Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ Iyanu Pupọ Sii ni Kapanaomu

Iṣẹ Iyanu Pupọ Sii ni Kapanaomu

Orí 23

Iṣẹ Iyanu Pupọ Sii ni Kapanaomu

SABAATI ti o tẹle eyi ti Jesu pe awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ mẹrin akọkọ—Peteru, Anderu, Jakọbu, ati Johanu—gbogbo wọn jumọ lọ sí sinagọgu adugbo kan ti o wà ni Kapanaomu. Nibẹ Jesu bẹrẹsii kọnilẹkọọ, háà sì ṣe awọn eniyan naa nitori pe o nkọ wọn gẹgẹ bi ẹnikan ti o ní ọla aṣẹ kii sii ṣe bii awọn akọwe ofin.

Ni Sabaati yii ọkunrin ẹlẹmii eṣu kan wà nibẹ. Lẹhin akoko diẹ, o kigbe soke pẹlu ohùn rara pe: “Ki ni ṣe tawa tìrẹ, Jesu ara Nasarẹti? Iwọ wá lati pa wa run? Emi mọ ẹni ti iwọ nṣe: Ẹni Mimọ Ọlọrun.”

Ẹmi eṣu ti ndari ọkunrin naa ni dajudaju jẹ ọkan lara awọn angẹli Satani. Ni biba ẹmi eṣu naa wi lọna ti o lekoko, Jesu wipe: “Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o sì jade kuro lara rẹ̀!”

Ko buru, ẹmi eṣu naa mu ki gìrì mú ọkunrin naa tí ó sì kérara jade pẹlu ohùn rẹ̀. Ṣugbọn ó jade kuro ninu ọkunrin naa laipa a lara. Iyanu sì bá gbogbo ẹni ti nbẹ nibẹ! “Ki ni eyi?” ni wọn beere. ‘O fi agbara paṣẹ fun awọn ẹmi aimọ, wọn sì gbọ́ tirẹ̀.’ Irohin nipa eyi tàn yika gbogbo agbegbe ti o yii ka.

Ni fifi sinagọgu naa silẹ, Jesu ati awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ lọ si ile Simoni, tabi Peteru. Nibẹ iya iyawo Peteru dubulẹ aisan ibà. ‘Jọwọ ràn án lọwọ,’ ni wọn bẹ̀bẹ̀. Nitori naa Jesu lọ si ibẹ, ó mú un dani ni ọwọ́, ó sì fà á dìde. Lẹsẹkan naa ara rẹ̀ yá, ó sì bẹrẹsii pese ounjẹ fun wọn!

Nigba ti o ṣe, lẹhin ti oorun ti wọ̀, awọn eniyan lati ibi gbogbo bẹrẹsii wá sí ile Peteru pẹlu awọn alaisan wọn. Laipẹ jọjọ gbogbo ilu naa ti pejọ lẹnu ọna! Jesu sì wo gbogbo awọn alaisan wọn sàn, ohun yoowu ti aarun naa lè jẹ́. Koda o tilẹ dá awọn ti o ni ẹmi eṣu silẹ. Bi wọn ti njade, awọn ẹmi eṣu ti o nle jade naa nkigbe pe: “Iwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọrun.” Ṣugbọn Jesu bá wọn wí lọna lilekoko tí kò sì fi ààyè gbà wọn lati sọrọ nitori wọn mọ̀ pe oun ni Kristi naa. Maaku 1:21-34; Luuku 4:31-41; Matiu 8:14-17.

▪ Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ ni sinagọgu ni Sabaati lẹhin ti Jesu ti pe awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ mẹrin?

▪ Nibo ni Jesu lọ nigba ti o fi sinagọgu silẹ, iṣẹ iyanu wo ni oun sì ṣe nibẹ?

▪ Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ lẹhin naa ni irọlẹ ọjọ yẹn gan-an?