Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kíkọ́ Obinrin Ara Samaria Kan Lẹkọọ

Kíkọ́ Obinrin Ara Samaria Kan Lẹkọọ

Orí 19

Kíkọ́ Obinrin Ara Samaria Kan Lẹkọọ

BI WỌN ti nlọ lati Judia si Galili, Jesu ati awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ rin irin ajo la aarin agbegbe Samaria kọja. Bí àárẹ̀ ti mú wọn nitori irin ajo naa, ni nǹkan bii ọjọ́kanrí wọn duro lati sinmi lẹbaa kanga kan nitosi ilu Sika. Kanga yii ni Jakọbu ti gbẹ́ ni ọ̀pọ̀ ọgọrun-un ọdun ṣaaju, ó sì wà ani titi di oni, nitosi ilu Nablus ti òde òní.

Nigba ti Jesu nsinmi nihin-in, awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ lọ sinu ilu naa lati ra ounjẹ. Nigba ti obinrin ara Samaria kan wá lati fa omi, Jesu beere pe: “Fun mi mu.”

Awọn Juu ati awọn ara Samaria ni gbogbogboo kò saba maa nni ibalo kankan pẹlu araawọn nitori awọn ẹtanu jijinlẹ. Nitori naa, pẹlu iyalẹnu, obinrin naa beere pe: “Èétirí ti iwọ ti nṣe Juu, fi nbeere omi mimu lọwọ mi, emi ẹni ti nṣe obinrin ara Samaria?”

“Ibaṣepe iwọ mọ,” ni Jesu dahun, “ẹni ti o wi fun ọ pe, Fun mi mu, iwọ ìbá sì ti beere lọwọ rẹ̀, oun ìbá ti fi omi ìyè fun ọ.”

“Ọgbẹni,” ni obinrin naa fesipada, “iwọ kò ní nǹkan ti iwọ yoo fi fa omi, bẹẹ ni kanga naa jìn: nibo ni iwọ gbé ti ri omi ìyè naa? Iwọ pọ̀ ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹni ti o fun wa ni kanga naa, ti oun tìkáraarẹ̀ mu ninu rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ẹranko rẹ̀?”

“Ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi yii, oungbẹ yoo sì tún gbẹ ẹ́,” ni Jesu sọ. “Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi yoo fifun un, oungbẹ kì yoo gbẹ ẹ́ mọ́ lae; ṣugbọn omi ti emi yoo fifun un yoo di kanga omi ninu rẹ̀, ti yoo maa sun sí iye ainipẹkun.”

“Ọgbẹni, fun mi ni omi yii, ki oungbẹ ki o maṣe gbẹ mi, ki emi kí ó má sì wá fa omi nihin-in,” ni obinrin naa dahunpada.

Jesu wá sọ fun un nisinsinyi pe: “Lọ pe ọkọ rẹ ki o sì wá sihin-in.”

“Emi kò ní ọkọ,” ni obinrin naa dahun.

Jesu jẹrii sí gbolohun ọrọ obinrin naa. “Iwọ wí rere pe, Emi kò ní ọkọ: nitori iwọ ti ni ọkọ marun-un rí; ẹni ti iwọ sì ní nisinsinyi kii ṣe ọkọ rẹ.”

“Ọgbẹni, mo woye pe, wolii ni iwọ nṣe,” ni obinrin naa sọ pẹlu kayefi. Ni ṣiṣipaya ìfẹ́ rẹ̀ fun awọn nǹkan tẹmi, oun ṣakiyesi pe awọn ara Samaria “nsin lori oke yii [Gerisiimu, ti o wà nitosi]; ẹyin [Juu] wipe, Jerusalẹmu ni ibi ti o yẹ ti a ba maa sìn.”

Sibẹ, ibi ijọsin kọ́ ni ohun ti o ṣe pataki, ni Jesu pe afiyesi sí. “Wakati nbọ,” ni oun wi, “nigba ti awọn olusin tootọ yoo maa sin Baba ni ẹ̀mí ati ni otitọ: nitori iru wọn ni Baba nwa ki o maa sin oun. Ẹmi ni Ọlọrun: awọn ẹni ti nsin in kò lè ṣe alaisin in ni ẹmi ati ni otitọ.”

Obinrin naa ni ọ̀rọ̀ naa wọ̀ lọ́kàn ṣinṣin. “Mo mọ̀ pe Mesaya nbọ wá, ti a npe ni Kristi,” ni oun wí. “Nigba ti oun bá dé, yoo sọ ohun gbogbo fun wa.”

“Emi ẹni ti o nba ọ sọrọ yii ni oun,” ni Jesu kede. Rò ó wò ná! Obinrin yii ti o wá ni ọjọ́kanrí lati fa omi, boya ki o lè yẹra fun ṣiṣe alabaapade awọn obinrin ilu ti wọn nkẹgan rẹ̀ fun ọna igbesi aye rẹ̀, ni Jesu ṣe ojurere sí lọna agbayanu. Ṣàkó ni oun sọ fun obinrin naa ohun ti oun kò tii jẹwọ ni gbangba fun ẹnikẹni miiran. Pẹlu awọn abajade wo sì ni?

