Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Pẹlu Awọn Àkàwé

Kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Pẹlu Awọn Àkàwé

Orí 43

Kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Pẹlu Awọn Àkàwé

ÓHÀN gbangba pe Jesu wà ní Kapanaomu nigba ti ó bá awọn Farisi wí lọna tí ó lekoko. Lẹ́hìn náà ní ọjọ kan naa, ó fi ilé naa silẹ ó sì rìn lọ sí Òkun Galili nítòsí, níbi tí ogunlọgọ kórajọ pọ̀ sí. Nibẹ ni ó ti wọ ọkọ̀ oju omi kan, ó wakọ̀ sẹ́hìn kuro ní ilẹ̀, ó sì bẹrẹsii kọ́ awọn eniyan tí wọn ńbẹ ní èbúté lẹ́kọ̀ọ́ nipa Ijọba awọn ọ̀run. O ṣe bẹẹ nipasẹ ọ̀wọ́ awọn òwe, tabi awọn àkàwé, tí ọkọọkan sì jẹ́ pẹlu ìgbékalẹ̀ kan tí awọn eniyan naa mọ̀.

Lákọ̀ọ́kọ́, Jesu sọ nipa afúnrúgbìn kan tí ó ńgbin irúgbìn. Awọn irúgbìn kan bọ́ sílẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà, awọn ẹyẹ sì jẹ ẹ́. Awọn irúgbìn miiran bọ́ sori ilẹ̀ ti o ni apata ti o farasin labẹ rẹ̀. Niwọn bi awọn gbòǹgbò rẹ̀ kò ti jinlẹ̀, awọn ewéko titun naa rọ lábẹ́ oòrùn ti o múhánhán. Sibẹ awọn irúgbìn miiran bọ́ sáàárín ẹ̀gún, eyi tí ó fun awọn ewéko naa pa nigba ti wọn hù sókè. Nikẹhin, awọn irúgbìn kan bọ́ sí ilẹ̀ dídára, wọn sì mú èso jáde ní ìṣẹ́po ọgọrọọrun, awọn kan ìṣẹ́po ọgọtọọta, ati awọn kan ìṣẹ́po ọgbọọgbọn.

Ninu àkàwé miiran, Jesu fi Ijọba Ọlọrun wé ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn. Bí ọjọ́ ti ńgorí ọjọ́, nigba tí ọkunrin naa bá sùn ati nigba ti o bá wà lojufo, irúgbìn naa ńdàgbà. Ọkunrin naa kò mọ bí ó ṣe ṣẹlẹ̀. Ó dàgbà patapata fúnraarẹ̀ ó sì mú eso jade. Nigba ti hóró ọkà naa sì pọ́n, ọkunrin naa kórè rẹ̀.

Jesu sọ àkàwé kẹta nipa ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn yíyẹ, ṣugbọn, “nigba tí awọn eniyan ńsùn,” ọ̀tá kan wá ó sì gbin awọn èpò sáàárín àlìkámà. Awọn iranṣẹ ọkunrin naa beere boya ki wọn tu awọn èpò naa kuro. Ṣugbọn oun fèsì pe: ‘Bẹẹkọ, ẹyin yoo tu lára awọn àlìkámà bí ẹ bá ṣe bẹẹ. Ẹ jẹ́ kí awọn mejeeji dàgbà papọ̀ títí di ìgbà ìkórè. Nigba naa emi yoo sọ fun awọn olùkórè lati kó awọn èpò sọ́tọ̀ kí wọn sì jó wọn kí wọn sì kó awọn àlìkámà sínú abà.’

Ní bíbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí ogunlọgọ ní èbúté naa nìṣó, Jesu pèsè awọn àkàwé meji siwaju sii. O ṣàlàyé pe “ijọba awọn ọrun” dabi hóró musitadi kan tí ọkunrin kan gbìn. Bí ó tilẹ jẹ́ pe oun ni o kere julọ ninu gbogbo irúgbìn, ni oun wí, ó dàgbà di eyi tí ó tóbi jùlọ ninu gbogbo ewébẹ̀. Ó di igi kan tí awọn ẹyẹ ńwá sí, tí wọn ńrí ibi ààbò láàárín awọn ẹ̀ka rẹ̀.

