Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ki Ni Ńsọ Ènìyàn di Ẹlẹ́gbin?

Ki Ni Ńsọ Ènìyàn di Ẹlẹ́gbin?

Orí 56

Ki Ni Ńsọ Ènìyàn di Ẹlẹ́gbin?

ÀTAKÒ sí Jesu tubọ ńlágbára sí i. Kii ṣe kìkì pe ọ̀pọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fi i silẹ nikan ni ṣugbọn awọn Juu ní Judia ńwá ọ̀nà lati pa á, ani bí wọn ti ṣe nigba ti ó wà ní Jerusalẹmu ni akoko Irekọja ti 31 C.E.

O jẹ akoko fun Irekọja ti 32 C.E. nisinsinyi. Boya ní ibamu pẹlu ohun tí Ọlọrun beere fun lati lọ sibẹ, Jesu gòkè lọ fun Irekọja naa ní Jerusalẹmu. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣe bẹẹ pẹlu ọgbọ́n nitori ẹ̀mí rẹ̀ wà ninu ewu. Lẹhin naa ó padà sí Galili.

Ó lè jẹ́ pe Kapanaomu ni Jesu wà nigba ti awọn Farisi ati awọn akọwe-ofin lati Jerusalẹmu wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọn ńwá ìpìlẹ̀ lórí eyi tí wọn yoo fi fẹ̀sùnkàn án fun rírú òfin ìsìn. “Eeṣe tí awọn ọmọ-ẹhin rẹ fi ńré awọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ awọn ènìyàn ìgbà àtijọ́ kọjá?” ni wọn wádìí. “Fun apẹẹrẹ, wọn kìí wẹ ọwọ́ wọn nigba ti wọn bá fẹ́ jẹun.” Eyi kii ṣe ohun kan tí Ọlọrun beere, sibẹ awọn Farisi kà á sí láìfí wíwúwo kan lati maṣe mú ààtò ìsìn àtọwọ́dọ́wọ́ yii ṣe, eyi tí ó ní ninu wíwẹ́ ọwọ́ dé ìgúnpá.

Kàkà tí ìbá fi dáhùn ẹ̀sùn wọn, Jesu tọkasi ìwà buburu wọn ati bi wọn ṣe ńmọ̀ọ́mọ̀ rú Òfin Ọlọrun. “Eeṣe tí ẹyin pẹlu fi ńré òfin Ọlọrun kọjá nitori òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yin?” ó fẹ́ lati mọ̀. “Fun apẹẹrẹ, Ọlọrun wipe, ‘Bọlá fún baba rẹ ati iya rẹ’; ati, ‘Jẹ́ kí ẹni tí ó bá kẹ́gàn baba tabi iya kú ikú rẹ̀.’ Ṣugbọn ẹyin wipe, ‘Ẹni yoowu tí ó bá wí fun baba tabi iya rẹ̀ wipe: “Ohun yoowu tí mo ní nipa eyi tí iwọ ìbá fi jàǹfààní lati ọ̀dọ̀ mi jẹ́ ẹ̀bùn tí a yàsọ́tọ̀ fun Ọlọrun,” oun kò gbọdọ bọlá fún baba rẹ̀ rárá.’”

Nitootọ, awọn Farisi kọ́ni pe owó, dúkìá, tabi ohunkohun tí a yàsímímọ́ gẹgẹ bi ẹ̀bùn kan fun Ọlọrun jẹ́ ti tẹmpili tí a kò sì lè lò ó fun ète miiran mọ́. Sibẹ, niti tootọ, ẹ̀bùn tí a yàsímímọ́ naa ni ẹni tí ó yà á sí mímọ́ tọju tikaraarẹ. Ní ọ̀nà yii ọmọkunrin kan, nipa wíwulẹ̀ sọ pe owó tabi dúkìá rẹ̀ jẹ́ “kọbani”—ẹ̀bùn kan tí a yàsímímọ́ fun Ọlọrun tabi fun tẹmpili—yẹ ẹrù-iṣẹ́ rẹ̀ silẹ lati ran awọn òbí rẹ̀ àgbàlagbà lọwọ, awọn ẹni tí ó ṣeeṣe kí wọn wà ninu ìpọ́njú lílekoko.

