Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kristi Wọ Jerusalẹmu Pẹlu Ayọ̀ Ìṣẹ́gun

Kristi Wọ Jerusalẹmu Pẹlu Ayọ̀ Ìṣẹ́gun

Orí 102

Kristi Wọ Jerusalẹmu Pẹlu Ayọ̀ Ìṣẹ́gun

NÍ ÒWÚRỌ̀ ọjọ tí ó tẹle e, Sunday, Nisan 9, Jesu fi Bẹtani silẹ papọ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ó sì forílé Òkè Olifi síhà Jerusalẹmu. Laipẹ wọn súnmọ́ Bẹtifage, tí ó wà lórí Òkè Olifi. Jesu fun meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ní ìtọ́ni pe:

“Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yin, lọ́gán ẹyin yoo rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, ati ọmọ rẹ̀ pẹlu, ẹ tú wọn, kí ẹ sì fà wọn fun mi wá. Bí ẹnikẹni bá sì wí nǹkan fun yin, ẹyin yoo wipe, Oluwa ní fi wọn ṣe; lọ́gàn ni yoo sì rán wọn wá.”

Bí ó tilẹ jẹ́ pe lákọ̀ọ́kọ́ awọn ọmọ-ẹhin naa kò mọ̀ pe awọn ìtọ́ni wọnyi ní ohunkohun ṣe pẹlu ìmúṣẹ asọtẹlẹ Bibeli, lẹhin naa wọn mọ̀ pe wọn ṣe bẹẹ. Wolii naa Sekaraya sọtẹ́lẹ̀ pe Ọba tí Ọlọrun ṣeleri yoo gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerusalẹmu, bẹẹni, “ó sì ńgun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” Solomoni Ọba bakan naa ti gùn ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ síbi tí a ti fòróró yàn án.

Nigba ti awọn ọmọ-ẹhin naa wọ̀ Bẹtifage tí wọn sì mú ọmọ kẹtẹkẹtẹ naa ati iya rẹ̀, diẹ lára awọn tí wọn dúró nítòsí wipe: “Ki ni ẹyin ńṣe?” Ṣugbọn nigba ti a sọ fun wọn pe awọn ẹran naa wà fun Oluwa, awọn ọkunrin naa jẹ́ kí awọn ọmọ-ẹhin mú wọn lọ fun Jesu. Awọn ọmọ-ẹhin fi awọn ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn sórí ìyà kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ naa ati sórí ọmọ rẹ̀, ṣugbọn Jesu gùn ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ naa.

Bí Jesu ti ńgùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerusalẹmu, ogunlọgọ naa ńpọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ awọn eniyan tẹ́ awọn ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn sí ojú-ọ̀nà, nigba tí awọn miiran gé awọn ẹ̀ka lati ara awọn igi tí wọn sì ńtẹ́ wọn silẹ. ‘Olubukun ni ẹni tí ńbọ̀wá gẹgẹ bi Ọba ní orukọ Jehofa!’ ni wọn ńkígbe. ‘Alaafia ní ọ̀run, ati ògo ní awọn ibi gíga jùlọ!’

Ọkan diẹ lara awọn Farisi ninu ogunlọgọ naa gbọgbẹ́ nipasẹ ìpòkìkí wọnyi tí wọn sì ráhùn fun Jesu pe: “Olukọni, bá awọn ọmọ-ẹhin rẹ wí.” Ṣugbọn Jesu fèsì pe: “Mo wí fun yin, bí awọn wọnyi bá pa ẹnu wọn mọ́, awọn okuta yoo kígbe sókè.”