Awọn kan lonii ṣàtakò pe awọn irúgbìn tí ó tun kere jù irúgbìn musitadi lọ nbẹ. Ṣugbọn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ewéko kọ ni Jesu ńfi kọ́ni. Lára awọn irúgbìn tí awọn ara Galili ọjọ́ rẹ̀ mọ̀, irúgbìn musitadi nitootọ ni ó kere jùlọ. Nitori naa wọn mọrírì ìdàgbàsókè àràmériyìírí tí Jesu ńṣàkàwé.

Nikẹhin, Jesu fi “ijọba awọn ọ̀run” wé ìwúkàrà tí obinrin kan mú tí ó sì pò pọ̀ sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ńlá mẹta. Bí àkókò ti ńlọ, ni oun wí, ó mú gbogbo apá ìyẹ̀fun àpòrọ́ naa di wiwu.

Lẹhin fífúnni ní awọn àkàwé márùn-ún wọnyi, Jesu yọnda fun ogunlọgọ naa lati maa lọ si ile ó sì padà sí ilé ibi tí ó wọ̀ sí. Láìpẹ́ awọn apọsiteli rẹ̀ 12 ati awọn miiran tọ̀ ọ́ wá nibẹ.

Jíjàǹfààní Lati Inú Awọn Àkàwé Jesu

Nigba ti awọn ọmọ-ẹhin tọ Jesu wá lẹhin ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí awọn ogunlọgọ ní etíkun, wọn ńtọpinpin lati mọ̀ nipa ọ̀nà ìgbà kọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ titun. Óò, wọn ti gbọ́ ọ tí ó lo awọn àkàwé ṣaaju ìgbà naa ṣugbọn kii ṣe lọna tí ó gbòòrò tobẹẹ. Nitori naa wọn béèrè pe: “Eeṣe tí o fi nfi àkàwé ba awọn wọn sọ̀rọ̀?”

Ìdí kan tí oun fi ńṣe bẹẹ ni lati mú awọn ọ̀rọ̀ wolii naa ṣẹ: “Emi yoo la ẹnu mi pẹlu àkàwé, emi yoo kéde awọn nǹkan wọnni tí o ti fi ara pamọ́ lati àkókò pípilẹ̀.” Ṣugbọn pupọ sii nbẹ ju eyi lọ. Lílò awọn àkàwé rẹ̀ ṣiṣẹ́ lati ṣípayá ẹ̀mí-ìrònú ọkàn-àyà awọn ènìyàn.

Niti tootọ, pupọ awọn eniyan nifẹẹ sí Jesu kìkì nitori pe ó jẹ́ asọ̀tàn agbayanu ati oníṣẹ́ ìyanu, kii ṣe bí ẹnikan tí ó yẹ kí a ṣiṣẹ́sìn gẹgẹ bi Oluwa ki a sì tọ̀ lẹhin láìsí ìmọtara-ẹni-nìkan. Wọn kò fẹ́ kí a dí wọn lọwọ ninu ojú ìwòye wọn nipa awọn nǹkan tabi ọ̀nà igbesi-aye wọn. Wọn kò fẹ́ kí ìhìn-iṣẹ́ naa wọlé ṣinṣin dé àyè yẹn.

Nitori naa Jesu wipe: “Ìdí rẹ̀ niyii tí mo fi ńfi àkàwé bá wọn sọ̀rọ̀, nitori pe, ní wíwò, wọn ńwò lásán, ati ní gbígbọ́, wọn ńgbọ́ lásán, bẹẹ ni òye rẹ̀ kò yé wọn; sí wọn sì ni asọtẹlẹ Aisaya ńní ìmúṣẹ, tí ó wipe, ‘ . . . Nitori ọkàn-àyà awọn eniyan wọnyi ti yigbì.’”

