Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jíjẹun Pẹlu Farisi Kan

Jíjẹun Pẹlu Farisi Kan

Orí 76

Jíjẹun Pẹlu Farisi Kan

LẸHIN tí Jesu ti dáhùn ibeere awọn lámèyítọ́ nipa orísun agbára rẹ̀ lati mú ọkunrin kan láradá ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, Farisi kan késí i fun oúnjẹ alẹ́. Ṣaaju kí wọn tó jẹun, awọn Farisi kówọnú ààtò wíwẹ awọn ọwọ́ wọn títí dé ìgúnpá. Wọn ńṣe eyi ṣaaju ati lẹhin ounjẹ ati kódà láàárín ounjẹ. Bí ó tilẹ jẹ́ pe àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yii kò tẹ òfin Ọlọrun tí a ti kọsílẹ̀ lójú, ó lọ rékọjá ohun tí Ọlọrun beere fun ninu ọ̀ràn ìmọ́tónítóní aláyẹyẹ.

Nigba ti Jesu kùnà lati kíyèsí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ naa, ẹnu ya olùgbàlejò rẹ̀. Àní bí ó tilẹ jẹ́ pe o ṣeeṣe ki o ma le sọ ìyàlẹ́nu rẹ jade, Jesu jádìí rẹ̀ tí ó sì wipe: “Nisinsinyi ẹyin Farisi, ẹ ńfọ òde aago ati àwokòtò mọ́, ṣugbọn inú yin kún fun ìpiyẹ́ ati ìwà burúkú. Ẹyin eniyan aláìlọ́gbọ́nnínú! Ẹni tí ó dá òde ó dá inú pẹlu, kò ha ṣe é bí?”

Jesu tipa bayii túdìí àṣírí àgàbàgebè awọn Farisi tí wọn ńwẹ ọwọ́ wọn lọna ààtò ṣíṣe ṣugbọn tí wọn kùnà lati wẹ ọkàn-àyà wọn kuro ninu ìwà burúkú. O gba wọn nímọ̀ràn pe: “Kí ẹyin kí ó kúkú maa ṣe ìtọrẹ àánú ninu ohun tí ẹyin ní; sì kíyèsí i, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fun yin.” Fífúnni wọn ni ọkan-aya onifẹẹ gbọdọ súnṣe, kii ṣe nipa ìfẹ́-ọkàn lati wù awọn miiran pẹlu ìdíbọ́n òdodo wọn.

“Ègbé ni fun ẹyin Farisi,” ni Jesu nbaa lọ, “nitori pe ẹ fúnni ní ìdámẹ́wàá ewéko minti ati rue ati olukuluku ewébẹ̀ miiran, ṣugbọn ẹyin gbójúfò ìdájọ́ òdodo ati ìfẹ́ Ọlọrun! Nǹkan wọnyi jẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe fun yin, ṣugbọn awọn ohun miiran wọnni kii ṣe gbígbójúfòdá.” Òfin Ọlọrun fun Isirẹli beere fun sísan ìdámẹ́wàá, tabi apá kẹwàá irè-oko lati inú awọn pápá. Ewéko minti ati rue jẹ́ awọn ewébẹ̀ tabi ewéko kéékèèké tí a ńlò ninu mímú ounjẹ ládùn. Awọn Farisi naa fi tìṣọ́tìṣọ́ra san ìpín kẹwàá àní awọn ewéko aláìjámọ́ pàtàkì wọnyi, ṣugbọn Jesu dá wọn lẹ́bi fun ṣíṣàìfiyèsí fifi ifẹ han, lati mu inurere lò, ati lati jẹ́ ẹlẹmii irẹlẹ, tí a beere fun tí ó ṣe pàtàkì jù.

Ní dídá wọn lẹ́bi siwaju sii, Jesu wipe: “Ègbé ni fun ẹyin Farisi, nitori pe ẹ nífẹ̀ẹ́ awọn ìjókòó iwájú ninu sinagọgu ati ìkíní ninu awọn ibi ọjà! Ègbé ni fun yin, nitori pe ẹ dabii awọn ibojì ìrántí wọnni tí kò farahàn tobẹẹ tí awọn eniyan ńrìn lórí wọn wọn kò sì mọ̀ ọ́n!” Ìwà àìmọ́ wọn kò hàn kedere. Ìsìn awọn Farisi ní ìfihàn òde ṣugbọn kò ní ìníyelori inú! A gbé e ka orí àgàbàgebè.

