Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Irora Ẹdun Ninu Ọgba Naa

Irora Ẹdun Ninu Ọgba Naa

Orí 117

Irora Ẹdun Ninu Ọgba Naa

NIGBA ti Jesu pari gbigbadura, oun ati awọn oluṣotitọ apọsiteli rẹ̀ 11 kọ awọn orin iyin si Jehofa. Lẹhin naa wọn sọkalẹ lati iyara oke naa, wọn jade sinu okunkun alẹ́ titutu minimini, wọn sì pada forile isọda Afonifoji Kidironi, niha Bẹtani. Ṣugbọn loju ọna, wọn duro nibi ayanlaayo kan, ọgba Gẹtisemani. Eyi wa ni ọgangan tabi ni sakaani Òkè Olifi. Niye igba ni Jesu ti pade pẹlu awọn apọsiteli rẹ̀ nihin-in laaarin awọn igi olifi.

Ni fifi mẹjọ ninu awọn apọsiteli rẹ̀ silẹ—boya nitosi ẹnu ọna ọgba naa—o fun wọn ni itọni: “Ẹ jokoo nihin-in nigba ti emi ba lọ sọhun-un lati gbadura.” Lẹhin naa ni o mu awọn mẹta yooku—Peteru, Jakọbu, ati Johanu—o sì rin siwaju sinu ọgba naa. Ẹdun ọkan ba Jesu o sì daamu tẹduntẹdun. “A kó ẹdun ọkan ba ọkan mi gidigidi, ani de iku,” ni oun sọ fun wọn. “Ẹ duro nihin-in ki ẹ sì maa baa niṣo ni ṣiṣọna pẹlu mi.”

Ni lilọ siwaju diẹ, Jesu wolẹ ni dida oju rẹ bolẹ o bẹrẹsii gbadura pẹlu ifọkansi: “Baba mi, bi o ba ṣeeṣe, jẹ ki aago yii kọja kuro lọdọ mi. Sibẹ, kii ṣe bi ifẹ mi bikoṣe bi ifẹ rẹ.” Ki ni oun ni lọkan? Eeṣe ti oun fi ‘ni ẹdun ọkan gidigidi, ani de iku’? Oun ha nfasẹhin kuro ninu ipinnu rẹ̀ lati kú ati lati pese irapada ni bi?

Rara o! Jesu kò bẹ̀bẹ̀ pe ki a da oun si kuro lọwọ iku. Ani ironu yiyẹra fun iku irubọ paapaa, ti Peteru damọran rẹ nigba kan, jẹ ìríra fun un. Kaka bẹẹ, oun wa ninu irora nitori pe oun bẹru pe ọna ti oun yoo gba ku laipẹ—gẹgẹ bi òkúùgbẹ́ oniwa ọdaran kan—yoo mu ẹgan wa sori orukọ Baba rẹ̀. Oun nisinsinyi nimọlara pe ni iwọnba wakati diẹ sii a o kan oun mọ́gi bi ẹni buburu kan—asọrọ odi lodisi Ọlọrun! Eyi ni ohun ti o daamu rẹ gan-an gidigidi.

Lẹhin gbigbadura fun akoko gigun kan, Jesu pada o sì ri awọn apọsiteli mẹta naa ti nsun. Ni biba Peteru sọrọ taarata, oun wipe: “Ṣe ẹyin eniyan yii kò tilẹ le ba mi ṣọna fun wakati kan ni bi? Ẹ maa baa niṣo ni ṣiṣọna ki ẹ sì maa gbadura nigba gbogbo, ki ẹyin ma baa bọ sinu idẹwo.” Bi o ti wu ki o ri, ni jijẹwọ pe wọn wa labẹ masunmawo ati pe wakati ọjọ naa ti lọ jinna, oun wipe: “Ẹmi nharagaga, ṣugbọn ẹran ara ṣe ailera.”