“Bí ó ti wù kí ó rí,” ni Jesu nbaa lọ lati sọ, “aláyọ̀ ni ojú yin nitori wọn rí, ati etí yin nitori wọn gbọ́. Nitori lóòótọ́ ni mo wí fun yin, Ọ̀pọ̀ awọn wolii ati awọn olódodo eniyan fẹ́ lati rí awọn nǹkan tí ẹyin rí wọn kò sì rí wọn, ati lati gbọ́ awọn nǹkan tí ẹyin gbọ́ wọn kò sì gbọ́ wọn.”

Bẹẹni, awọn apọsteli 12 naa ati awọn tí wọn wà pẹlu wọn ní awọn ọkàn-àyà tí ńgba nǹkan wọlé. Nitori naa Jesu wipe: “Ẹyin ni a ti fifún lati lóye awọn àṣírí mímọ́ ti ijọba awọn ọ̀run, ṣugbọn a kò fifún awọn eniyan wọnni.” Nitori ìfẹ́-ọkàn wọn fun òye, Jesu ṣàlàyé àkàwé afúnrúgbìn naa fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

“Irúgbìn naa ni ọ̀rọ̀ Ọlọrun,” ni Jesu sọ, ilẹ̀ sì jẹ́ ọkàn-àyà. Nipa irúgbìn tí a gbìn sí ojú ọ̀nà ti ilẹ̀ rẹ̀ lekoko, oun ṣàlàyé pe: “Eṣu wá ó sì mú ọ̀rọ̀ naa kuro ní ọkàn-àyà wọn kí wọn kí ó maa baa gbàgbọ́ kí a maa baa sì ṣe gbà wọn là.”

Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, irúgbìn tí a gbìn sórí ilẹ̀ tí ó ní àpáta tí ó farasin lábẹ́ rẹ̀ tọ́ka sí ọkàn-àyà awọn eniyan tí wọn gba ọ̀rọ̀ naa pẹlu ayọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nitori pe ọ̀rọ̀ naa kò lè ta gbòǹgbò ninu irúfẹ́ awọn ọkàn-àyà bẹẹ, awọn eniyan wọnyi ṣubú kuro nigba ti àkókò ìdánwò tabi inúnibíni dé.

Niti irúgbìn tí ó bọ́ sáàárín awọn ẹ̀gún, ni Jesu nbaa lọ, eyi tọ́kasí awọn eniyan tí wọn ti gbọ́ ọ̀rọ̀ naa. Awọn wọnyi, bí ó ti wù kí ó rí, ni àníyàn ati awọn ọrọ̀ ati ìgbádùn ayé yii gbélọ, ati nitori naa a fún wọn pa patapata tí wọn kò sì mú ohunkohun dé ìjẹ́pípé.

Paríparí rẹ̀, niti irúgbìn tí a gbìn sórí ilẹ̀ rere, Jesu wipe, iwọnyi ni awọn ẹni tí, lẹhin tí wọn ti gbọ́ ọ̀rọ̀ naa pẹlu ọkàn-àyà rere tí ó sì dára, pa á mọ́ wọn sì so èso pẹlu ìfaradà.

Bawo ni awọn ọmọ-ẹhin wọnyi tí wọn ti wá Jesu kiri lati rí àlàyé awọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ gbà ti jẹ́ ẹni ibukun tó! Jesu pète pe kí a lóye awọn àkàwé rẹ̀ lati fi otitọ fun awọn ẹlomiran. “A kìí mú fìtílà wá lati gbé e sábẹ́ agbọ̀n òṣùwọ̀n tabi sábẹ́ ibùsùn, a ńṣe é bẹẹ bí?” ni oun beere. Bẹẹkọ, “a gbé e wá lati gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà.” Nipa bayii Jesu fikun un pe: “Nitori naa, ẹ fiyèsí bí ẹ ti nfetisilẹ.”

A Bukun Wọn Pẹlu Ìtọ́ni Pupọ Síi

Lẹhin gbígbọ́ àlàyé Jesu nipa àkàwé afúnrúgbìn, awọn ọmọ-ẹhin fẹ́ lati kẹ́kọ̀ọ́ sí i. “Ṣàlàyé fun wa,” ni wọn beere, “àkàwé nipa èpò inú pápá.”

