Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ni Ọwọ́ Ọtun Ọlọrun

Ni Ọwọ́ Ọtun Ọlọrun

Orí 132

Ni Ọwọ́ Ọtun Ọlọrun

TÍTÚ ẹmi mimọ jade ni Pẹntikọsi jẹ ẹri pe Jesu ti pada de ọrun. Iran ti a fifun ọmọ-ẹhin naa Stefanu ni kete lẹhin naa tun fi ẹri han pe Oun ti de si ibẹ. Ní kete ṣaaju ki wọn tó sọ ọ ni okuta fun ijẹrii igbagbọ rẹ, Stefanu kigbe soke pe: “Wòó, mo ri ọrun ṣí silẹ, ati Ọmọ eniyan [“Ọmọkunrin eniyan,” NW] nduro ni ọwọ ọtun Ọlọrun.”

Nigba ti o wa ni ọwọ ọtun Ọlọrun, Jesu duro de aṣẹ lati ọdọ Baba rẹ pe: “Iwọ jọba laaarin awọn ọta rẹ.” Ṣugbọn laaarin akoko naa, titi di igba ti oun yoo gbe igbesẹ lodisi awọn ọta rẹ, ki ni Jesu nṣe? Oun nṣakoso, tabi jọba, lori awọn ọmọ-ẹhin rẹ ti a fàmì ororo yan, ni titọ wọn sọna ninu igbokegbodo ijẹrii wọn ati mimura wọn silẹ lati di ọba àjùmọ̀jẹ́ pẹlu rẹ ninu Ijọba Baba rẹ nipa ajinde.

Fun apẹẹrẹ, Jesu yan Sọọlu (ti a wa mọ daradara lẹhin naa nipa orukọ Roomu rẹ, Pọọlu) lati ṣe òléwájú ninu iṣẹ sisọni di ọmọ-ẹhin ni awọn ilẹ miiran. Sọọlu jẹ onitara fun Òfin Ọlọrun, sibẹ oun ni a mú ṣìnà nipasẹ awọn aṣaaju isin Juu. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, kii ṣe kiki pe Sọọlu lọwọ si pipa Stefanu nikan ni ṣugbọn oun lọ si Damasku pẹlu iwe-aṣẹ lati ọwọ alufaa agba Kaifa lati mú awọn ọkunrin ati obinrin eyikeyi ti oun ri nibẹ ti wọn jẹ ọmọlẹhin Jesu pada wa si Jerusalẹmu labẹ ifaṣẹ ọba muni. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti Sọọlu wà loju ọna, imọlẹ titan yoo kan kọmànà yi i ka lojiji, o si ṣubu lulẹ.

Ohùn kan lati orisun aiṣeefojuri kan beere pe, “Sọọlu, Sọọlu, eeṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi?” Sọọlu beere pe, “Iwọ ta ni, Oluwa?”

Idahun naa wa pe, “Emi Jesu ni, ẹni ti iwọ nṣe inunibini si.”

Sọọlu, ẹni ti a ti bùfọ́jú lù nipasẹ imọlẹ agbayanu naa, ni Jesu sọ fun lati wọ Damasku lọ ki o si duro de awọn itọni. Lẹhin naa Jesu farahan ninu iran si Ananaya, ọkan lara awọn ọmọ-ẹhin rẹ. Nipa Sọọlu, Jesu sọ fun Ananaya pe: “Ohun eelo aayo ni oun jẹ fun mi, lati gbé orukọ mi lọ si iwaju awọn Keferi, ati awọn ọba, ati awọn ọmọ Isirẹli.”

Nitootọ, pẹlu itilẹhin Jesu, Sọọlu (ti a mọ nisinsinyi si Pọọlu) ati awọn ajihinrere miiran rí agbayanu aṣeyọri si rere ninu iṣẹ wiwaasu ati kikọni wọn. Niti tootọ, ni nǹkan bi 25 ọdun lẹhin ifarahan Jesu si i loju ọna si Damasku, Pọọlu kọwe pe “ihinrere” naa ni a ti “waasu rẹ ninu gbogbo ẹda ti nbẹ labẹ ọrun.”

Lẹhin ti ọpọlọpọ awọn ọdun ti kọja sii, Jesu pese ọ̀wọ́ awọn iran fun apọsiteli aayo olufẹ rẹ, Johanu. Nipasẹ awọn iran wọnyii ti Johanu ṣapejuwe ninu iwe Bibeli Iṣipaya, oun, nitori eyi, wàláàyè lati ri ipadabọ Jesu ninu agbara Ijọba. Johanu wipe “ninu ẹmi” a gbe oun rin siwaju ninu akoko lọ si “ọjọ Oluwa.” Ki ni “ọjọ” yii?