Ní bibinu si awọn Farisi fun lílọ́ Òfin Ọlọrun lọna buburu bẹẹ, Jesu wipe: “Ẹyin sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun di aláìlágbára nipa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yin. Ẹyin àgàbàgebè, Aisaya sọtẹlẹ daradara nipa yin, nigba ti ó wipe, ‘Awọn ènìyàn wọnyi ńfi ètè wọn bọlá fún mi, sibẹ ọkàn-àyà wọn jìnnà kuro lọdọ mi. Lásán ni wọn ńjọ́sìn mi, nitori wọn ńfi òfin ènìyàn kọ́ni gẹgẹ bi ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́.’”

O ṣeeṣe ki awọn ogunlọgọ naa ti fasẹhin lati fun awọn Farisi láàyè lati bi Jesu ní ibeere. Nisinsinyi, nigba ti awọn Farisi kò ní ìdáhùn kankan sí ìdálẹ́bi lílekoko tí Jesu fun wọn, ó pe ogunlọgọ naa sunmọtosi. “Ẹ fetisilẹ sí mi,” ni oun wí, “kí ẹ sì mọ itumọ naa. Kò sí ohunkohun lati òde ara ènìyàn tí ńkọjá sínú rẹ̀ tí ó lè sọ ọ di ẹlẹ́gbin; ṣugbọn awọn nǹkan tí ńjáde wá lati inú ènìyàn ni awọn nǹkan tí ńsọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.”

Lẹhin eyi, nigba ti wọn wọ ilé kan, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ beere pe: “Iwọ ha mọ̀ pe awọn Farisi kọsẹ̀ bí wọn ti gbọ́ ohun tí iwọ wí?”

“Olukuluku igi tí Baba mi ọ̀run kò bá gbìn ni a ó fàtu,” ni Jesu dáhùn. “Ẹ jọwọ wọn sí. Afọ́jú amọ̀nà ni wọn. Nigba naa, bí afọ́jú bá ńfi ọ̀nà han afọ́jú, awọn mejeeji yoo ṣubú sinu kòtò.”

Ó jọ pe ẹnu ya Jesu nigba ti, Peteru, ní gbígbẹnusọ fun awọn ọmọ-ẹhin beere fun ohun tí ńsọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin. “Ẹyin pẹlu ha ṣì jẹ́ aláìlóye sibẹ?” ni Jesu dáhùnpadà. “Ẹyin kò ha mọ̀ pe ohun gbogbo tí ńwọ ẹnu nrekọja lọ sínú ìfun a ó sì yà á dànù sínú ilé ìgbẹ́? Bí ó ti wù kí ó rí, awọn nǹkan tí ńti ẹnu jáde wá lati inú ọkàn-àyà, nǹkan wọnni sì ńsọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin. Fun apẹẹrẹ, lati inú ọkàn-àyà ni awọn èrò buruku, ìpànìyàn, ìwà-panṣágà, ìwà-àgbèrè, olè-jíjà, ẹ̀rí èké, ọ̀rọ̀-òdì ti ńjáde wá. Iwọnyi ni awọn nǹkan tí ńsọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin; ṣugbọn lati fi ọwọ́ tí a kò wẹ̀ jẹun kò sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.”

Jesu níhìn-ín kò sọ pe àṣà ìmọ́tótó tí ó yẹ kò dára. Oun kò jiyàn pe ẹnikan kò nilati fọ awọn ọwọ́ rẹ̀ ṣaaju síse ounjẹ tabi jijẹun. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jesu ńdẹ́bi fún ìwà àgàbàgebè awọn aṣaaju isin awọn ẹni tí wọn fi békebèke gbìyànjú lati yí awọn òfin òdodo Ọlọrun po nipa títẹpẹlẹmọ́ awọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò bá iwe mimọ mu. Bẹẹni, awọn ìṣe buburu ni ńsọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin, Jesu sì fihàn pe iwọnyi ńpilẹ̀ṣẹ̀ lati inú ọkàn-àyà ẹnikan wá. Johanu 7:1; Deutaronomi 16:16; Matiu 15:1-20, NW; Maaku 7:1-23; Ẹkisodu 20:12; 21:17; Aisaya 29:13.

▪ Àtakò wo ni Jesu dojúkọ nisinsinyi?

▪ Ẹ̀sùn wo ni awọn Farisi mú wá, ṣugbọn gẹgẹ bi Jesu ti wí, bawo ni awọn Farisi ṣe mọ̀ọ́mọ̀ rú Òfin Ọlọrun?

▪ Ki ni awọn ohun tí Jesu ṣípayá pe ó ńsọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin?