Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jesu Kọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ní Jẹriko

Jesu Kọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ní Jẹriko

Orí 99

Jesu Kọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ní Jẹriko

LÁÌPẸ́ Jesu ati awọn ogunlọgọ tí wọn ńrìnrìn àjò pẹlu rẹ̀ dé sí Jẹriko, ìlú kan tí ó jẹ́ nǹkan bii ìrìn àjò ọjọ́ kan sí Jerusalẹmu. Ó farahan bí ẹni pe Jẹriko jẹ́ ìlú meji, ìlú atijọ awọn Juu jẹ́ nǹkan bii ibùsọ̀ kan sí ìlú awọn ara Roomu ti o tubọ jẹ́ titun. Bí awọn ogunlọgọ naa ti ńjáde kuro ninu ìlú atijọ naa tí wọn sì ńsúnmọ́ eyi tí ó jẹ́ titun, awọn afọ́jú alágbe meji gbọ́ ìrúkèrúdò naa. Ọ̀kan ninu wọn njẹ Batimeu.

Nigba tí ó gbọ́ pe Jesu ni ó ńkọjá lọ, Batimeu ati alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ bẹrẹsii kígbe pe: “Oluwa, iwọ [“Ọmọkunrin,” NW] Dafidi, ṣàáánú fun wa!” Nigba ti ogunlọgọ naa jágbe mọ́ wọn pe kí wọn panumọ́, wọn tubọ kígbe jáde pẹlu ohùn rara sii: “Oluwa, iwọ [“Ọmọkunrin,” NW] Dafidi, ṣàáánú fun wa!”

Ní gbígbọ́ ìyọlẹ́nu naa, Jesu dúró. Ó sọ fun awọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pe kí wọn pe awọn ẹni tí ńkígbe naa wá. Awọn wọnyi lọ sọ́dọ̀ awọn afọ́jú alágbe naa wọn sì sọ fun ọ̀kan ninu wọn pe: “Tújúká, dìde; ó ńpè ọ.” Pẹlu ìrusókè ìmọ̀lára tí ó kọyọyọ, ọkunrin afọ́jú naa bọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ sọnù, ó fò dìde, ó sì lọ bá Jesu.

“Ki ni ẹyin ńfẹ́ kí emi kí ó ṣe fun yin?” ni Jesu beere.

“Oluwa, jẹ́ kí ojú wa là,” ni wọn jírẹ̀ẹ́bẹ̀.

Bí àánú ti ṣe é, Jesu fọwọ́kan ojú wọn. Gẹgẹ bi ìròhìn Maaku ti wí, Jesu sọ fun ọ̀kan ninu wọn pe: “Maa lọ; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.” Lójú ẹsẹ̀ awọn afọ́jú alágbe naa bẹrẹsii riran, láìsí iyèméjì awọn mejeeji sì bẹrẹsii fi ògo fun Ọlọrun. Nigba tí gbogbo awọn eniyan naa rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ, awọn pẹlu fi iyìn fun Ọlọrun. Láìjáfara, Batimeu ati alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ bẹrẹsii tẹle Jesu.

Bí Jesu ti ńla Jẹriko kọja, awọn ogunlọgọ naa tubọ npọ sii. Olukuluku eniyan ńfẹ́ lati rí ẹni naa tí ó mú awọn ọkunrin afọ́jú naa láradá. Awọn eniyan naa há Jesu mọ́ gádígádí ní gbogbo ìhà, ati gẹgẹ bi ìyọrísí eyi, awọn kan kò tilẹ lè kòfìrí rẹ̀. Lára awọn wọnyi ni Sakeu, olórí awọn agbowó-orí ninu ati ní ayika Jẹriko. Oun ti kúrú jù lati rí ohun tí ó ńlọ lọwọ.

Nitori naa Sakeu sáré síwájú ó sì gun igi ọ̀pọ̀tọ́ mulibẹri kan ní ojú ọna tí Jesu ńgbà kọja. Lati ibẹ, oun lè rí ohun gbogbo daradara. Bí awọn ogunlọgọ naa ti nsunmọtosi, Jesu kesi ẹni ti o wà lori igi naa pe: “Sakeu, yára, kí o sì sọ̀kalẹ̀, nitori emi kò lè ṣàìmá wọ̀ ní ilé rẹ lonii.” Sakeu sọ̀kalẹ̀ pẹlu inúdídùn ó sì yára lọ sí ilé lati pèsè awọn nǹkan silẹ fun olùbẹ̀wò rẹ̀ títayọ.