Ní fifetisilẹ sí irúfẹ́ ìdálẹ́bi bẹẹ, amòfin kan, ọ̀kan lára awọn wọnni tí wọn mọwámẹ̀hìn ninu Òfin Ọlọrun, ráhùn pe: “Olùkọ́ni, ní sísọ nǹkan wọnyi iwọ ńfi ìwọ̀sí kan wá pẹlu.”

Jesu mú awọn ògbógi ninu òfin wọnyi fun ìjíhìn pẹlu, ní wiwi pe: “Ègbé ni fun ẹyin pẹlu tí ẹ jáfáfá ninu Òfin, nitori pe ẹ di awọn ẹrù tí wọn ṣòro lati gbé ru awọn eniyan, ṣugbọn ẹyin fúnraayin kò fi ọ̀kan ninu awọn ìka-ọwọ́ yin kan awọn ẹrù naa! Ègbé ni fun yin, nitori pe ẹ ńkọ́ awọn ibojì iranti awọn wolii, ṣugbọn awọn babanla yin ni wọn pa wọn!”

Awọn ẹrù tí Jesu mẹ́nubà jẹ́ awọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ọlọ́rọ̀ ẹnu, ṣugbọn awọn amòfin wọnyi kì yoo mu kekere julọ ninu awọn ilana wọnyi kuro lati mú un rọrùn sí i fun awọn eniyan naa. Jesu ṣí i payá pe wọn tilẹ gbà lati ṣìkàpa awọn wolii, oun sì kìlọ̀ pe: “‘Kí a lè beere lọwọ ìran-ènìyàn yii ẹ̀jẹ̀ gbogbo awọn wolii tí a ti tasílẹ̀ lati ìgbà pípilẹ̀ ayé, lati ẹ̀jẹ̀ Ebẹli títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekaraya, ẹni tí a pa láàárín pẹpẹ ati ilé.’ Bẹẹni, mo sọ fun yin, a o beere lọwọ ìran-ènìyàn yii.”

Ayé aráyé tí ó ṣeé túnrà padà bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìbí awọn ọmọ lati ọwọ́ Adamu ati Efa; nipa bẹẹ, Ebẹli gbé ní “ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.” Tẹle ìṣìkàpànìyàn rírorò Sekaraya, agbo ọmọ ogun Siria fi Juda ṣèjẹ. Ṣugbọn Jesu sọtẹ́lẹ̀ ìfiṣèjẹ bíburù jù kan ti ìran-ènìyàn tirẹ̀ fúnraarẹ̀ nitori ìwà burúkú rẹ̀ títóbi jù. Ìfiṣèjẹ yii ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bii 38 ọdun lẹhin naa, ní 70 C.E.

Ní bíbá ìdálẹ́bi rẹ̀ nìṣó, Jesu wipe: “Ègbé ni fun ẹyin tí ẹ jáfáfá ninu Òfin, nitori pe ẹ mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ lọ; ẹyin fúnraayin kò wọlé, awọn wọnni tí wọn ńwọlé ni ẹ dílọ́wọ́!” Awọn ògbógi ninu Òfin ni ó ni ẹru iṣẹ lati ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fun awọn eniyan, ní ṣíṣí awọn ìtumọ̀ rẹ̀ sójútáyé. Ṣugbọn wọn kùnà lati ṣe eyi wọn sì gba àǹfààní lati lóye kuro lọwọ awọn eniyan naa pàápàá.

Awọn Farisi ati awọn ògbógi lọna òfin kún fun ìhónú sí Jesu fun títúdìí àṣírí wọn. Nigba ti ó fi ilé naa silẹ, wọn bẹrẹsii takò ó lọna rírorò tí wọn sì dá awọn ibeere bò ó. Wọn gbìyànjú lati mú un sọ ohun kan tí wọn fi lè fi àṣẹ ọba mú un. Luuku 11:37-54, NW; Deutaronomi 14:22; Mika 6:8; 2 Kironika 24:20-25.

▪ Eeṣe tí Jesu fi dá awọn Farisi ati awọn ògbógi ninu Òfin lẹ́bi?

▪ Ẹrù wo ni awọn amòfin gbé lé orí awọn eniyan naa?

▪ Nigba wo ni “ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé”?