Ẹ wo bi ẹ̀mí-ìrònú awọn ọmọ-ẹhin ṣe yàtọ̀ tó sí iyoku ogunlọgọ naa ní etíkun! Awọn eniyan wọnni kò ní ìfẹ́-ọkàn onítara lati kẹ́kọ̀ọ́ itumọ awọn àkàwé naa, bí ó ti jẹ́ pe wọn ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu akopọ ṣoki awọn nǹkan tí a là lẹsẹẹsẹ ninu wọn. Ní fífa ìyàtọ̀ yọ láàárín àwùjọ olùgbọ́ ẹ̀bá òkun naa ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ atọpinpin tí wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ninu ilé naa, Jesu wipe:

“Òṣùwọ̀n tí ẹyin fi ńwọ̀n jáde, oun ni a o fi wọ̀n fun yin, bẹẹni, a o fi pupọ kún un fun yin.” Awọn ọmọ-ẹhin naa ńwọ̀n ọkàn-ìfẹ́ ati àfiyèsí onítara fun Jesu, ati nitori naa a bukun wọn pẹlu gbígba ìtọ́ni pupọ sí i. Nipa bayii, ní ìdáhùn sí ìwádìí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Jesu ṣàlàyé pe:

“Afúnrúgbìn irúgbìn rere naa ni Ọmọkunrin ènìyàn; pápá ni ayé; niti irúgbìn rere, awọn wọnyi ni awọn ọmọ ijọba naa; ṣugbọn èpò ni awọn ọmọ ẹni buruku naa, ọ̀tá tí ó sì fun wọn ni Eṣu. Ìkórè ni òpin ètò ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan, awọn angẹli si ni olùkórè.”

Lẹhin fifi ẹ̀ka kọọkan àkàwé rẹ̀ hàn, Jesu ṣàpèjúwe àbárèbábọ̀ rẹ̀. Ní òpin ètò ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan, o sọ pe awọn olùkórè, tabi awọn angẹli, yoo ya awọn Kristẹni ayédèrú ẹni bíi èpò sọ́tọ̀ kuro lára “awọn ọmọkunrin ijọba” tootọ. Lẹhin naa “awọn ọmọkunrin ẹni buruku naa” ni a ó sàmìsí fun ìparun, ṣugbọn awọn ọmọkunrin Ijọba Ọlọrun, “awọn olódodo,” yoo maa tàn yòò ninu Ijọba Baba wọn.

Lẹhin naa Jesu bukun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ atọpinpin pẹlu awọn àkàwé mẹta sí i. Lákọ̀ọ́kọ́, oun wipe: “Ijọba awọn ọ̀run dàbíi ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú pápá, eyi tí ọkunrin kan rí tí ó sì fi pamọ́; ati nitori ayọ̀ tí ó ní ó lọ ó sì ta awọn nǹkan tí ó ní ó sì ra pápá yẹn.”

“Ẹ̀wẹ̀,” ó ńbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó, “ijọba awọn ọ̀run dabi alájàpá kan tí ńwá awọn peali rere kiri. Nigba tí ó rí peali kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga, ó jáde lọ ó sì ta gbogbo ohun tí ó ní ó sì rà á.”

Jesu fúnraarẹ̀ ni ó dabi ọkunrin naa tí ó ṣàwárí ìṣúra tí a fi pamọ́ ati bí alájàpá naa tí ó rí peali kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga. O tá ohun gbogbo tí ó ní, kí a sọ ọ lọna bẹẹ, ní fífi ipò ọlá silẹ ní ọ̀run tí ó sì wá di ẹ̀dá-ènìyàn rírẹlẹ̀. Lẹhin naa, gẹgẹ bi ọkunrin kan lórí ilẹ̀-ayé, o jìyà ẹ̀gàn ati inúnibíni kikoro, ní fífi ẹ̀rí ìtóótun rẹ̀ hàn lati jẹ Olùṣàkóso Ijọba Ọlọrun.

