Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nigba Ti A Bá Ṣí Ọmọkunrin Ènìyàn Payá

Nigba Ti A Bá Ṣí Ọmọkunrin Ènìyàn Payá

Orí 93

Nigba Ti A Bá Ṣí Ọmọkunrin Ènìyàn Payá

NIGBA ti Jesu ṣì wà ní àríwá sibẹ (yálà ní Samaria tabi ní Galili), awọn Farisi beere nipa dídé Ijọba naa lọwọ rẹ̀. Wọn gbàgbọ́ pe yoo dé pẹlu àṣehàn ati ayẹyẹ ńlá, ṣugbọn Jesu wipe: “Ijọba Ọlọrun kì yoo dé pẹlu ṣíṣeékíyèsí tí ńpàfiyèsí, bẹẹ ni awọn eniyan kì yoo maa wipe, ‘Wòó nihin-in!’ tabi, ‘Lọhun-un!’ Nitori, kiyesii! ijọba Ọlọrun ńbẹ láàárín yin.”

Awọn ọ̀rọ̀ Jesu “láàárín yin” ni a ti túmọ̀ nigba miiran sí “ninu yin.” Nitori naa awọn kan ti rò pe Jesu ní in lọ́kàn pe Ijọba Ọlọrun ńṣàkóso ninu ọkàn-àyà awọn iranṣẹ Ọlọrun. Ṣugbọn lọna ti o hàn gbangba, Ijọba Ọlọrun kò sí ninu ọkàn-àyà awọn Farisi aláìgbàgbọ́ wọnyi awọn ẹni tí Jesu ńbá sọ̀rọ̀. Sibẹ ijọba naa wà láàárín wọn, niwọn bi Ọba Ijọba Ọlọrun ti a yansipo naa, Jesu Kristi, ti ńbẹ láàárín wọn gan-an.

O ṣeeṣe ki o jẹ́ pe lẹhin tí awọn Farisi ti kúrò ni Jesu tó sọ̀rọ̀ siwaju sí i pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nipa dídé Ijọba naa. Ohun tí ó ní lọ́kàn ní pataki ni wíwàníhìn-ín rẹ̀ lẹhin-ọla ninu agbára Ijọba nigba ti ó kìlọ̀ pe: “Awọn ènìyàn yoo sì wí fun yin, ‘Ẹ wòó lọhun-un!’ tabi, ‘Ẹ wòó nihin-in!’ Ẹ maṣe jade lọ tabi sare tẹle [awọn Mesaya èké wọnyi]. Nitori ani gẹgẹ bi mànàmáná, nipasẹ ìkọmànà rẹ̀, ti ńtàn lati apa kan labẹ ọ̀run de apa miiran lábẹ́ ọ̀run, bẹẹ gẹgẹ ni Ọmọkunrin ènìyàn yoo rí.” Nipa bẹẹ, Jesu fihàn pe gan-an gẹgẹ bi a ti ńrí mànàmáná kárí àgbègbè gbígbòòrò kan, ẹ̀rí wíwàníhìn-ín rẹ̀ ninu agbára Ijọba yoo ṣeérí kedere fun gbogbo awọn ẹni tí ńdàníyàn lati fi ìṣọ́ra kíyèsí i.

Lẹhin naa ni Jesu ṣe awọn ìfiwéra pẹlu awọn ìṣẹ̀lẹ̀ igbaani lati fihàn ohun tí ẹ̀mí-ìrònú awọn ènìyàn yoo jẹ́ lákòókò wíwàníhìn-ín rẹ̀ lẹhin-ọla. Ó ṣàlàyé pe: “Ju bẹẹ lọ, gan-an gẹgẹ bi ó ti ṣẹlẹ ni awọn ọjọ́ Noa, bẹẹ gẹgẹ ni yoo rì ní awọn ọjọ́ Ọmọkunrin ènìyàn . . . Bẹẹ gẹgẹ, gan-an bi o ti ṣẹlẹ ni awọn ọjọ́ Lọọti; wọn ńjẹ, wọn ńmu, wọn ńrà, wọn ńtà, wọn ńgbìn, wọn ńkọ́lé. Ṣugbọn ní ọjọ́ naa tí Lọọti jáde kuro ní Sodomu, iná ati imí-ọjọ́ rọ̀ lati ọ̀run wá, ó sì pa gbogbo wọn run. Bakan naa ni yoo jẹ́ ní ọjọ́ yẹn tí a ó ṣí Ọmọkunrin eniyan payá.”

