Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nigba Ti A Jí Lasaru Dìde

Nigba Ti A Jí Lasaru Dìde

Orí 91

Nigba Ti A Jí Lasaru Dìde

JESU pẹlu awọn tí wọn bá a rìn, dé sí ibi ibojì iranti Lasaru nisinsinyi. Niti tootọ, ó jẹ́ ihò inú àpáta kan pẹlu òkúta kan tí a fi dí ẹnu ọ̀nà. “Ẹ gbé òkúta naa kuro,” ni Jesu wí.

Mata takò ó, ní ṣíṣàìlóye ohun tí Jesu ńgbèrò lati ṣe sibẹ. “Oluwa,” ni obinrin naa wí, “ó ti ńrùn nisinsinyi: nitori pe ó ti di ọjọ́ mẹrin.”

Ṣugbọn Jesu beere pe: “Emi kò ti wí fun ọ pé, bí iwọ bá gbàgbọ́, iwọ yoo rí ògo Ọlọrun?”

Nitori naa wọn gbe òkúta naa kuro. Lẹhin naa Jesu gbé ojú rẹ̀ sókè ó sì gbàdúrà pe: “Bàbá, mo dúpẹ́ lọwọ rẹ, nitori tí iwọ gbọ́ ti emi. Emi sì ti mọ̀ pe, iwọ a maa gbọ́ ti emi nigba gbogbo: ṣugbọn nitori ijọ ènìyàn tí ó dúró yii ni mo ṣe wí i, kí wọn kí ó lè gbàgbọ́ pe iwọ ni ó rán mi.” Jesu gbàdúrà ní gbangba kí awọn ènìyàn kí ó lè mọ̀ pe ohun tí oun yoo ṣe láìpẹ́ sí àkókò naa ni yoo ṣeeṣe nipasẹ agbára tí ó rígbà lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Lẹhin naa ni ó kígbe jáde pẹlu ohùn rara pe: “Lasaru, jáde wá!”

Loju ẹsẹ, Lasaru jáde wá. Ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ ṣì wà ní dídì sibẹ pẹlu awọn ọjá ìsìnkú, aṣọ kan sì bò ojú rẹ̀. “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó maa lọ,” ni Jesu wí.

Nigba tí wọn rí iṣẹ́ ìyanu naa, ọ̀pọ̀ awọn Juu tí wọn ti wá lati tù Maria ati Mata ninu lò ìgbàgbọ́ ninu Jesu. Awọn miiran, bí ó ti wù kí ó rí, lọ lati sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fun awọn Farisi. Awọn ati awọn olórí alufaa lẹsẹkẹsẹ ṣètò fun ipade ilé ẹjọ́ gíga ti awọn Juu, Sanhẹdrin.

Sanhẹdrin naa ní ninu alufaa àgbà lọwọlọwọ, Kaifa, ati bakan naa awọn Farisi ati awọn Sadusi, olórí alufaa, ati awọn alufaa àgbà ti tẹlẹri. Awọn wọnyi dárò pe: “Ki ni awa ńṣe nitori ọkunrin yii ńṣe ọpọlọpọ iṣẹ́-àmì? Bí awa bá fi i silẹ ni ọna yii, gbogbo ènìyàn yoo fi igbagbọ hàn ninu rẹ̀, awọn ara Roomu yoo sì wá, wọn yoo sì gbà ilẹ̀ ati orílẹ̀-èdè wa pẹlu.”

Bí ó tilẹ jẹ́ pe awọn aṣaaju-isin naa gbà pe Jesu ‘ńṣe ọ̀pọ̀lọpọ iṣẹ́-àmì,’ ohun kanṣoṣo tí wọn ńdàníyàn nipa rẹ̀ ni ipò ati ọlá-àṣẹ tiwọn fúnraawọn. Jíjí tí a jí Lasaru dìde jẹ́ àgbálù alágbára fun awọn Sadusi, niwọn bi wọn kò ti gbà ajinde gbọ́.

Kaifa, tí ó ṣeeṣe kí ó jẹ́ Sadusi kan, sọ̀rọ̀ jáde nisinsinyi, ní wiwi pe: “Ẹyin kò mọ ohunkohun rárá. Bẹẹ ni ẹ kò sì ronú pe, ó ṣàǹfààní fun wa, kí eniyan kan kú fun awọn eniyan, kí gbogbo orílẹ̀-èdè kí ó ma baa ṣègbé.”

Ọlọrun darí Kaifa lati sọ eyi, nitori apọsiteli Johanu sọ lẹhin naa pe: “Oun [Kaifa] kò sọ ninu idanuṣe ti araarẹ̀, bi o ti wu ki o ri.” Ohun tí Kaifa ní lọ́kàn niti tootọ ni pe ó yẹ kí a pa Jesu ki o ma baa ṣeeṣe fun Un lati jìn ipò ọlá-àṣẹ ati agbára ìdarí wọn lẹ́sẹ̀ siwaju sí i. Sibẹ, gẹgẹ bi Johanu ti wí, ‘Kaifa sọtẹlẹ pe Jesu ni a ti kádàrá lati kú kii ṣe fun orílẹ̀-èdè naa nikan, ṣugbọn kí a baa lè kó awọn ọmọ Ọlọrun jọ papọ̀.’ Ati pe, nitootọ, ète Ọlọrun ni pe kí Ọmọkunrin rẹ̀ kú gẹgẹ bi ìràpadà kan fun gbogbo ènìyàn.

Kaifa ṣaṣeyọri nisinsinyi ni lílò agbára ìdarí lórí Sanhẹdrin lati ṣe awọn ìwéwèé lati pa Jesu. Ṣugbọn Jesu, tí ó ṣeeṣe kí ó mọ̀ nipa awọn ìwéwèé wọnyi lati ọ̀dọ̀ Nikodemu, mẹmba Sanhẹdrin kan tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, kúrò nibẹ. Johanu 11:38-54.

▪ Eeṣe tí Jesu fi gbàdúrà ní gbangba ṣaaju kí ó tó jí Lasaru dìde?

▪ Bawo ni awọn wọnni tí wọn rí ajinde yii ṣe dáhùnpadà sí i?

▪ Ki ni ó ṣípayá ìwà burúkú awọn mẹmba Sanhẹdrin?

▪ Ki ni ìpètepèrò Kaifa, ṣugbọn ki ni Ọlọrun lò ó lati sọ àsọtẹ́lẹ̀ nipa rẹ̀?