Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ní Bẹtani, ní Ilé Simoni

Ní Bẹtani, ní Ilé Simoni

Orí 101

Ní Bẹtani, ní Ilé Simoni

NIGBA ti Jesu fi Jẹriko silẹ, ò forílé Bẹtani. Ìrìn àjò naa fẹrẹẹ gbà gbogbo ọjọ́ naa, niwọn bi ó ti jẹ́ gígùn òkè fun nǹkan bii ibùsọ̀ 12 rekọja àgbègbè tí ó ṣòro. Jẹriko fi nǹkan bii 820 ẹsẹ̀-bàtà lọsílẹ̀ jù ìtẹ́bẹẹrẹ ojú omi òkun, Bẹtani sì fi nǹkan bii 2,500 ẹsẹ̀-bàtà ga jù ìtẹ́bẹẹrẹ ojú omi òkun lọ. Iwọ lè rántí pé Bẹtani ni ilé Lasaru ati awọn arabinrin rẹ̀. Abúlé kékeré naa wà ní nǹkan bii ibùsọ̀ meji sí Jerusalẹmu, niwọn bi ó ti wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá ìlà-oòrùn Òkè Olifi.

Ọpọlọpọ ti dé sí Jerusalẹmu bayii fun Ìrékọjá naa. Wọn ti tètè dé lati wá wẹ̀ araawọn mọ́ lọna ayẹyẹ. Bóyá wọn ti fọwọ́kàn òkú tabi wọn ti ṣe ohun mìíràn kan tí ó sọ wọn di aláìmọ́. Nitori naa wọn tẹ̀lé awọn ìlànà lati wẹ̀ araawọn mọ́ kí wọn lè ṣayẹyẹ Ìrékọjá lọna itẹwọgba. Bí awọn tí ó kọ́kọ́ dé wọnyi ti ńkórajọ sí tẹmpili, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ńméfòó nipa boya Jesu yoo wá sí Ìrékọjá naa.

Jerusalẹmu jẹ́ agbegbe ọlọ́ràá fun àríyànjiyàn nipa Jesu. Gbogbo awọn eniyan ti wá mọ̀ pé awọn aṣaaju isin fẹ́ lati gbá a mú kí wọn sì pa á. Nitootọ, wọn ti pàṣẹ pé bí ẹnikẹni bá mọ̀ ibi ti ó wà, ó gbọ́dọ̀ fi tó wọn létí. Igba mẹta ninu awọn oṣu àìpẹ́ yii—nibi Àjọ-àríyá Awọn Àgọ́-ìsìn, níbi Àjọ-àríyá Ìyàsímímọ́, ati lẹhin ti o jí Lasaru dìde—awọn aṣaaju wọnyi ti gbiyanju lati pa á. Nitori naa, awọn eniyan naa ṣe kàyéfì pé, Jesu yoo ha tún fi araarẹ̀ hàn ní ojútáyé nigba miiran síbẹ̀? “Ki ni èrò tìrẹ?” ni wọn ńbi araawọn ẹnìkínní ẹnikeji.

Láàárín akoko naa, Jesu dé sí Bẹtani ní ọjọ́ mẹfa ṣaaju Ìrékọjá naa, eyi ti ó bọ́ sí Nisan 14 ní ìbámu pẹlu kalẹnda awọn Juu. Jesu dé sí Bẹtani ní ìrọ̀lẹ́ Friday, eyi ti ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ Nisan 8. Kò lè jẹ́ Saturday ni ó rìn ìrìn àjò naa wá sí Bẹtani nitori pe ìrìnnà àjò ní Sabaati—lati ìgbà wíwọ̀ oòrùn ní Friday títí di ìgbà wíwọ̀ oòrùn ní Saturday—ni òfin awọn Juu ká lọ́wọ́kò. O ṣeeṣe kí Jesu ti lọ sí ilé Lasaru, gẹgẹ bi oun ti ṣe rí, kí ó sì ti lò alẹ́ Friday nibẹ.

