Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jesu Pari Gbogbo Ohun Ti Ọlọrun Beere Fun

Jesu Pari Gbogbo Ohun Ti Ọlọrun Beere Fun

Orí 133

Jesu Pari Gbogbo Ohun Ti Ọlọrun Beere Fun

NIGBA ti Ọba Ajagun naa Jesu Kristi ba mu Satani ati aye alaiṣootọ rẹ kuro, iru idi fun idunnu wo ni yoo wa! Akoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun alalaafia ti Jesu bẹrẹ nígbẹ̀hìn gbẹ́hín!

Labẹ idari Jesu ati awọn alajumọ jẹ́ ọba pẹlu rẹ̀, awọn olula Amagẹdọn ja yoo palẹ awọn awoku ti a ti fi silẹ nipasẹ ogun ododo naa mọ́. O ṣeeṣe pe, awọn olulaaja lori ilẹ-aye yoo bi awọn ọmọ fun akoko kan, awọn wọnyi yoo si ṣalabaapin ninu iṣẹ onidunnu ti sisọ ilẹ-aye di ọgba itura ẹlẹwa jingbinni kan.

Bi akoko ti nlọ Jesu yoo mu araadọta ọkẹ ti a ko le sọ iye rẹ jade kuro ninu iboji wọn lati gbadun Paradise ẹlẹwa yii. Yoo ṣe eyi ni imuṣẹ ẹri didaju tirẹ funraarẹ pe: “Wakati nbọ, ninu eyi ti gbogbo awọn ti o wa ni isa oku yoo . . . jade wa.”

Lara awọn ti Jesu ji dide yoo jẹ oluṣe buburu tẹlẹri ti o ku lẹgbẹẹ rẹ lori opo-igi idaloro. Ranti pe Jesu ṣeleri fun un pe: “Lootọ ni mo wi fun ọ lonii, Iwọ yoo wa pẹlu mi ni Paradise.” Bẹẹkọ, ọkunrin yẹn ni a ki yoo mu lọ si ọrun lati ṣakoso gẹgẹ bi ọba pẹlu Jesu, bẹẹ ni Jesu ki yoo di eniyan lẹẹkan sii ki o si maa gbe lori Paradise ilẹ-aye pẹlu rẹ̀. Kaka bẹẹ, Jesu yoo wa pẹlu oluṣe buburu tẹlẹri yii ni itumọ ti pe oun yoo jí i dide si iye ninu Paradise ti yoo si ri sii pe awọn aini rẹ̀, nipa ti ara ati tẹmi, ni a bojuto, gẹgẹ bi a ti ṣapejuwe ni oju-iwe ti o tẹle e.

Ronu nipa rẹ ná! Labẹ afiyesi onifẹẹ ti Jesu, gbogbo idile eniyan—awọn olula Amagẹdọn ja, awọn ọmọ wọn, ati ẹgbẹẹgbẹrun araadọta ọkẹ awọn oku ti a ji dide ti o ṣegbọran si i—yoo dagba si ìjẹ́pipe eniyan. Jehofa, nipasẹ Ọmọkunrin rẹ ọba, Jesu Kristi, yoo maa gbe nipa tẹmi pẹlu iran eniyan. Gẹgẹ bi ohùn ti Johanu gbọ lati ọrun wá ti wipe, “Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; ki yoo si si iku mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkun, bẹẹ ni ki yoo si irora mọ.” Ko si ẹnikan lori ilẹ-aye ti yoo jiya tabi ti yoo ṣaisan.

Nigba ti o ba fi maa di ipari Akoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti Jesu, ipo naa yoo rí gan-an gẹgẹ bi Ọlọrun ti pete ni ipilẹṣẹ nigba ti o sọ fun tọkọtaya akọkọ, Adamu ati Efa, lati bisii ki wọn si kun ilẹ-aye. Bẹẹni, aye yoo kún fun iran olododo awọn eniyan pipe. Eyi jẹ nitori pe anfaani ẹbọ irapada Jesu ni a o ti fisilo fun gbogbo eniyan. Iku nitori ẹṣẹ Adamu ki yoo si mọ!

Nipa bayii, Jesu yoo ti ṣaṣepari gbogbo ohun ti Jehofa beere lọwọ rẹ. Nitori naa, ni opin ẹgbẹrun ọdun naa, oun yoo gbé Ijọba naa ati idile eniyan ti a ti mu de ijẹpipe pada fun Baba rẹ. Ọlọrun nigba naa yoo tu Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ silẹ lati inu ọgbun ti o dabi ipo iku tí kò ti lè ṣe ohunkohun. Fun ete wo ni?

O dara, ni igba opin ẹgbẹrun ọdun naa, eyi ti o pọ julọ ninu awọn ti wọn wa ninu Paradise yoo jẹ awọn ẹni ti a jí dide ti a ko tii dan igbagbọ wọn wò ri. Ṣaaju kí wọn tó ku, wọn ko tii figba kan ri mọ awọn ileri Ọlọrun nitori naa wọn ko le fi igbagbọ hàn ninu wọn. Nigba naa, lẹhin ti a ti ji wọn dide ti a si ti kọ́ wọn lẹkọọ otitọ Bibeli, o rọrun fun wọn ninu Paradise, laisi atako eyikeyii, lati ṣiṣẹsin Ọlọrun. Ṣugbọn bi a ba fun Satani ni anfaani lati gbiyanju lati dá wọn duro ni bibaa lọ lati ṣiṣẹsin Ọlọrun, wọn yoo ha fi araawọn han gẹgẹ bi aduroṣinṣin labẹ idanwo bi? Lati yanju ibeere yii, Satani ni a o tu silẹ.

