Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ní Àjọ-àríyá Awọn Àgọ́-ìsìn

Ní Àjọ-àríyá Awọn Àgọ́-ìsìn

Orí 66

Ní Àjọ-àríyá Awọn Àgọ́-ìsìn

JESU ti di olókìkí láàárín ohun tí ó fẹrẹẹ tó ọdun mẹta lati ìgbà baptism rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹrun eniyan ti rí awọn iṣẹ́-ìyanu rẹ̀, ìròhìn nipa awọn ìgbòkègbodò rẹ̀ sì ti tànkálẹ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè naa. Nisinsinyi, bí awọn eniyan ti kórajọ fun Àjọ-àríyá Awọn Àgọ́-ìsìn ní Jerusalẹmu, wọn ńwá a kiri nibẹ. “Nibo ni [ọkunrin] yẹn wà?” wọn fẹ́ lati mọ̀.

Jesu ti di ẹnikan ti àríyànjiyàn dale lori. “Eniyan daradara ni,” ni awọn kan wí. “Kò rí bẹẹ, ṣugbọn ó ńṣi ogunlọgọ lọ́nà,” ni awọn miiran kéde. Ọpọlọpọ awọn ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ bíi irú eyi ni ó wà nígbà awọn ọjọ akọkọ àjọ-àríyá naa. Sibẹ kò sí ẹnikẹni tí ó ní ìgboyà lati sọ̀rọ̀ jáde ní gbangba nitori Jesu. Eyi jẹ́ nitori pe awọn eniyan naa bẹ̀rù ìyáró lati ọ̀dọ̀ awọn aṣaaju Juu.

Nigba ti àjọ-àríyá naa dé ìdajì, Jesu dé. Ó gòkè lọ sí tẹmpili, níbi tí kayefi ti ṣe awọn eniyan nitori agbára-ìṣe ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yíyanilẹ́nu rẹ̀. Niwọn ìgbà tí Jesu kò ti lọ sí awọn ilé-ẹ̀kọ́ rabi rí, awọn Juu bẹrẹsii ṣe kàyéfì pe: “Bawo ni ọkunrin yii ṣe ní ìmọ̀ ìwé, nigba ti kò kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìwé?”

“Ohun tí emi fi ńkọ́ni kii ṣe temi,” ni Jesu ṣàlàyé, “bikoṣe ti ẹni tí ó rán mi. Bí ẹnikẹni bá fẹ́ ṣe ìfẹ́-inú Rẹ̀, oun yoo mọ̀ nipa ẹ̀kọ́ naa boya ó wá lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun tabi emi ńsọ̀rọ̀ lati inú àpilẹ̀ṣe ti araami.” Awọn ẹ̀kọ́ Jesu rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ òfin Ọlọrun. Nipa bẹẹ, ó yẹ kí ó ṣe kedere pe oun ńwá ògo Ọlọrun, kii ṣe tirẹ̀. “Mose fun yin ní Òfin, oun kò ha ṣe bẹẹ bí?” ni Jesu beere. Lọna ìbáwí, oun wipe: “Kò sí ẹnikan ninu yin tí ó ńṣe ìgbọràn sí Òfin naa.”

“Eeṣe tí ẹ fi ńwá ọ̀nà lati pa mi?” ni Jesu beere lẹhin naa.

Awọn eniyan ninu ogunlọgọ naa, tí ó ṣeeṣe kí wọn jẹ́ awọn olùbẹ̀wò sí àjọ-àríyá naa, kò mọ nipa irú ìsapá bẹẹ. Wọn kà á sí ohun ti kò ṣeeṣe pe ẹnikẹni yoo fẹ́ lati pa irúfẹ́ àgbàyanu olùkọ́ bẹẹ. Nitori naa wọn pari rẹ̀ si pe nǹkan gbọdọ maa ṣe Jesu lati ronú eyi. “Iwọ ní ẹ̀mí-èṣù,” ni wọn wí. “Ta ni ńwá ọ̀nà lati pa ọ́?”

