Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jesu Lé Ẹ̀dùn Ọkàn Opó kan Lọ

Jesu Lé Ẹ̀dùn Ọkàn Opó kan Lọ

Orí 37

Jesu Lé Ẹ̀dùn Ọkàn Opó kan Lọ

LÁÌPẸ́ lẹhin tí ó ti mú iranṣẹ ọ̀gágun naa láradá, Jesu gbéra lati lọ sí Naini, ìlú-ńlá kan tí ó ju 20 ibùsọ̀ sí gúúsú ìwọ̀-oòrùn Kapanaomu. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ati ogunlọgọ nla kan nbaa lọ. Àfàìmọ̀ ki o ma jẹ ni ọwọ́ alẹ́ ni wọn sunmọ ìgbèríko Naini. Níhìn-ín ni wọn ti pàdé ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ńtò lọ́wọ̀ọ̀wọ́rìn fun ìsìnkú kan. Òkú ọkunrin ọ̀dọ́ kan ni wọn ńgbé jáde kuro ní ìlú-ńlá naa lati lọ sin.

Ipò iya naa tubọ banininujẹ pàápàá ní pàtàkì, niwọn bi oun ti jẹ́ opó tí eyi sì jẹ́ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo. Nigba ti ọkọ rẹ̀ kú, oun lè rí ìtùnú ninu otitọ naa pe oun ní ọmọkunrin kan. Awọn ireti rẹ̀, ìfẹ́-ọkàn rẹ̀, ati awọn ìlépa àṣeyọrí rẹ̀ ni o wépọ̀ mọ́ ọjọ́ ọ̀la ọmọkunrin rẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyi kò sí ẹnikẹni mọ́ ti o lè pese itunu fun un. Ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ ga pupọ bí awọn ara ìlú naa ti nbaa lọ sí ibi ìsìnkú.

Nigba ti Jesu tajú kán ti o sì ri obinrin naa, a gún ọkàn-àyà rẹ̀ ní kẹ́sẹ́ nipasẹ ìbànújẹ́ obinrin naa tí ó lékenkà. Nitori naa lọna pẹ̀lẹ́tù, ati sibẹ pẹlu ìfìdímúlẹ̀gbọnyin tí ńfúnni ní ìgbọ́kànlé, o wí fun obinrin naa pe: “Dẹ́kun ẹkún sísun.” Ọ̀nà ìṣarasíhùwà ati ìṣe rẹ̀ fa àfíyèsí ogunlọgọ naa mọ́ra. Nitori naa nigba ti ó sunmọ ohun tí a fi ńgbé òkú naa lọ tí ó sì fọwọ́kàn án, awọn tí ó gbé e dúró jẹ́ ẹ́. Kayefi ti nilati ṣe gbogbo wọn si ohun tí oun fẹ́ ṣe.

Otitọ ni pe awọn tí wọn ńbá Jesu rin ti ríi tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá kuro lọwọ awọn àrùn lọna iṣẹ́ ìyanu. Ṣugbọn ó hàn gbangba pe wọn kò tíì rí i kí ó jí ẹnikẹni dìde kuro ninu òkú rí. Oun ha lè ṣe bẹẹ bí? Ní dídarí ọ̀rọ̀ sí òkú naa, Jesu pàṣẹ pe: “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fun ọ, Dìde!” Ọkunrin naa sì dìde jókòó! Ó bẹrẹsii sọ̀rọ̀, Jesu sì fà á lé iya rẹ̀ lọwọ.

Nigba ti awọn ènìyàn naa ríi pe ọ̀dọ́mọkùnrin naa ti walaaye nitootọ, wọn bẹrẹsii sọ pe: “Wolii ńlá kan ni a ti gbé dìde láàárín wa.” Awọn miiran wipe: “Ọlọrun ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí awọn ènìyàn rẹ̀.” Ní kiakia ni ìròhìn nipa iṣẹ́ àrà àgbàyanu yii tàn kaakiri gbogbo Judia ati gbogbo ìgbèríko tí ó yí i ká.

Johanu Arinibọmi ṣì wà lẹ́wọ̀n sibẹ, oun sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ pupọ sí i nipa awọn iṣẹ́ tí Jesu lè ṣe. Awọn ọmọ-ẹhin Johanu ròhìn fun un nipa awọn iṣẹ́ ìyanu wọnyi. Ki ni ìdáhùnpadà rẹ̀? Luuku 7:11-18.

▪ Ki ni ohun tí ó ńṣẹlẹ̀ bí Jesu ti ńsúnmọ́ Naini?

▪ Bawo ni ohun tí Jesu rí ṣe nípa lórí rẹ̀, kí sì ni ohun tí oun ṣe?

▪ Bawo ni awọn ènìyàn naa ṣe dáhùnpadà sí iṣẹ́ ìyanu Jesu?