Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mímú Asọtẹlẹ Aisaya Ṣẹ

Mímú Asọtẹlẹ Aisaya Ṣẹ

Orí 33

Mímú Asọtẹlẹ Aisaya Ṣẹ

LẸHIN ti Jesu mọ pe awọn Farisi ati awọn ọmọ-ẹhin ẹgbẹ́ Hẹrọdu ńwéwèé lati pa oun, oun ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ padà sẹ́hìn sí Òkun Galili. Níhìn-ín awọn ogunlọgọ nla eniyan wọ́ gìrìgìrì tọ̀ ọ́ wá jakejado Palẹstini, ati paapaa lati òde awọn ààlà ẹnubodè rẹ̀. Ó wò ọpọlọpọ sàn, pẹlu àbájáde naa pe gbogbo awọn wọnni tí wọn ní òkùnrùn aronilára nsunmọ iwaju pẹlu ipinnu lati fọwọ́kàn án.

Nitori pe ogunlọgọ naa tóbi lọpọlọpọ, Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe kí wọn mú ọkọ̀ kan wà lárọ̀ọ́wọ́tó nigba gbogbo fun ìlò rẹ̀. Nipa wíwa ọkọ̀ sẹhin diẹ kuro ní èbúté, oun lè ṣèdíwọ́ fun awọn ogunlọgọ naa lati má rọ́lù ú. Oun lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ lati inú ọkọ naa tabi rìnrìn àjò lọ sí àgbègbè miiran lẹgbẹẹ èbúté lati ran awọn ènìyàn lọwọ nibẹ.

Ọmọ-ẹhin naa Matiu ṣàkíyèsí pe ìgbòkègbodò Jesu mú “ohun tí a ti sọ lati ẹnu Aisaya wolii” ṣẹ. Lẹhin naa ni Matiu fa ọ̀rọ̀ asọtẹlẹ naa tí Jesu múṣẹ yọ:

“Wòó! Iranṣẹ mi tí mo yàn, olùfẹ́ mi, ẹni tí ọkàn mi tẹ́wọ́gbà! Emi yoo fi ẹ̀mí mi sórí rẹ̀, ati ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ ni oun yoo mú ṣe kedere fun awọn orílẹ̀-èdè. Oun kì yoo ṣe awuyewuye, tabi ké tantan, bẹẹ ni ẹnikẹni kì yoo gbọ́ ohùn rẹ̀ ní awọn ọ̀nà fífẹ̀. Kò sí esùsú tí a halára tí oun yoo tẹ̀fọ́, kò sì sí òwú àtùpà ọlọ́gbọ̀ tí ńjó lọ́úlọ́ú tí oun yoo pa, títí oun yoo fi rán ìdájọ́ òdodo jáde pẹlu ìyọrísírere. Nitootọ, ninu orukọ rẹ̀ ni awọn orílẹ̀-èdè yoo ní ireti.”

Jesu, dajudaju, jẹ́ iranṣẹ olùfẹ́ naa ẹni tí Ọlọrun tẹ́wọ́gbà. Jesu sì mú ohun tí ìdájọ́ òdodo tootọ jẹ ṣe kedere, eyi tí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn èké ńmú kí ó ṣókùnkùn. Nitori tí wọn ńfi òfin Ọlọrun sílò lọna tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu, awọn Farisi kò ní ràn ẹnikan tí àìsàn ńṣe paapaa lọwọ ní Sabaati! Ní mímú ìdájọ́ òdodo Ọlọrun ṣe kedere, Jesu gba awọn ènìyàn kuro ninu ẹrù ìnira awọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ti kò bá ìdájọ́ òdodo mu, ati fun eyi, awọn aṣaaju isin gbìyànjú lati pa á.

Ki ni ohun tí ó tumọsi pe ‘oun kì yoo ṣe awuyewuye, tabi gbé ohùn rẹ̀ sókè tantan kí wọn lè gbọ́ ọ ní awọn ọ̀nà fífẹ̀’? Nigba ti ó ńwo awọn ènìyàn sàn, Jesu ‘pàṣẹ fun wọn láìyẹhùn kí wọn maṣe fi oun hàn ni gbangba.’ Oun kò fẹ́ ìfọnrere aláriwo nipa araarẹ̀ ní awọn ojú pópó tabi lati ta àtaré awọn ìròhìn tí a lọpo lọna ti nru igbonara soke lati ẹnu sí ẹnu.

Pẹlupẹlu, Jesu mú awọn ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ tí ńtunilára wá fun awọn ènìyàn tí wọn dabi esùsú tí a halára, tí a ṣẹ́po tí a sì nàmọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ lọna àpẹẹrẹ. Wọn dabi òwú àtùpà ọlọ́gbọ̀ kan tí ńjó lọ́úlọ́ú, tí a ti fẹrẹẹ fi afẹfẹ du ẹ̀ṣẹ́ iná rẹ̀ ti o kẹhin. Jesu kò tẹ esùsú tí a halára fọ́ tabi pa iná ọ̀gbọ̀ tí ńjó bàìbàì. Ṣugbọn pẹlu pẹ̀lẹ́tù ati ìfẹ́, oun fi pẹlu ìjáfáfá gbé awọn onínútútù sókè. Nitootọ, Jesu ni ẹni naa ninu ẹni tí awọn orílẹ̀-èdè lè ní ìrètí! Matiu 12:15-21; Maaku 3:7-12; Aisaya 42:1-4.

▪ Bawo ni Jesu ṣe mú ìdájọ́ òdodo ṣe kedere, láìṣe awuyewuye tabi gbé ohùn rẹ̀ sókè ní awọn ọ̀nà fífẹ̀?

▪ Awọn wo ni wọn dabi esùsú kan tí a halára ati òwú àtùpà ọlọ́gbọ̀, bawo sì ni Jesu ṣe hùwàsì wọn?