Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ifihan Ṣaaju Ògo Ijọba Kristi

Ifihan Ṣaaju Ògo Ijọba Kristi

Orí 60

Ifihan Ṣaaju Ògo Ijọba Kristi

JESU ti dé awọn apákan Kesaria ti Filipi, ó sì ńkọ́ ogunlọgọ kan tí ó ní awọn apọsiteli rẹ̀ ninu. Oun ṣe ìfilọ̀ tí ó múnitagìrì yii fun wọn: “Lóòótọ́ ni mo wi fun yin pe awọn miiran wà ninu awọn tí ó dúró níhìn-ín yii tí kì yoo tọ́ ikú wò rárá títí di ìgbà tí wọn bá kọ́kọ́ rí Ọmọkunrin eniyan tí nbọ ninu ijọba rẹ̀.”

‘Ki ni Jesu lè ní lọ́kàn?’ ni awọn ọmọ-ẹhin naa gbọdọ ṣe kàyéfì. Nǹkan bii ọsẹ kan lẹhin naa, Jesu mú Peteru, Jakọbu, ati Johanu pẹlu rẹ̀, wọn sì gùn òkè gíga fíofío kan lọ. Ó ṣeeṣe kí ó jẹ́ ní alẹ́, niwọnbi ó ti jẹ́ pe awọn ọmọ-ẹhin naa ńtòògbé. Nigba tí Jesu ngbadura, a pa á láradà ní ojú wọn. Ojú rẹ̀ bẹrẹsii tàn bii oòrùn, àwọ̀ aṣọ rẹ̀ sì di eyi tí ó ńtàn yanranyanran bii ìmọ́lẹ̀.

Nigba naa, ìrí ẹ̀dá meji, tí a dámọ̀ gẹgẹ bi “Mose ati Elija,” farahàn, wọn sì bẹrẹsii bá Jesu sọ̀rọ̀ nipa ‘ìjádelọ rẹ̀ tí yoo ṣẹlẹ̀ ní Jerusalẹmu.’ Ìjádelọ naa ní kedere tọ́kasí ikú Jesu ati ajinde tí yoo tẹle e. Nipa bẹẹ, ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ yii fihàn pe ikú atẹ́nilógo rẹ̀ yii kii ṣe ohun kan lati yẹra fun, gẹgẹ bi Peteru ti fẹ́.

Bi wọn ti jípépé nisinsinyi, awọn ọmọ-ẹhin naa ńwòran wọn sì nfetisilẹ pẹlu kàyéfì. Bí ó tilẹ jẹ́ pe eyi jẹ́ ìran kan, ó farahàn bí òtítọ́ gidi tobẹẹ tí Peteru fi bẹrẹsii kopa ninu ìran naa, ní wiwi pe: “Oluwa, ó dára fun wa lati wà níhìn-ín. Bí iwọ bá fẹ́, emi yoo kọ́ àgọ́ mẹta síhìn-ín, ọ̀kan fun iwọ ọ̀kan fun Mose ati ọ̀kan fun Elija.”

Nigba tí Peteru ṣì ńsọ̀rọ̀ lọwọ, àwọsánmà mímọ́lẹ̀ yòò kan bò wọn, ohùn kan lati inú àwọsánmà naa sì wipe: “Eyi ni Ọmọkunrin mi, aayo olùfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́gbà; ẹ maa gbọ́ tirẹ̀.” Ní gbígbọ́ ohùn naa, awọn ọmọ-ẹhin naa da ojú wọn bolẹ̀. Ṣugbọn Jesu wipe: “Ẹ dìde kí ẹ má sì bẹ̀rù.” Nigba ti wọn dìde wọn kò rí ẹnikẹni yàtọ̀ sí Jesu.

Nigba tí wọn ńsọ̀kalẹ̀ bọ̀ lati orí òkè-ńlá naa ní ọjọ keji, Jesu pa á láṣẹ pe: “Ẹ kò gbọdọ sọ ìran naa fun ẹnikẹni títí a o fi jí Ọmọkunrin eniyan dìde kuro ninu òkú.” Ìfarahàn Elija ninu ìran naa gbé ibeere kan dìde ninu èrò-inú awọn ọmọ-ẹhin naa. “Eeṣe,” ni wọn beere, “tí awọn akọwe-ofin fi ńsọ pe Elija gbọdọ kọ́kọ́ wá?”

“Elija ti wá ná,” ni Jesu wí, “wọn kò sì mọ̀ ọ́n dájú.” Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, ńsọ̀rọ̀ nipa Johanu Arinibọmi, tí ó mú iṣẹ́ kan tí ó jọra pẹlu ti Elija ṣe. Johanu pa ọ̀nà mọ́ fun Kristi, gẹgẹ bi Elija ti ṣe fun Eliṣa.

Ẹ wo bi ìran yii ṣe jẹ́ eyi tí ó ńfúnni lókun tó, fun Jesu ati fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lápapọ̀! Ìran naa, gẹgẹ bi a ti lè sọ pe ó rí, jẹ́ ifihan ṣaaju ogo Ijọba Kristi. Awọn ọmọ-ẹhin naa rí, niti tootọ, “Ọmọkunrin eniyan tí ńbọ̀ ninu ògo ijọba rẹ̀,” gan-an gẹgẹ bi Jesu ti ṣèlérí ní ọsẹ kan ṣaaju. Lẹhin ikú Jesu, Peteru kọwe nipa ‘dídi ẹlẹrii olùfojúrí ti ìtóbilọ́lá Kristi nigba tí wọn wà pẹlu rẹ̀ ní orí òkè mímọ́ naa.’

Awọn Farisi ti beere àmì kan lọwọ Jesu tí yoo fihàn pe oun ni ẹni tí a ṣèlérí ninu Iwe Mimọ lati jẹ́ Ọba àyànfẹ́ Ọlọrun. A kò fun wọn ní irúfẹ́ àmì bẹẹ. Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin Jesu tímọ́tímọ́ ni a yọnda fun lati rí ìparadà Jesu gẹgẹ bi itilẹhin alagbara kan fun awọn asọtẹlẹ Ijọba naa. Nipa bayii, Peteru kọwe lẹhin naa pe: “Nitori naa ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ naa ni a túbọ̀ múdájú sí i.” Matiu 16:13, Mt 16:28–17:13; Maaku 9:1-13; Luuku 9:27-37; 2 Peteru 1:16-19, NW.

▪ Kí wọn tó tọ́ ikú wò, bawo ni awọn kan ṣe rí dídé Kristi ninu Ijọba rẹ̀?

▪ Ninu ìran naa, ki ni ohun tí Mose ati Elija sọ̀rọ̀ nipa rẹ̀ pẹlu Jesu?

▪ Eeṣe tí ìran yii fi jẹ́ irúfẹ́ àrànṣe afúnnilókun kan bẹẹ fun awọn ọmọ-ẹhin?