Bí ó ti wù kí ó rí, olùgbé Bẹtani miiran késí Jesu ati awọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ fun ounjẹ ní alẹ́ Saturday. Ọkunrin naa ni Simoni, adẹ́tẹ̀ kan tẹ́lẹ̀rí, ti ó ṣeeṣe kí Jesu ti mú láradá ṣáájú igba naa. Ní ìbámu pẹlu ànímọ́ rẹ̀ ti jíjẹ́ alákitiyan, Mata ńṣèránṣẹ́ fun awọn àlejò naa. Ṣugbọn, gẹgẹ bi ó ti máa ńrí, Maria fiyèsílẹ̀ sí Jesu, ní akoko yii ní ọ̀nà tí ó ru àríyànjiyàn sókè.

Maria ṣí òrùba tabi ṣágo alabasita kékeré kan, tí ó gbà nǹkan bii ìwọ̀n pound kan òróró onílọ́fínńdà, “ojúlówó naadi.” Eyi ṣeyebíye gidigidi. Nitootọ, iniyelori rẹ̀ bá nǹkan bí owó-ọ̀yà ọdún kan dọ́gba! Nigba ti Maria tú òróró naa dà sórí Jesu ati sórí ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó sì ńfi irun rẹ̀ nù ẹsẹ̀ rẹ̀, òórùn títasánsán rẹ̀ kún gbogbo ilé naa.

Awọn ọmọ-ẹhin bínú wọn sì beere pé: “Ki ni ìdí fun ìfiṣòfò yii?” Lẹhin naa ni Judasi Isikariọtu wipe: “Eeṣe tí a kò fi ta òróró onílọ́fínńdà yii fun ọ̀ọ́dúnrún dinari kí a sì fi fun awọn òtòṣì eniyan?” Ṣugbọn Judasi kò dàníyàn niti gidi nipa awọn òtòṣì, nitori pe oun ti ńjí ninu owó àpótí tí awọn ọmọ-ẹhin ńpamọ́.

Jesu gbèjà Maria. “Ẹ jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́,” ni ó pàṣẹ. “Èéṣe tí ẹ fi ngbiyanju lati wá ìjàngbọ̀n fun un? Ó ṣe iṣẹ rere kan fun mi. Nitori ẹyin ní awọn òtòṣì pẹlu yin nigba gbogbo, nigba yoowu tí ẹ bá sì fẹ ẹyin lè ṣoore fun wọn, ṣugbọn emi ni ẹ kò ní nigba gbogbo. O ṣe ohun tí ó lè ṣe; o dáwọ́lé ṣaaju akoko lati fi òróró olóòórùn dídùn sí ara mi fun isinku mi. Lóòótọ́ ni mo wí fun yin, Ibi yoowu tí a bá waasu ihinrere yii ní gbogbo ayé, ohun tí obinrin yii ṣe ni a o sọ pẹlu gẹgẹ bi iranti rẹ̀.”

Jesu ti wà ní Bẹtani nisinsinyi fun ohun tí ó jù wakati 24, ọ̀rọ̀ nipa wíwàníbẹ̀ rẹ̀ sì ti tàn kaakiri. Nitori naa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí ilé Simoni lati rí Jesu, ṣugbọn wọn tún wá pẹlu lati rí Lasaru. Nitori naa awọn olórí àlùfáà gbìmọ̀pọ̀ lati pa kìí ṣe Jesu nikan ṣugbọn Lasaru pẹlu. Eyi jẹ́ nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ eniyan nfi igbagbọ hàn ninu Jesu nitori pe wọn rí ẹni ti oun ti jí dìde kuro ninu òkú! Ẹ wo bí awọn aṣaaju isin wọnyi ti jẹ́ eniyan burúkú tó nitootọ! Johanu 11:55–12:11, NW; Matiu 26:6-13; Maaku 14:3-9; Iṣe 1:12.

▪ Ijiroro wo ni ó ńlọ lọ́wọ́ ní tẹmpili, eesitiṣe?

▪ Eeṣe ti Jesu ti fi nilati dé sí Bẹtani ní Friday kàkà kí ó jẹ́ Saturday?

▪ Nigba ti Jesu dé sí Bẹtani, nibo ni ó ṣeeṣe kí ó ti lò Sabaati?

▪ Ìṣe Maria wo ni ó ru àríyànjiyàn sókè, bawo sì ni Jesu ṣe gbèjà rẹ̀?

▪ Ki ni ó ṣàkàwé ìwà burúkú ńláǹlà awọn olórí àlùfáà naa?