Kii ṣe ohun tí Jesu ńsọ ni pe awọn ènìyàn ọjọ́ Noa ati ti Lọọti ni a parun kìkì nitori pe wọn ńlépa awọn ìgbòkègbodò tí wọn wà déédéé ti jíjẹ, mímu, rírà, títà, gbígbìn, ati kíkọ́lé. Kódà Noa ati Lọọti ati awọn idile wọn ṣe awọn nǹkan wọnyi. Ṣugbọn awọn yooku nba awọn ìgbòkègbodò ojoojumọ wọnyi lọ láìfi àfiyèsí kankan fun ìfẹ́-inú Ọlọrun, ati nitori ìdí eyi ni a ṣe pa wọn run. Nitori ìdí kan naa, awọn eniyan ni a ó parun nigba ti a bá ṣí Kristi payá lákòókò ìpọ́njú ńlá lórí ètò ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii.

Ní títẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì dídáhùnpadà kiakia sí àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ lẹhin-ọla ninu agbára Ijọba, Jesu fikun un pe: “Ní ọjọ́ yẹn, ki ẹni naa ti o wà ni orule ṣugbọn ti awọn nnkan rẹ̀ ti wọn ṣeé gbé wà ninu ile maṣe sọkalẹ wá lati gbé awọn wọnyi, ati ki ẹni naa ti o wà ni pápá pẹlu maṣe pada si awọn nnkan ti nbẹ lẹhin. Ẹ ranti aya Lọọti.”

Nigba ti ẹ̀rí wíwàníhìn-ín Kristi bá farahàn, awọn eniyan kò lè jẹ́ kí ìsomọ́ wọn pẹlu awọn ohun-ìní ti ara dí wọn lọwọ lati gbé ìgbésẹ̀ ní kánmọ́. Bí ó ti ńjáde lọ kuro ní Sodomu, ó farahàn bí ẹni pe aya Lọọti wẹ̀hìn pẹlu aáyun fun awọn ohun tí ó ti fi sílẹ̀ sẹhin, o sì di ọwọ̀n iyọ̀.

Ní bíbá apejuwe rẹ̀ lọ nipa ipò tí yoo wà lákòókò wíwàníhìn-ín rẹ̀ lẹhin-ọla, Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Ní òru yẹn, ọkunrin meji yoo wà lórí ibusun kan; a ó mú ọ̀kan dání lọ, ṣugbọn a ó pa ekeji tì. Obinrin meji yoo wà ti wọn nlọ nnkan nidii ọlọ kan naa; a ó mú ọ̀kan dani lọ, ṣugbọn a ó pa èkejì tì.”

Mímú tí a múni lọ naa ṣerẹ́gí pẹlu wíwọ̀ tí Noa wọ inú aaki pẹlu idile rẹ̀ ati mímú tí awọn angẹli mú Lọọti ati idile rẹ̀ jáde kuro ní Sodomu. Ó tumọsi ìgbàlà. Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, pípa tí a pa ẹnikan tì tumọsi jíjìyà iparun.

Ní ọgangan yii, awọn ọmọ-ẹhin beere pe: “Nibo, Oluwa?”

“Níbi tí òkú bá wà, nibẹ ni awọn idì ńkójọpọ̀ sí pẹlu,” ni Jesu dáhùn. Awọn wọnni ‘tí a mú lọ’ fun ìgbàlà dabi awọn idì ti nriran jinna niti pe wọn kórajọpọ̀ sí ọ̀dọ̀ “òkú” naa. Òkú naa ńtọ́kasí Kristi tootọ nigba wíwàníhìn-ín rẹ̀ aláìṣeérí ninu agbára Ijọba ati sí àsè tẹ̀mí tí Jehofa pèsè. Luuku 17:20-37; Jẹnẹsisi 19:26.

▪ Bawo ni Ijọba naa ṣe wà láàárín awọn Farisi?

▪ Ní ọ̀nà wo ni wíwàníhìn-ín Kristi fi dabi mànàmáná?

▪ Eeṣe tí a ó fi pa awọn eniyan run fun ìṣesí wọn lákòókò wíwàníhìn-ín Kristi?

▪ Ki ni ó tumọsi lati jẹ́ ẹni tí a múlọ, ati ẹni tí a patì?