Ọpọ Awọn Ara Samaria Gbàgbọ́

Nigba ti wọn pada dé lati Sika pẹlu ounjẹ, awọn ọmọ-ẹhin naa bá Jesu nibi kanga Jakọbu nibi ti wọn fi i silẹ si, nibi ti oun nisinsinyi ti nba obinrin ara Samaria kan sọ̀rọ̀. Nigba ti awọn ọmọ-ẹhin naa dé, obinrin naa lọ kuro, ó sì fi iṣà omi rẹ̀ silẹ, o forile ilu naa.

Bi o ti nifẹẹ gidigidi sí awọn ohun ti Jesu bá a sọ, o wi fun awọn ọkunrin ilu naa pe: “Ẹ wa wo ọkunrin kan, ẹni ti o sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fun mi.” Lẹhin naa, lọna ti o nru ifẹ onitara lati mọ̀ soke, o beere pe: “Eyi ha lè jẹ́ Kristi naa?” Ibeere naa ṣe aṣepari ète rẹ̀—awọn ọkunrin naa lọ lati ríi fun araawọn.

Ní bayii, awọn ọmọ ẹhin rọ Jesu lati jẹ ounjẹ tí wọn gbé wá lati ilu. Ṣugbọn o fesipada pe: “Emi ni ounjẹ lati jẹ, tí ẹyin kò mọ̀.”

“Ẹnikan mú ounjẹ fun un wa lati jẹ bí?” ni awọn ọmọ ẹhin naa bi araawọn. Jesu ṣalaye pe: “Ounjẹ mi lati ṣe ifẹ ẹni ti o ran mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀. Ẹyin kò ha wipe, o kú oṣu mẹrin, ikore yoo sì dé?” Bi o ti wu ki o ri, ni titọka sí ikore tẹmi naa Jesu wipe: “Ẹ gbé oju yin soke, ki ẹ sì wo oko; nitori ti wọn ti funfun fun ikore naa. Ẹni ti nkore ngba owó ọ̀yà, ó sì nko eso jọ si iye ainipẹkun: kí ẹni ti o nfunrugbin ati ẹni ti nkore lè jọ maa yọ̀ pọ̀.”

Boya Jesu ni akoko naa ti ri iyọrisi iṣẹ́ ọlọla ibapade rẹ̀ pẹlu obinrin ara Samaria naa—pe ọpọlọpọ nfi igbagbọ hàn ninu rẹ̀ nitori ẹ̀rí obinrin naa. Obinrin naa njẹrii fun awọn eniyan ilu naa, ni wiwi pe: “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fun mi.” Nitori naa, nigba ti awọn ọkunrin Sika wá bá a nibi kanga naa, wọn sọ fun un pe ki o duro lati bá wọn sọ̀rọ̀ sii. Jesu tẹwọgba ikesini naa ó sì duro fun ọjọ meji.

Bí awọn ara Samaria ti nfetisilẹ sí Jesu, ọpọlọpọ sii tún gbagbọ. Lẹhin naa ni wọn wi fun obinrin naa pe: “Kii ṣe nitori ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ni awa ṣe gbàgbọ́: nitori ti awa tikaraawa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, awa sì mọ̀ pe, nitootọ eyi ni Kristi naa, olugbala araye.” Dajudaju obinrin ara Samaria naa pese apẹẹrẹ rere nipa bi awa ṣe le jẹrii nipa Kristi nipasẹ riru ifẹ lati mọ̀ soke ki awọn olufetisilẹ baa le ṣe iwakiri siwaju sii!

Ranti pe ikore ku oṣu mẹrin—ti o ṣe kedere pe eyi jẹ ikore ọka bali, eyi ti o maa nṣẹlẹ ni ìgbà iruwe ní Palẹstini. Nitori naa afaimọ ni akoko yii kò fi ni jẹ November tabi December. Eyi tumọsi pe tẹle Irekọja 30 C.E., Jesu ati awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ lo nnkan bii oṣu mẹjọ ni Judia ni kikọni lẹkọọ ati bibaptisi. Wọn lọ nisinsinyi si agbegbe ibilẹ wọn ni Galili. Ki ni ohun ti o nduro dè wọn nibẹ? Johanu 4:3-43.

▪ Eeṣe ti ẹnu fi ya obinrin ara Samaria naa pe Jesu bá a sọrọ?

▪ Ki ni ohun tí Jesu kọ́ obinrin naa nipa omi iye ati ibi ijọsin?

▪ Bawo ni Jesu ṣe ṣipaya fun un ẹni ti oun jẹ́, eeṣe ti iṣipaya yii fi jẹ kayefi nla tobẹẹ?

▪ Ijẹrii wo ni obinrin ara Samaria naa ṣe pẹlu iyọrisi wo sì ni?

▪ Bawo ni ounjẹ Jesu ṣe ni nǹkan ṣe pẹlu ikore naa?

▪ Bawo ni a ṣe le pinnu gigun akoko iṣẹ ojiṣẹ Jesu ni Judia tẹle Irekọja 30 C.E.?