Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ninu Sinagọgu Ilu Ibilẹ Jesu

Ninu Sinagọgu Ilu Ibilẹ Jesu

Orí 21

Ninu Sinagọgu Ilu Ibilẹ Jesu

KÒ SÍ iyemeji pe irusoke imọlara wà ní Nasarẹti nigba ti Jesu pada si ile. Ṣaaju ki o to fi ibẹ silẹ lati lọ ṣe baptisi ni ọwọ́ Johanu ni ohun ti o fi diẹ ju ọdun kan ṣaaju, gbẹ́nàgbