Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lẹhin Dídé Ilé ní Kapanaomu

Lẹhin Dídé Ilé ní Kapanaomu

Orí 26

Lẹhin Dídé Ilé ní Kapanaomu

NÍSINSINYI òkìkí Jesu ti tànkálẹ̀, ọpọlọpọ ènìyàn sì rìnrìn àjò lọ sí ibi jíjìnnà réré tí oun ńgbé. Lẹhin ọjọ́ melookan, bí ó ti wù kí ó rí, oun padà sí Kapanaomu lórí Òkun Galili. Ní kiakia ni ìròhìn naa tànkálẹ̀ kaakiri ìlú-ńlá naa pe oun ti padà dé ilé, ọpọlọpọ sì wá sí inú ilé ibi tí oun wà. Awọn Farisi ati awọn olùkọ́ Òfin wá lati Jerusalẹmu bí ó ti jìnnà tóo nì.

Ogunlọgọ naa pọ̀ tí ó fi jẹ́ pe wọn rọ́ di ẹnu ọ̀nà àbáwọlé naa, kò sì sí àyè fun ẹnikẹni miiran lati wọlé. Imurasilẹ ni a ti ṣe fun ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti o pẹtẹrí nitootọ. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò yii jẹ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì gidi, nitori ó ràn wa lọwọ lati mọrírì pe Jesu ní agbára lati mú ohun tí ńṣokùnfà ìjìyà ẹ̀dá-ènìyàn kuro kí ó sì mú ìlera padàbọ̀sípò fun gbogbo awọn wọnni tí oun bá yàn.

Nigba tí Jesu ńkọ ogunlọgọ naa lẹ́kọ̀ọ́, awọn ọkunrin mẹrin gbé ọkunrin alárùn ẹ̀gbà tí ó wà lórí àkéte kan wá sínú ilé naa. Wọn fẹ́ kí Jesu mú ọ̀rẹ́ wọn láradá, ṣugbọn nitori ogunlọgọ naa, wọn kò lè wọlé. Ẹ wo bí eyi ti jẹ́ ìjákulẹ̀ tó! Sibẹ wọn kò juwọ́sílẹ̀. Wọn gòkè lọ sórí òrùlé, wọn dá ihò lu sára rẹ̀, wọn sì rọ̀ àkéte naa pẹlu ọkunrin ti o ni àrùn ẹ̀gbà naa lórí rẹ̀ silẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jesu.

Jesu ha bínú nitori pe a da ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu bí? Kí a ma ríi! Kàkà bẹẹ, ìgbàgbọ́ wọn wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin. Ó sọ fun alárùn ẹ̀gbà naa pe: “A dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì.” Ṣugbọn njẹ Jesu niti tootọ ha lè dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ jì bí? Awọn akọwe ati awọn Farisi kò rò bẹẹ. Wọn ronú ninu ọkàn-àyà wọn pe: “Eeṣe tí ọkunrin yii fi ńsọ̀rọ̀ ní irú ọ̀nà yii? Ó ńsọ̀rọ̀ òdì. Ta ni lè dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ jì bikoṣe ẹnikan, Ọlọrun?”

Ní mímọ èrò wọn, Jesu sọ fun wọn pe: “Eeṣe tí ẹ fi ńronú nǹkan wọnyi ninu ọkàn-àyà yin? Ewo ni ó rọrùn jù, lati wí fun alárùn ẹ̀gbà naa pe, ‘A dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì,’ tabi lati wipe, ‘Dìde kí o sì gbé àkéte rẹ kí o sì maa rìn’?”

Nigba naa, Jesu yọnda ogunlọgọ naa, tí ó ní ninu awọn lámèyítọ́ rẹ̀, lati rí àṣefihàn pípẹtẹrí kan tí yoo ṣípayá pe oun ní àṣẹ lati dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ jì lórí ilẹ̀-ayé ati pe oun nitootọ jẹ́ ọkunrin gíga jùlọ tí ó tíì wà rí. Ó yíjúsí alárùn ẹ̀gbà naa ó sì pàṣẹ pe: “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì lọ sí ilé rẹ.” Lẹsẹkẹsẹ ni oun sì ṣe bẹẹ, ní rírìn lọ pẹlu àkéte rẹ̀ niwaju gbogbo wọn! Pẹlu iyalẹnu awọn ènìyàn naa yin Ọlọrun lógo, wọn sì ṣe sáàfúlà wipe: “Awa kò rí irú rẹ̀ rí lae”!

Njẹ o ṣàkíyèsí pe Jesu mẹ́nukàn awọn ẹ̀ṣẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹlu àìsàn ati pe dídárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ jì ní ìbátan pẹlu jíjèrè ìlera nipa ti ara? Bibeli ṣàlàyé pe òbí wa àkọ́kọ́, Adamu, dẹ́ṣẹ̀, ati pe, gbogbo wa ni a ti jogún awọn àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ yẹn, eyiini ni, àìsàn ati ikú. Ṣugbọn lábẹ́ àkóso Ijọba Ọlọrun, Jesu yoo dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì gbogbo awọn tí wọn fẹ́ràn Ọlọrun tí wọn sì ṣiṣẹ́sìn Ín, ati lẹhin naa gbogbo àìsàn ni a ó múkúrò. Bawo ni iyẹn yoo ti dárá to! Maaku 2:1-12; Luuku 5:17-26; Matiu 9:1-8; Roomu 5:12, 17-19.

▪ Imurasilẹ wo ni o wà fun ìṣẹ̀lẹ̀ pípẹtẹrí tootọ kan?

▪ Bawo ni alárùn ẹ̀gbà naa ṣe dé ọ̀dọ̀ Jesu?

▪ Eeṣe tí gbogbo wa fi jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn bawo ni Jesu ṣe pèsè ìrètí pe ìdáríjì awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ati ìlera pípé ṣeéṣe?