Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jesu Rán 70 naa Jáde

Jesu Rán 70 naa Jáde

Orí 72

Jesu Rán 70 naa Jáde

ÓJẸ́ ìgbà ìwọ́wé 32 C.E., ọdun mẹta gbákó lati ìgbà ìrìbọmi Jesu. Oun ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ sí Àjọ-àríyá Awọn Àgọ́-ìsìn ní Jerusalẹmu, ati ni kedere wọn ṣì wà nítòsí. Niti tootọ, Jesu lò eyi tí ó pọ̀ julọ ninu oṣu mẹfa ti o ṣẹku fun iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ yálà ní Judia tabi ní ìsọdá Odò Jọdani gẹ́lẹ́ ní àgbègbè Peria. Ọ̀ranyàn ni lati kárí àgbègbè yii pẹlu.

Lóòótọ́, lẹhin Irekọja 30 C.E., Jesu lo nǹkan bíi oṣu mẹjọ ní wiwaasu ní Judia. Ṣugbọn lẹhin ìgbà tí awọn Juu gbìyànjú lati pa á nibẹ ní Irekọja ti 31 C.E., ó lò ọdun kan aabọ tí ó tẹle e ní wiwaasu ní ohun tí ó fẹrẹẹ jẹ́ ni Galili nikanṣoṣo. Láàárín àkókò yẹn, ó mú ètò-àjọ awọn oniwaasu títóbi, tí a ti dálẹ́kọ̀ọ́ dáadáa kan dàgbà, ohun kan tí oun kò ní ní ìbẹ̀rẹ̀. Nitori naa oun nisinsinyi bẹ̀rẹ̀ ìgbétásì iwaasu ikẹhin gbígbónájanjan ní Judia.

Jesu mú ìgbétásì rẹ̀ tẹsiwaju nipa yíyàn 70 awọn ọmọ-ẹhin tí ó sì rán wọn jáde lọ ní meji meji. Nipa bẹẹ, awọn 35 ọ̀wọ́ oniwaasu Ijọba ni ó wà lápapọ̀ lati ṣiṣẹ́ àgbègbè naa. Awọn wọnyi ńlọ ṣaaju sínú gbogbo ìlú ati ibi tí Jesu, ẹni tí awọn apọsiteli yoo ba kẹ́gbẹ́rìn lọna híhàn gbangba, ńwéwèé lati lọ.

Dípò kí ó darí awọn 70 naa lọ sínú awọn sinagọgu, Jesu sọ fun wọn lati wọ awọn ilé àdáni, ní ṣíṣàlàyé pe: “Ní ilékílé tí ẹyin bá wọ̀, ẹ kọ wipe, Alaafia fun ilé yii. Bí ọmọ alaafia bá sì nbẹ nibẹ, alaafia yin yoo bà lé e.” Ki ni yoo jẹ́ ìhìn-iṣẹ́ wọn? “Ẹ wí fun wọn pe,” ni Jesu wí, “ijọba Ọlọrun ti sunmọtosi.” Nipa ìgbòkègbodò awọn 70 naa, Matthew Henry’s Commentary ròhìn pe: “Gẹgẹ bi Ọ̀gá wọn, ibikíbi tí wọn bá bẹ̀wò, wọn nwaasu lati ilé dé ilé.”

Awọn ìtọ́ni tí Jesu fun awọn 70 naa farajọra pẹlu awọn wọnni tí ó fifún awọn 12 nigba ti ó ńrán awọn wọnyi jáde lọ lórí ìgbétásì iwaasu kan ní Galili ní nǹkan bii ọdun kan ṣaaju. Kii ṣe kìkì pe ó kìlọ̀ fun awọn 70 naa nipa àtakò tí wọn yoo dojúkọ, ní mímúra wọn silẹ lati gbé ìhìn-iṣẹ́ wọn kalẹ̀ fun awọn onile, ṣugbọn ó fun wọn lágbára lati wo awọn aláìsàn sàn. Nipa bẹẹ, nigba ti Jesu bá dé ní kété lẹhin naa, ọpọlọpọ ni yoo háragàgà lati pade Ọ̀gá naa ẹni tí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti ṣe irúfẹ́ awọn ohun yíyanilẹ́nu bẹẹ.

Iwaasu tí awọn 70 naa ṣe ati iṣẹ́ àṣekún Jesu gba àkókò kúkúrú kan ní ìfiwéra. Láìpẹ́ awọn 35 ọ̀wọ́ oniwaasu Ijọba naa bẹrẹsii padà lọ sọ́dọ̀ Jesu. “Oluwa,” ni wọn sọ pẹlu ayọ̀, “awọn ẹ̀mí eṣu tilẹ foríbalẹ̀ fun wa ní orukọ rẹ.” Irúfẹ́ ìròhìn iṣẹ́-ìsìn rere kan bẹẹ mú ìmọ̀lára Jesu rusókè dajudaju, nitori ó dáhùnpadà pe: “Emi rí Satani ṣubú bíi mànàmáná lati ọ̀run wá. Kíyèsí i, emi fun yin ní àṣẹ lati tẹ ejò ati àkèéke mọ́lẹ̀.”

Jesu mọ̀ pe lẹhin ìbí Ijọba Ọlọrun ní àkókò òpin, Satani ati awọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ ni a o lé síta kuro ní ọ̀run. Ṣugbọn nisinsinyi ìlésíta awọn ẹ̀mí-èṣù àìrí yii lati ọwọ́ awọn ẹ̀dá-ènìyàn lásánlàsàn ṣiṣẹ́ gẹgẹ bi àfikún ìdánilójú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ńbọ̀ yẹn. Nitori naa, Jesu sọ̀rọ̀ nipa ìṣubú Satani lọjọ iwaju lati ọ̀run gẹgẹ bi ohun kan tí ó dájú. Nitori bẹẹ, ó jẹ́ ní ọna ìfàmìṣàpẹẹrẹ kan ni a fifún awọn 70 naa ní àṣẹ lati tẹ awọn ejò nla ati awọn àkèéke mọlẹ. Sibẹ, Jesu wipe: “Ẹ maṣe yọ̀ sí eyi, pe awọn ẹ̀mí foríbalẹ̀ fun yin, ṣugbọn ẹ kúkú yọ̀, pe, a kọ̀wé orukọ yin ní ọ̀run.”

Jesu yọ gidigidi ó sì yin Baba rẹ̀ ní gbangba fun lílò awọn iranṣẹ rírẹlẹ̀ wọnyi ní irúfẹ́ ọ̀nà alágbára kan bẹẹ. Ní yíyíjúsí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ó wipe: “Ibukun ni fun ojú tí ó rí ohun tí ẹyin rí: nitori mo wí fun yin, wolii ati ọba pupọ ni ó fẹ́ lati rí ohun tí ẹyin rí, wọn kò sì rí wọn, ati lati gbọ́ ohun tí ẹyin gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.” Luuku 10:1-24; Matiu 10:1-42; Iṣipaya 12:7-12.

▪ Nibo ni Jesu ti waasu láàárín ọdun mẹta àkọ́kọ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀, àgbègbè wo ni ó sì kárí ní oṣu mẹfa rẹ̀ tí ó kẹhin?

▪ Nibo ni Jesu darí awọn 70 naa sí lati wá awọn eniyan rí?

▪ Eeṣe tí Jesu fi sọ pe oun rí Satani tí ó ti ṣubú ná lati ọ̀run?

▪ Ní ọna wo ni awọn 70 naa fi lè tẹ awọn ejò ati awọn àkèéke mọ́lẹ̀?