Ṣugbọn nigba ti awọn eniyan rí ohun tí ó ńṣẹlẹ̀, gbogbo wọn bẹrẹsii ráhùn. Wọn kà á sí ohun tí kò tọ̀nà fun Jesu lati jẹ́ àlejò irúfẹ́ ọkunrin bẹẹ. Ṣe o ríi, Sakeu di ọlọ́rọ̀ nipasẹ ìlọ́nilọ́wọ́gbà lọna àbòsí ninu iṣẹ́ owó-orí gbígbà rẹ̀.

Ọpọlọpọ eniyan tẹle e, nigba ti Jesu sì wọlé sínú ilé Sakeu, wọn ráhún pe: “Ó lọ wọ̀ lọ́dọ̀ ọkunrin tíí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀.” Sibẹsibẹ Jesu rí ṣiṣeeṣe naa fun ìrònúpìwàdà ninu Sakeu. Jesu ni a kò sì jákulẹ̀, nitori pe Sakeu dìde dúró ó sì ṣèfilọ̀ pe: “Wòó, Oluwa, ìdajì ohun ìní mi ni emi yoo fifún awọn òtòṣì, ohun yoowu tí mo bá sì fi agbára gbà lọwọ ẹnikẹni nipa ẹ̀sùn èké, emi yoo san án padà ní ìlọ́po mẹrin.”

Sakeu fi ẹ̀rí hàn pe ìrònúpìwàdà oun jẹ́ ojúlówó nipa fífi ìdajì awọn ohun ìní rẹ̀ fun awọn òtòṣì ati nipa lílò ìdajì tí ó ṣẹ́kù lati ṣe ìsanpadà fun awọn wọnni tí oun ti rẹ́jẹ. Ó hàn gbangba pe oun lè ṣírò eyi lati inú awọn akọsilẹ owó-orí rẹ̀ lati mọ̀ iye tí oun jẹ awọn eniyan wọnyi gẹ́lẹ́. Nitori naa oun jẹ́jẹ̀ẹ́ ìmúpadà bọ̀sípò onílọ̀ọ́po mẹ́rin ní ìbámu pẹlu òfin Ọlọrun tí ó sọ pe: ‘Bí ọkunrin kan bá jí àgùtàn kan, yoo san àgùtàn mẹrin dípò àgùtàn kan naa.’

Inú Jesu dùn sí bí Sakeu ti ṣèlérí lati pín awọn ohun ìní rẹ̀, nitori Ó ṣe sáàfúlà pe: “Ni òní yii ìgbàlà ti dé sinu ilé yii, nitori oun pẹlu jẹ́ ọmọkunrin Aburahamu. Nitori Ọmọkunrin eniyan wá lati wákiri ati lati gbà ohun tí ó sọnù là.”

Ní lọwọlọwọ yii, Jesu ti ṣàkàwé ipò ‘awọn tí wọn ti sọnù’ pẹlu ìtàn rẹ̀ nipa ọmọkunrin oninàákúnàá naa. Nisinsinyi awa ní apẹẹrẹ igbesi-aye tootọ gidi nipa ẹnikan tí ó ti sọnù tí a sì ti rí. Àní bí ó tilẹ jẹ́ pe awọn aṣaaju isin ati awọn wọnni tí wọn tẹle wọn sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tí wọn sì ráhùn nipa àfiyèsí Jesu fun awọn eniyan bii Sakeu, Jesu nbaa lọ lati maa wá awọn ọmọkunrin Aburahamu tí wọn sọnù wọnyi kiri kí ó sì mú wọn padàbọ̀sípò. Matiu 20:29-34; Maaku 10:46-52; Luuku 18:35–19:10; Ẹkisodu 22:1.

▪ Bí ó ti hàn gbangba kedere nibo ni Jesu ti padé awọn afọ́jú alágbe naa, ki ni ohun tí ó sì ṣe fun wọn?

▪ Ta ni Sakeu, eesitiṣe tí ó fi gun igi kan?

▪ Bawo ni Sakeu ṣe fi ẹ̀rí ìrònúpìwàdà rẹ̀ hàn?

▪ Ẹ̀kọ́ wo ni awa lè kọ́ lati inú ìhùwàsí Jesu sí Sakeu?