitootọ, ẹnikẹni tí ó bá gbójúgbóyà lati tú àṣírí àgàbàgebè wọn wà ninu ewu!

Ní titẹsiwaju, Jesu sọ awọn ọ̀rọ̀ ìfibú rẹ̀ lílágbára julọ jade. “Ẹyin ejò, ìran ọmọ awọn paramọ́lẹ̀,” ni oun wi, “bawo ni ẹyin yoo ṣe sá fun idajọ Gẹhẹna?” Gẹhẹna ni àfonífojì tí wọn ńlò gẹgẹ bi ibi tí a ńda pàǹtírí sí ní Jerusalẹmu. Nitori naa Jesu nsọ pe nitori lílépa ipa-ọ̀nà buruku wọn, awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi yoo jiya iparun àìnípẹ̀kun.

Nipa awọn wọnni tí oun ran jade lọ gẹgẹ bi awọn aṣojú rẹ̀, Jesu sọ pe: “Awọn kan ninu wọn ni ẹyin yoo pa tí ẹ o sì kànmọ́gi, awọn kan ninu wọn ni ẹyin yoo sì nà ní pàṣán ninu awọn sinagọgu yin tí ẹ o sì ṣe inunibinu sí lati ilu dé ilu; kí ẹ̀jẹ̀ gbogbo awọn olododo tí a ti tasílẹ̀ lori ilẹ̀-ayé lè wá sori yin, lati ẹ̀jẹ̀ Ebẹli olododo títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekaraya ọmọkunrin Barakaya [tí a pè ni Jehoada ni Kironika Keji], ẹni tí ẹyin ṣìkàpa laaarin ibùjọsìn ati pẹpẹ. Loootọ ni mo wi fun yin, Gbogbo nǹkan wọnyi yoo wá sori iran eniyan yii.”

Nitori pe Sekaraya dá awọn aṣaaju Isirẹli lẹ́bi lọna rírorò, “wọn di rìkíṣí, wọn sì sọ ọ́ ni òkúta nipa aṣẹ ọba ní àgbàlá ilé Oluwa [“Jehofa,” NW].” Ṣugbọn, gẹgẹ bi Jesu ti sọtẹlẹ Isirẹli yoo ṣe isanpada irufẹ gbogbo ẹ̀jẹ̀ olododo bẹẹ tí wọn tasílẹ̀. Wọn san an pada ní 37 ọdun lẹhin naa, ní 70 C.E., nigba ti ọmọ ogun Roomu pa Jerusalẹmu run tí ohun tí ó ju million kan awọn Juu sì ṣègbé.

Bí Jesu ti ńgbé ipò ti ndẹrubani yii yẹ̀wò, ìdààmú bá a. “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu,” ni oun pòkìkí lẹẹkan sii, “bawo ni ó ti jẹ́ nígbàkugbà tó ti emi ti fẹ kó ọmọ rẹ jọpọ̀ ní ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ fi ńkó awọn òròmọ adìyẹ jọpọ̀ sábẹ́ ìyẹ́-apá rẹ̀! Ṣugbọn ẹyin eniyan yii kò fẹ́ ẹ. Sáwòó! A pa ilé yin tì fun yin.”

Jesu fikun un lẹhin naa pe: “Ẹyin kì yoo rí mi mọ́ lọ́nàkọnà lati isinsinyi lọ́ títí ẹyin yoo fi wipe, ‘Olubukun ni ẹni naa tí ńbọ̀ ní orukọ Jehofa!’” Ọjọ́ yẹn yoo jẹ́ nigba wíwàníhìn-ín Kristi nigba ti ó bá dé sinu Ijọba rẹ̀ ti ọ̀run tí awọn eniyan sì rí i pẹlu ojú igbagbọ.

Jesu nisinsinyi sún sẹ́gbẹ́ẹ́kan nibi ti ó ti lè maa ṣọ́ awọn àpótí ìṣúra ninu tẹmpili ati awọn ogunlọgọ tí wọn nsọ owó sinu wọn. Awọn ọlọ́rọ̀ nsọ ọpọlọpọ ẹyọ-owó sinu rẹ̀. Ṣugbọn nigba naa òtòṣì opó kan wá sí ìtòsí ó sì sọ ẹyọ-owó kéékèèké meji tí wọn ní ìníyelórí kíkéré gan-an silẹ.

Ní pípè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ súnmọ́tòsí, Jesu sọ pe: “Loootọ ni mo wi fun yin pe òtòṣì opó yii sọ owó pupọ sinu rẹ̀ ju gbogbo awọn wọnni tí ńsọ owó sinu àpótí ìṣúra.” Wọn gbọdọ ti ṣe kàyéfì bí eyi ṣe lè jẹ́ bẹẹ. Nitori naa Jesu ṣalaye pe: “Gbogbo wọn sọ sinu rẹ̀ lati inú ọpọ rẹpẹtẹ wọn, ṣugbọn oun, lati inú àìní rẹ̀, sọ gbogbo ohun tí ó ní sinu rẹ̀, gbogbo ohun-ìní igbesi-aye rẹ̀.” Lẹhin tí ó ti sọ awọn nǹkan wọnyi, Jesu jade lọ kuro ninu tẹmpili fun ìgbà ikẹhin.

Bi ẹnu tí yà wọn sí ìtóbi ati ẹwà tẹmpili naa, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ṣe sáàfúlà pe: “Olukọ, woo! Iru awọn òkúta ati iru awọn ilé-kíkọ́ tí ó wà nihinyii!” Nitootọ, awọn òkúta naa ni a rohin rẹ̀ pe wọn gùn jù 35 ẹsẹ̀-bàtà, wọn fẹ̀ ju 15 ẹsẹ̀-bàtà, wọn sì ga sókè ní ìwọ̀n tí ó jù 10 ẹsẹ̀-bàtà!

“Ṣe ẹ rí awọn ilé-kíkọ́ ńláǹlà wọnyi?” ni Jesu fèsìpadà. “A kì yoo fi òkúta kan sílẹ̀ níhìn-ín lọ́nàkọnà lórí ekeji tí a kì yoo wó lulẹ̀.”

Lẹhin tí ó ti sọ awọn nǹkan wọnyi, Jesu ati awọn apọsiteli rẹ̀ rekọja Àfonífojì Kidironi wọn sì gùn Òkè Olifi. Lati ibẹ̀ wọn lè maa wò tẹmpili gbígbórín naa lati òkè. Matiu 23:25–24:3; Maaku 12:41–13:3; Luuku 21:1-6; 2 Kironika 24:20-22, NW.

▪ Ki ni Jesu ṣe nigba ìbẹ̀wò rẹ̀ ikẹhin sí tẹmpili?

▪ Bawo ni àgàbàgebè awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi ṣe farahàn?

▪ Ki ni “idajọ Gẹhẹna” tumọsi?

▪ Eeṣe ti Jesu fi sọ pe opó naa ṣe itọrẹ tí ó pọ̀ jù ti awọn ọlọ́rọ̀?