Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹgbẹrun Lọna Iṣẹ́-ìyanu

Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹgbẹrun Lọna Iṣẹ́-ìyanu

Orí 52

Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹgbẹrun Lọna Iṣẹ́-ìyanu

AWỌN apọsiteli 12 ti gbádùn ìrìn àjò iwaasu kan tí ó pẹtẹrí jákèjádò Galili. Nisinsinyi, lẹhin ikú Johanu, wọn padà sọ́dọ̀ Jesu tí wọn sì ròhìn awọn ìrírí wọn yíyanilẹ́nu. Ní rírí i pe àárẹ̀ mú wọn ati pe ọpọlọpọ ènìyàn ni wọn ńwá tí wọn sì ńlọ tobẹẹ gẹ́ẹ́ tí wọn kò tilẹ ní àkókò lati jẹun, Jesu wipe: ‘Ẹ jẹ́ kí awa lọ kúrò ní awa nikan sí ibi ìdánìkanwà kan níbi tí ẹ ti lè sinmi.’

Ní wíwọ̀ inú ọkọ̀ ojú-omi wọn, boya nítòsí Kapanaomu, wọn forílé ibìkan tí ó bọ́sí kọ̀rọ̀, tí ó han gbangba pe o wà ní ìlà-oòrùn Jọdani ní ìkọjá Bẹtisaida. Ọpọlọpọ ènìyàn, bí ó ti wù kí ó rí, rí wọn nigba tí wọn ńlọ kúrò, awọn miiran sì mọ̀ nipa rẹ̀. Gbogbo awọn wọnyi sáré lọ ṣaaju gba etí èbúté, nigba ti ọkọ̀ naa gúnlẹ̀, awọn ènìyàn naa ti wà níbẹ̀ lati pade wọn.

Bí ó ti ńjáde kuro ninu ọkọ̀ tí ó sì rí ogunlọgọ naa, àánú ṣe Jesu nitori pe awọn ènìyàn naa dàbí awọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́-àgùtàn. Nitori naa ó mú awọn aláìsàn láradá tí ó sì bẹrẹsii kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan.

Kiakia ni àkókò kọjá lọ, awọn ọmọ-ẹhin Jesu sì tọ̀ ọ́ wá tí wọn sì wipe: “Àdádó ni ibí yii, wakati sì ti lọ tán nisinsinyi. Rán wọn lọ, kí wọn lè lọ sí àgbègbè ìgbèríko ati awọn abúlé yíkáàkiri kí wọn sì ra nǹkan fun araawọn lati jẹ.”

Bí ó ti wù kí ó rí, ní ifesipada Jesu wipe: “Ẹyin fun wọn ní nǹkan lati jẹ.” Lẹhin naa, niwọn bi Jesu ti mọ ohun tí oun yoo ṣe, ó dán Filipi wò nipa bibeere lọwọ rẹ̀ pe: “Nibo ni a o ti ra ìṣù burẹdi fun awọn wọnyi lati jẹ?”

Ní ojú ìwòye ti Filipi ọ̀ràn naa jẹ́ aláìṣeéṣe. Họ́wù, awọn ọkunrin tí ó wà níbẹ̀ jẹ́ nǹkan bíi 5,000, ati lọna tí ó ṣeeṣe daradara iye tí ó ju 10,000 awọn ènìyàn ní kíka awọn obinrin ati awọn ọmọde pẹlu! Filipi dáhùnpadà pe “awọn ìṣù burẹdi tí ìníyelórí wọn tó igba owó dinari [owó dinari kan nigba naa jẹ́ owó-ọ̀yà iṣẹ́ ọjọ́ kan] kò tó fun wọn, tí ẹnikọọkan fi lè rí iwọnba diẹ.”

Boya lati fi àìṣeéṣe bíbọ́ ọpọlọpọ bẹẹ hàn, Anderu dabaa pe: “Ọmọdekunrin kékeré kan wà níhìn-ín tí ó ní ìṣù burẹdi bali márùn-ún ati ẹja wẹ́wẹ́ meji,” tí ó sì fikun un pe, “ṣugbọn ki ni awọn wọnyi jámọ́ láàárín ọ̀pọ̀ ènìyàn bí eyi?”

Niwọn bi ó ti jẹ́ àkókò ìrúwé, kété ṣaaju Irekọja 32 C.E., ọ̀pọ̀ koríko tútùyọ̀yọ̀ ní nbẹ. Nitori naa Jesu jẹ́ kí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ sọ fun awọn ènìyàn naa lati rọ̀gbọ̀kú sórí koríko ní àwùjọ tí ó wà ní aadọta-aadọta ati ọgọọgọrun. Ó mú ìṣù burẹdi márùn-ún naa ati ẹja wẹ́wẹ́ meji, ó wò ọ̀run, ó sì súre. Nigba naa ni ó bẹrẹsii bu awọn ìṣù burẹdi naa tí ó sì ńpín awọn ẹja wẹ́wẹ́. Ó fi awọn wọnyi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ẹni tí, ẹ̀wẹ̀, pín wọn fun awọn ènìyàn naa. Lọna ti o ṣeni ni kàyéfì, gbogbo awọn ènìyàn naa jẹ títí wọn fi yó!

Lẹhin naa Jesu wí fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Ẹ kó awọn èbúbù tí ó ṣẹ́kù jọ pọ̀, kí a má fi ohunkohun ṣòfò.” Nigba ti wọn ṣe bẹẹ, wọn fi àjẹkù naa kún agbọ̀n 12 lati inu ohun tí wọn jẹ! Matiu 14:13-21; Maaku 6:30-44; Luuku 9:10-17; Johanu 6:1-13.

▪ Eeṣe tí Jesu fi ńwá ibi àdádó kiri fun awọn apọsiteli rẹ̀?

▪ Nibo ni Jesu mú awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ, eesitiṣe tí a kò fi mú àìní wọn fun ìsinmi ṣẹ?

▪ Nigba ti ọjọ́ ti lọ tán, ki ni awọn ọmọ-ẹhin naa ńrọni lati ṣe, ṣugbọn bawo ni Jesu ṣe tọ́jú awọn ènìyàn naa?