Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibẹrẹpẹpẹ Igbesi-aye Idile Jesu

Ibẹrẹpẹpẹ Igbesi-aye Idile Jesu

Orí 9

Ibẹrẹpẹpẹ Igbesi-aye Idile Jesu

NIGBA ti Jesu ndagba ni Nasarẹti, o wulẹ jẹ ilu kekere kan, ti kò lókìkí. O wà ni igberiko oloke ní agbegbe kan ti a npe ni Galili, ti kò jinna sí Afonifoji Jẹsirẹli ẹlẹwa ni.

Nigba ti a gbé Jesu wá sihin-in, boya ni nǹkan bii ẹni ọdun meji, lati Íjíbítì pẹlu Josẹfu ati Maria, dajudaju oun ṣì jẹ́ ọmọ kanṣoṣo ti Maria bí nigba naa. Ṣugbọn kii ṣe fun igba pipẹ. Bí akoko ti nlọ, a bí Jakọbu, Josẹfu, Simoni, ati Judasi, Maria ati Josẹfu sì di òbí fun awọn ọmọbinrin pẹlu. Nikẹhin Jesu ni, o kerepin, awọn aburo ọkunrin ati obinrin ti wọn jẹ́ mẹfa.

Jesu ní awọn ibatan miiran pẹlu. A ti mọ̀ tẹlẹ nipa Johanu mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ti o dagba jù ú lọ, ti o ngbe ni ọpọlọpọ ibusọ ní Judia. Ṣugbọn ẹni ti o tubọ ngbe nitosi ni Galili ni Salome, ẹni tí ẹ̀rí fihan kedere pe o jẹ arabinrin Maria. Salome fẹ́ Sebede, nitori naa awọn ọmọkunrin wọn mejeeji, Jakobu ati Johanu, yoo jẹ́ mọ̀lẹ́bí Jesu. Awa kò mọ boya, nigba ti o ndagba, Jesu lo akoko pupọ pẹlu awọn ọmọkunrin wọnyi, ṣugbọn nigba ti o ya wọn di alabaakẹgbẹpọ timọtimọ.

Josẹfu nilati ṣe iṣẹ aṣekara lati ṣe itilẹhin fun idile rẹ̀ ti ntobi sii. Oun jẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà kan. Josẹfu tọ́ Jesu dagba gẹgẹ bi ọmọkunrin ti oun fúnraarẹ̀, nitori naa a pe Jesu ni “ọmọ gbẹ́nàgbẹ́nà.” Josẹfu kọ́ Jesu lati jẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà pẹlu, oun sì kẹkọọ daradara. Ìdí niyẹn ti awọn eniyan lẹhin naa fi sọ nipa Jesu pe, “Eyi ni gbẹ́nàgbẹ́nà naa.”

Igbesi-aye idile Josẹfu ni a kọ́ yika ijọsin Jehofa Ọlọrun. Ní pipa Ofin Ọlọrun mọ́, Josẹfu ati Maria fun awọn ọmọ wọn ní itọni nipa tẹmi ‘nigba ti wọn bá jokoo ninu ile wọn, nigba ti wọn ba nrin ni ọna, nigba ti wọn ba dubulẹ, ati nigba ti wọn bá dide.’ Sinagọgu kan wà ni Nasarẹti, ó sì lè dá wa loju pe Josẹfu pẹlu maa nko idile rẹ lọ jọ́sìn nibẹ deedee. Ṣugbọn laisi aniani wọn rí igbadun wọn giga julọ ninu ririn irin ajo deedee lọ si tẹmpili Jehofa ni Jerusalẹmu. Matiu 13:55, 56; 27:56; Maaku 15:40; 6:3, NW; Deutaronomi 6:6-9.

▪ O kerepin, aburo ọkunrin ati obinrin meloo ni Jesu ni, kí sì ni orukọ diẹ lara wọn?

▪ Awọn mọ̀lẹ́bí Jesu mẹta wo ni a mọ̀ dunjú?

▪ Iṣẹ́ ọwọ́ wo ni Jesu wá tẹwọgba, eesitiṣe?

▪ Itọni pataki wo ni Josẹfu pese fun idile rẹ̀?