Lẹhin naa Jesu pada lọ ni igba keji o sì beere pe ki Ọlọrun mu “ago yii” kuro lọdọ oun, iyẹn ni, ipin tabi ifẹ inu Jehofa fun un. Nigbati oun pada wa, o tun ri awọn mẹta naa ti nsun lẹẹkan sii nigba ti wọn ì bá ti maa gbadura pe ki wọn maṣe bọ sinu idẹwo. Nigba ti Jesu ba wọn sọrọ, wọn kò mọ ohun ti wọn yoo sọ ni ifesi pada.

Ni igbẹhin gbẹhin, ni igba kẹta, Jesu lọ si itosi, bi o sì ti wà lori eékún rẹ̀ o gbadura pẹlu ẹkun alokunlagbara ati omije pe: “Baba, bi iwọ ba fẹ, mu ago yii kuro lọdọ mi.” Lọna ti o muna Jesu nimọlara irora ti o lekenka nitori ẹgan ti iku rẹ gẹgẹ bi ọdaran kan yoo mu wa sori orukọ Baba rẹ̀. Họwu, ki a finisun gẹgẹ bi asọrọ odi kan—ẹnikan ti o gegun-un fun Ọlọrun—fẹrẹẹ jẹ ohun ti o pọ ju lati mu mọra!

Bi o tilẹ ri bẹẹ, Jesu nbaa lọ lati gbadura pe: “Kii ṣe ohun ti emi nfẹ, bikoṣe ohun ti iwọ fẹ.” Jesu fi pẹlu igbọran mu ifẹ inu tirẹ tẹriba fun ti Ọlọrun. Pẹlu eyi, angẹli kan lati ọrun farahan o sì fun un lokun pẹlu awọn ọrọ ti nfunni ni iṣiri. O jọ bi ẹni pe angẹli naa sọ fun Jesu pe o ni ẹrin musẹ itẹwọgba Baba rẹ̀.

Sibẹ, ẹ wo ẹru ti o tẹ̀wọ̀n ti o wà ni awọn ejika Jesu! Iye ayeraye oun funraarẹ ati ti gbogbo ẹya iran ẹda eniyan wà ni aidaniloju sibẹ. Masunmawo ero imọlara naa pọ tabua. Nitori naa Jesu nbaa lọ ni gbigbadura pẹlu itara pupọ sii, oogun rẹ̀ sì wa dabii awọn ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ bi o ti nbọ sori ilẹ. “Bi eyi tilẹ jẹ ohun àrà ṣiṣọwọn gan-an,” ni The Journal of the American Medical Association ṣalaye, “oogun ẹlẹ́jẹ̀ . . . le waye niu ipo ọran elero imọlara giga.”

Lẹhin igba naa, Jesu pada sọdọ awọn apọsiteli rẹ̀ fun igba kẹta, ati lẹẹkan sii o ri wọn ti wọn nsun. Ẹdun ọkan paraku ti tán wọn lókun. “Ni iru akoko kan bi eyi ni ẹyin nsun ti ẹ sì nsinmi!” ni oun ṣe saafula. “O tó! Wakati naa ti de! Ẹ wòó! A fi Ọmọkunrin eniyan si ọwọ́ awọn ẹlẹṣẹ. Ẹ dide, ẹ jẹ ki a lọ. Ẹ wòó! Afinihan mi ti sunmọtosi.”

Nigba ti o ṣì nsọrọ lọwọ, Judasi Iskariọti yọ si i, pẹlu ogunlọgọ awọn eniyan ni gbigbe awọn ògùṣọ̀ ati awọn fitila ati awọn ohun ija. Matiu 26:30, 36-47; 16:21-23; Maaku 14:26, 32-43; Luuku 22:39-47; Johanu 18:1-3; Heberu 5:7, NW.

▪ Lẹhin fifi iyara oke silẹ, nibo ni Jesu mú awọn apọsiteli rẹ̀ lọ, ki ni o sì ṣe nibẹ?

▪ Nigba ti Jesu ngbadura, ki ni awọn apọsiteli nṣe?

▪ Eeṣe ti Jesu fi wà ninu irora ẹdun, ibeere wo ni o sì beere lọdọ Ọlọrun?

▪ Ki ni òógùn Jesu ti o dabii awọn ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ fihan?