Ikẹkọọ kínníkínní nipa awọn asọtẹlẹ Bibeli, ti o ni asọtẹlẹ Jesu funraarẹ nipa awọn ọjọ ikẹhin ninu, ṣipaya pe “ọjọ Oluwa” bẹrẹ ni ọdun ọlọrọ itan naa 1914, bẹẹni, laaarin iran yii! Nitori naa 1914 ni Jesu padabọ lọna aiṣeefojuri, laisi afẹfẹyẹ̀yẹ̀ itagbangba ti o si jẹ pe kiki awọn iranṣẹ rẹ oluṣotitọ ni wọn mọ nipa ipadabọ rẹ. Ni ọdun yẹn Jehofa fun Jesu laṣẹ lati maa jọba laaarin awọn ọta rẹ!

Ni ṣiṣegbọran si aṣẹ Baba rẹ, Jesu fọ ọrun mọ́ kuro lọwọ Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ, ni fifi wọn sọ̀kò si ilẹ-aye. Lẹhin riri i pe eyi ṣẹlẹ ninu iran, Johanu gbọ ohùn ọrun kan ti o pokiki pe: “Nigba yii ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọla ti Kristi rẹ.” Bẹẹni, ni 1914 Kristi bẹrẹ sii ṣakoso gẹgẹ bi Ọba!

Iru ihinrere wo ni eyi jẹ fun awọn olujọsin Jehofa ni ọrun! A rọ̀ wọn pe: “Ẹ maa yọ̀, ẹyin ọrun, ati ẹyin ti ngbe inu wọn.” Ṣugbọn ki ni ipo naa fun awọn wọnni ti wọn wa lori ilẹ-aye? Ohùn naa lati ọrun nbaa lọ pe: “Ègbé ni fun aye ati fun okun! nitori Eṣu sọkalẹ tọ yin wa ni ibinu nla, nitori o mọ pe igba kukuru ṣaa ni oun ni.”

A wà ni saa akoko kukuru yẹn gan-an nisinsinyi. Awọn eniyan ni a nya sọtọ ni lọwọlọwọ yala lati wọnu aye titun ti Ọlọrun tabi lati jiya iparun. Otitọ naa ni pe, kádàrá tirẹ funraarẹ ni a npinnu nisinsinyi nipa bi iwọ ti dahunpada si ihinrere Ijọba Ọlọrun ti a nwaasu rẹ̀ yika ilẹ-aye labẹ idari Kristi.

Nigba ti yiya awọn eniyan sọtọ ba ti pari, Jesu Kristi yoo ṣiṣẹ gẹgẹ bi Aṣoju Ọlọrun lati dá ilẹ-aye silẹ lominira kuro lọwọ gbogbo eto igbekalẹ awọn nǹkan ti Satani ati gbogbo awọn wọnni ti wọn tii lẹhin. Jesu yoo ṣaṣepari imukuro gbogbo iwa buruku yii ninu ogun ti a npe ni Ha-Magẹdọn, tabi Amagẹdọn, ninu Bibeli. Lẹhin naa, Jesu, ti o jẹ Ẹni titobilọla julọ ni agbaye tẹle Jehofa Ọlọrun funraarẹ, yoo gbá Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ mú yoo si dè wọn fun ẹgbẹrun ọdun ninu “ọgbun,” iyẹn ni, ipo alaiṣiṣẹ bi oku. Ise 7:55-60; 8:1-3; 9:1-19; 16:6-10; Saamu 110:1, 2; Heberu 10:12, 13; 1 Peteru 3:22; Luuku 22:28-30; Kolose 1:13, 23; Iṣipaya 1:1, 10; 12:7-12; Iṣi 16:14-16; 20:1-3; Matiu 24:14; 25:31-33.

▪ Lẹhin ti Jesu goke lọ si ọrun, ibo ni o wa, ki ni o si nduro de?

▪ Lori awọn wo ni Jesu nṣakoso lẹhin ti o goke re ọrun, bawo si ni a ṣe fi iṣakoso rẹ han?

▪ Nigba wo ni “ọjọ Oluwa” bẹrẹ, ki ni o si ṣẹlẹ ni ibẹrẹ rẹ?

▪ Iṣẹ iyasọtọ wo ti ntẹsiwaju lonii ni o kan wa gẹgẹ bi ẹnikọọkan, lori ipilẹ wo si ni a fi nṣe iyasọtọ naa?

▪ Nigba ti iṣẹ iyasọtọ naa ba pari, awọn iṣẹlẹ wo ni yoo tẹle e?