Iṣipaya ti a fun Johanu fihan pe lẹhin Akoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti Jesu, Satani yoo ṣaṣeyọri si rere ni yiyi iye awọn eniyan ti a ko mọ iye wọn pada kuro ninu ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun. Ṣugbọn lẹhin naa nigba ti idanwo ikẹhin naa ba ti pari, Satani, awọn ẹmi eṣu rẹ, ati gbogbo awọn wọnni ti oun ṣaṣeyọri ni ṣíṣì lọna ni a o parun titi lae. Ni ọwọ keji ẹwẹ, awọn ti a ti danwo ni kikun, awọn olulaaja aduroṣinṣin yoo wà laaye niṣo lati gbadun awọn ibukun Baba wọn ọrun titi ayeraye.

Ni kedere, Jesu ti kó ipa ṣiṣekoko, ti yoo si maa baa lọ lati maa ṣe bẹẹ ni ṣiṣaṣepari awọn ete ologo Ọlọrun. Iru ọjọ ọla titobilọla wo ni awa le gbadun gẹgẹ bi iyọrisi gbogbo ohun ti oun ti ṣaṣepari rẹ gẹgẹ bi Ọba nla ọrun ti Ọlọrun. Sibẹsibẹ, awa ko le gbagbe gbogbo ohun ti oun ti ṣe nigba ti o jẹ eniyan.

Jesu fi tifẹtifẹ yọnda lati wa sori ilẹ-aye ó si kọ́ wa lẹkọọ nipa Baba rẹ. Rekọja eyi oun fi apẹẹrẹ awọn animọ oniyebiye Ọlọrun lelẹ. Ọkan-aya wa ni a sun nigba ti a ba ronu nipa igboya ati aiṣojo rẹ̀ gigalọla, ọgbọn rẹ alailafiwe, itootun gigadabu rẹ gẹgẹ bi olukọ, ipo aṣiwaju alaibẹru rẹ, ìyọ́nú onijẹlẹnkẹ ati igbatẹniro rẹ. Nigba ti a ba ranti bi oun ṣe jiya laiṣeefẹnusọ bi oun ṣe npese irapada naa, nipasẹ ọna kanṣoṣo ti a le gba jere iwalaaye, dajudaju ọkan-aya wa ni a sun pẹlu imọriri fun un!

Nitootọ, ẹ wo iru ọkunrin naa ti a ti ri ninu ikẹkọọ igbesi-aye Jesu yii! Itobilọla rẹ ṣe kedere ó si bonimọlẹ. Awa ni a sun lati ṣe gbohungbohun awọn ọrọ gomina Roomu naa Pọntu Pilatu pe: “Ẹ wòó! Ọkunrin naa!” Bẹẹni, nitootọ, “Ọkunrin naa,” ọkunrin titobilọla julọ ti o tii gbé ayé rí!

Nipa titẹwọgba ipese ẹbọ irapada rẹ, ẹru ẹṣẹ ati iku ti a jogun lati ọdọ Adamu ni a le mu kuro lọdọ wa, Jesu si le di “Baba Ayeraye” fun wa. Gbogbo awọn ti yoo jere iye ayeraye gbọdọ gba imọ kii ṣe kiki nipa Ọlọrun ṣugbọn bakan naa nipa Ọmọkunrin rẹ, Jesu Kristi. Njẹ ki kika ati kikẹkọọ iwe yii ran ọ lọwọ lati gba iru imọ ti nfunni ni iwalaaye bẹẹ sinu! 1 Johanu 2:17; 1:7; Johanu 5:28, 29; 3:16; 17:3; 19:5; Luuku 23:43; Jẹnẹsisi 1:28; 1 Kọrinti 15:24-28; Iṣipaya 20:1-3, 6-10; 21:3, 4; Aisaya 9:6.

▪ Ki ni yoo jẹ anfaani alayọ awọn olula Amagẹdọn ja ati awọn ọmọ wọn?

▪ Awọn wo ni yoo gbadun Paradise ni afikun si awọn olula Amagẹdọn ja ati awọn ọmọ wọn, ni itumọ wo si ni Jesu yoo fi wa pẹlu wọn?

▪ Ki ni yoo jẹ ipo naa ni opin ẹgbẹrun ọdun, ki ni Jesu yoo sì ṣe nigba naa?

▪ Eeṣe ti a o fi tu Satani silẹ kuro ninu ọgbun naa, ki ni yoo si ṣẹlẹ nígbẹ̀hìn gbẹ́hín si oun ati gbogbo awọn ti o tẹle e?

▪ Bawo ni Jesu ṣe le di “Baba Ayeraye” fun wa?