Awọn aṣaaju Juu ńfẹ́ kí a pa Jesu, ani bí ó tilẹ jẹ́ pe ogunlọgọ naa lè ma mọ eyi. Nigba ti Jesu mú ọkunrin kan láradá ní Sabaati ní ọdun kan ati aabọ ṣaaju, awọn aṣaaju naa gbìyànjú lati pa á. Nitori naa Jesu mú ailọgbọnninu wọn ṣe kedere sí i nisinsinyi nipa bíbèèrè lọwọ wọn pe: “Bí ẹ bá ṣe ìkọlà fun eniyan kan ní Sabaati kí a maa bá rú òfin Mose, ẹyin ha bínú sí mi nitori mo mú ọkunrin kan láradá ṣáṣá ní sabaati? Ẹ dẹ́kun ṣíṣèdájọ́ nipa ìrísí òde, ṣugbọn ẹ maa fi ìdájọ́ òdodo ṣe ìdájọ́.”

Awọn olùgbé Jerusalẹmu, tí wọn mọ̀ nipa ọ̀ràn naa, sọ nisinsinyi pe: “Ọkunrin tí wọn ńwá-ọ̀nà lati pa niyii, oun ha kọ́? Sibẹsibẹ, ẹ wòó! ó sì ńsọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì lè rí ohunkohun sí i. Awọn alákòósò kò tíì mọ̀dájú pe eyi ni Kristi naa, wọn ha ti mọ eyi bí?” Awọn olùgbé Jerusalẹmu wọnyi ṣàlàyé ìdí tí wọn kò fi gbàgbọ́ pe Jesu ni Kristi naa: “Awa mọ ibi tí ọkunrin yii ti wá; sibẹsibẹ nigba ti Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yoo mọ ibi tí ó ti wá.”

Jesu dáhùn pe: “Ẹ mọ̀ mi ẹ sì tún mọ ibi tí mo ti wá. Pẹlupẹlu, emi kò wá nipa àtinúdá ti araami, ṣugbọn ẹni tí ó rán mi jẹ́ otitọ-gidi kan, ẹyin kò sì mọ̀ ọ́n. Emi mọ̀ ọ́n, nitori aṣojú lati ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni emi, Ẹni yẹn ni ó sì rán mi jáde wá.” Pẹlu eyi wọn gbìyànjú lati gbá a mú, boya lati fi sínú ẹ̀wọ̀n tabi lati jẹ́ kí wọn pa á. Sibẹ, wọn kò ṣàṣeyọrí sí rere nitori pe kò tii to àkókò fun Jesu lati kú.

Sibẹ, ọpọlọpọ ní ìgbàgbọ́ ninu Jesu, bí ó ti yẹ kí wọn ṣe niti tootọ. Họwu, oun ti rìn lórí omi, ó mu ki ẹ̀fúùfù parọ́rọ́, ó fi iṣẹ́-ìyanu bọ́ ẹgbẹẹgbẹrun lórí awọn ìṣù ati ẹja diẹ, ó wo awọn aláìsàn sàn, ó mú awọn arọ rìn, ó la ojú awọn afọ́jú, ó wo awọn adẹ́tẹ̀ sàn, ó tilẹ jí òkú dìde. Nitori naa wọn beere pe: “Nigba ti Kristi bá dé, oun kì yoo ṣe iṣẹ́-àmì tí ó pọ̀ju eyi tí ọkunrin yii ti ṣe, oun yoo ṣe bẹẹ bí?”

Nigba ti awọn Farisi gbọ́ tí ogunlọgọ naa ńkùn lórí awọn nǹkan wọnyi, awọn ati awọn olórí alufaa rán awọn òṣìṣẹ́ olóyè jáde lati fàṣẹ ọba mú Jesu. Johanu 7:11-32, NW.

▪ Nigba wo ni Jesu dé sí àjọ-àríyá naa, ọ̀rọ̀ wo sì ni awọn eniyan ńsọ nipa rẹ̀?

▪ Eeṣe tí ó fi jẹ́ pe awọn kan nsọ pe Jesu ní ẹ̀mí-èṣù?

▪ Ojú ìwòye nipa Jesu wo ni awọn olùgbé Jerusalẹmu ní?

▪ Eeṣe tí ọpọlọpọ fi ní ìgbàgbọ́ ninu Jesu?