Bí Jesu ti sunmọ Jerusalẹmu, ó wò ìlú naa ó sì bẹrẹsii sọkún sórí rẹ̀, ní wiwi pe: “Ìbáṣepé iwọ mọ̀, lonii yii, àní iwọ, ohun tíí ṣe ti alaafia rẹ! Ṣugbọn nisinsinyi wọn pamọ́ kuro ní ojú rẹ.” Fun mímọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn, Jerusalẹmu gbọdọ san iye owo naa, gẹgẹ bi Jesu ti sọtẹ́lẹ̀:

“Awọn ọta rẹ [awọn ara Roomu lábẹ́ Ọ̀gágun Titu] yoo wa yàrà ká ọ, wọn yoo sì yí ọ ká, wọn yoo sì sàgatì ọ níhà gbogbo, wọn yoo sì wó ọ palẹ̀ bẹẹrẹ, ati awọn ọmọ rẹ ninu rẹ; wọn kì yoo sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí araawọn.” Ìparun Jerusalẹmu tí Jesu sọtẹ́lẹ̀ yii wáyé niti gidi ní ọdun 37 lẹhin naa, ní 70 C.E.

Ní kíkí awọn ọsẹ diẹ ṣaaju ìgbà naa, ọpọlọpọ ninu ogunlọgọ naa ti rí Jesu nigba tí ó jí Lasaru dìde. Nisinsinyi awọn wọnyi nbaa lọ ní sísọ fun awọn ẹlomiran nipa iṣẹ́ ìyanu yẹn. Nitori naa nigba ti Jesu wọ̀ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú naa mì tìtì. “Ta ni yí?” awọn eniyan ńfẹ́ lati mọ̀. Awọn ogunlọgọ naa sì nbaa lọ ní sísọ pe: “Eyi ni Jesu wolii, lati Nasarẹti ti Galili!” Ní rírí ohun tí ńṣẹlẹ̀, awọn Farisi dárò pe awọn kò lè borí ní ohunkohun rárá, nitori, gẹgẹ bi wọn ti sọ: “Gbogbo ayé ti ńwọ́ tọ̀ ọ́.”

Gẹgẹ bi ó ti jẹ́ àṣà rẹ̀ nigba ti ó bá ṣèbẹ̀wò sí Jerusalẹmu, Jesu lọ sí tẹmpili lati kọ́ni. Nibẹ awọn afọ́jú ati arọ tọ̀ ọ́ wá, ó sì ńwò wọn sàn! Nigba ti awọn olórí alufaa ati awọn akọwe ofin rí awọn ohun yíyanilẹ́nu tí Jesu ńṣe ati nigba ti wọn gbọ́ tí awọn ọmọdekunrin ninu tẹmpili ńkígbe jáde pe, ‘Gbanilà, awa gbadura, Ọmọkunrin Dafidi!’ inú bí wọn. “Iwọ gbọ́ eyi tí awọn wọnyi ńwí?” ni wọn ṣàtakò.

“Bẹẹni,” ni Jesu fèsì. “Ẹyin kò ti kà á ninu ìwé pé, Lati ẹnu awọn ọmọ-àgbo ati awọn ọmọ-ọmú ni iwọ ti mú ìyìn pé?”

Jesu nbaa lọ lati maa kọ́nilẹ́kọ̀ọ́, ó sì ńwò ohun gbogbo tí nbẹ ní tẹmpili naa. Láìpẹ́ ilẹ̀ ti ṣú. Nitori naa ó kuro nibẹ, papọ̀ pẹlu awọn 12, ó sì rìnrìn àjò nǹkan bii ibùsọ̀ meji pada sí Bẹtani. Nibẹ ni ó ti lò òru Sunday, boya ní ilé Lasaru, ọ̀rẹ́ rẹ̀. Matiu 21:1-11, 14-17; Maaku 11:1-11; Luuku 19:29-44; Johanu 12:12-19; Sekaraya 9:9.

▪ Nigba wo ati ní irú ọ̀nà wo ni Jesu gba wọ Jerusalẹmu gẹgẹ bi Ọba?

▪ Bawo ni ó ti ṣe pàtàkì tó pe awọn ogunlọgọ naa yin Jesu?

▪ Bawo ni Jesu ṣe nímọ̀lára nigba ti ó wò Jerusalẹmu, asọtẹlẹ wo ni oun sì sọ?

▪ Ki ni ó ṣẹlẹ nigba ti Jesu lọ sí tẹmpili?