Ìpènijà kan naa ni a gbéka iwaju awọn ọmọ-ẹhin Jesu lati ta ohun gbogbo lati lè gba èrè ńláǹlà ti jíjẹ́ yálà alájùmọ̀ ṣàkóso pẹlu Kristi tabi ọmọ-abẹ́ Ijọba lórí ilẹ̀-ayé. Awa yoo ha ka nínípìn-ín kan ninu Ijọba Ọlọrun sí ohun tí ó ṣe iyebíye ju ohunkohun miiran lọ ninu igbesi-aye, gẹgẹ bi ìṣúra tí kò ṣeédíyelé kan tabi peali oníyebíye kan?

Nikẹhin, Jesu fi “ijọba awọn ọ̀run naa” wé àwọ̀n ńlá kan tí ó kó onírúurú ẹja jọ. Nigba ti a ya awọn ẹja naa sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, awọn tí kò dára ni a dànù ṣugbọn awọn tí ó dára ni a pamọ́. Nitori naa, Jesu wipe, bẹẹ ni yoo jẹ́ ní òpin ètò ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan; awọn angẹli yoo ṣe ìyàsọ́tọ̀ awọn ẹni buruku kuro lára awọn olódodo, tí wọn yoo sì tọ́jú awọn ẹni buruku pamọ́ fun ìparun ráúráú.

Jesu fúnraarẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ apẹja yii, ní pípe awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ àkọ́kọ́ lati jẹ́ “awọn apẹja eniyan.” Lábẹ́ àbójútó awọn angẹli, iṣẹ́ ìpẹja naa nbaa nìṣó la awọn ọ̀rúndún kọjá títí di isinsinyi. Nígbẹ̀hìn gbẹ́hín àkókò naa tó lati fa “àwọ̀n ńlá” naa sókè, eyi tí ó ṣàpẹẹrẹ awọn ètò-àjọ orí ilẹ̀-ayé tí wọn fẹnu sọ pe awọn jẹ́ Kristẹni.

Bí ó tilẹ jẹ́ pe awọn ẹja ti kò dára ni a parun, pẹlu ọpẹ́ a lè kà wa kún ara awọn ‘ẹja daradara’ tí a pamọ́. Nipa fifi ìfẹ́-ọkàn onitara kan-naa hàn gẹgẹ bi awọn ọmọ-ẹhin Jesu ti ṣe fun ìmọ̀ ati òye pupọ sí i, a ó bukun wa kii ṣe kìkì pẹlu ìtọ́ni pupọ sí i nikan ni ṣugbọn pẹlu ibukun Ọlọrun tí ó jẹ iye ayeraye. Matiu 13:1-52; Maaku 4:1-34; Luuku 8:4-18; Saamu 78:2; Aisaya 6:9, 10.

▪ Nigba wo ati nibo ni Jesu ti fi pẹlu awọn apejuwe bá ogunlọgọ sọ̀rọ̀?

▪ Awọn àkàwé márùn-ún wo ni Jesu sọ fun ogunlọgọ naa nisinsinyi?

▪ Eeṣe tí Jesu fi sọ pe irúgbìn musitadi ni ó kere julọ ninu gbogbo irúgbìn?

▪ Eeṣe tí Jesu fi sọ̀rọ̀ pẹlu awọn àkàwé?

▪ Bawo ni awọn ọmọ-ẹhin Jesu ṣe fi araawọn hàn pe wọn yàtọ̀ sí awọn ogunlọgọ naa?

▪ Àlàyé wo ni Jesu pèsè fun àkàwé afúnrúgbìn?

▪ Bawo ni awọn ọmọ-ẹhin ṣe yàtọ̀ sí ogunlọgọ naa ní etíkun?

▪ Ta ni tabi ki ni afúnrúgbìn, pápá, irúgbìn rere, ọ̀tá, ìkórè, ati awọn olùkórè dúró fún?

▪ Awọn àfikún àkàwé mẹta wo ni Jesu pèsè, kí sì ni a lè kẹ́kọ̀ọ́ lati inú wọn?