Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jesu ati Awọn Aworawọ

Jesu ati Awọn Aworawọ

Orí 7

Jesu ati Awọn Aworawọ

AWỌN ọkunrin kan wá lati Ila-oorun. Wọn jẹ́ awọn aworawọ—awọn eniyan ti wọn sọ pe awọn lè tumọ ipo awọn irawọ. Nigba ti wọn ṣì wà nile ni Ila oorun, wọn rí irawọ titun kan, wọn sì tẹle e fun ọgọrọọrun ibusọ titi dé Jerusalẹmu.

Nigba ti awọn aworawọ naa dé sí Jerusalẹmu, wọn beere pe: “Nibo ni ẹni ti a bí ti nṣe ọba awọn Juu wà? nitori awa ti rí irawọ rẹ̀ ni ila-oorun, awa sì wá lati foribalẹ fun un.”

Nigba ti Ọba Hẹrọdu ni Jerusalẹmu gbọ́ nipa eyi, inu bí i gidigidi. Nitori naa o késí awọn olori alufaa o sì beere ibi ti a o bi Kristi naa sí. Ni gbigbe idahun wọn ka ori Iwe Mimọ, wọn dahun pe: “Ni Bẹtilẹhẹmu.” Nigba naa, Hẹrọdu jẹ́ kí a mu awọn aworawọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì wi fun wọn pe: “Ẹ lọ wadii ti ọmọ ọwọ naa lẹ́sọ̀lẹsọ̀; nigba ti ẹyin ba sì rí i, ẹ pada wá sọ fun mi, ki emi ki o lè wá foribalẹ fun un pẹlu.” Ṣugbọn, niti gidi, Hẹrọdu fẹ́ lati wá ọmọ naa rí kí ó sì pa á!

Lẹhin igba ti wọn fi ibẹ silẹ, ohun iyalẹnu kan ṣẹlẹ. Ìràwọ̀ naa tí wọn ti ri nigba ti wọn wà ní Ila-oorun nlọ niwaju wọn. Ni kedere, eyi kii ṣe irawọ lasan, ṣugbọn a ti pese rẹ̀ lọna akanṣe lati tọ́ wọn sọna. Awọn aworawọ naa ntẹle e lọ titi o fi dúró lori ile naa nibi ti Josẹfu ati Maria wà.

Nigba ti awọn aworawọ naa wọ inu ilé, wọn rí Maria pẹlu ọmọ rẹ̀ kekere naa, Jesu. Nigba naa ni gbogbo wọn foribalẹ fun un. Wọn sì mú awọn ẹ̀bùn wura, turari, ati òjíá jade ninu awọn àpò wọn. Lẹhin eyiini, nigba ti wọn fẹ́ pada lọ lati lọ sọ fun Hẹrọdu nipa ibi ti ọmọ naa wà, a kilọ fun wọn lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun loju àlá lati maṣe ṣe bẹẹ. Nitori naa wọn pada si ilẹ wọn nipasẹ ọna miiran.

Ta ni iwọ rò pe o pese irawọ naa ti o rìn ni ojú ọrun lati ṣamọna awọn aworawọ naa? Ranti pe irawọ naa kò ṣamọna wọn ní taarata lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu ni Bẹtilẹhẹmu. Kaka bẹẹ, o dari wọn lọ sí Jerusalẹmu nibi ti wọn ti ṣalabaapade ọba Hẹrọdu, ẹni ti o nfẹ lati pa Jesu. Oun ìbá sì ti ṣe bẹẹ bí Ọlọrun kò bá ti dá sí ọran naa kí ó sì kilọ fun awọn aworawọ naa lati maṣe sọ fun Hẹrọdu ibi ti Jesu wà. Ọta Ọlọrun ni, Satani Eṣu, ẹni ti o nfẹ ki a pa Jesu, oun sì lo irawọ naa lati gbiyanju lati mú ète rẹ̀ ṣẹ. Matiu 2:1-12; Mika 5:2.

▪ Ki ni o fihan pe irawọ ti awọn aworawọ naa rí kii ṣe irawọ lasan?

▪ Nibo ni Jesu wà nigba ti awọn aworawọ naa rí i?

▪ Eeṣe ti a fi mọ̀ pe Satani ni o pese irawọ naa lati ṣamọna awọn aworawọ naa?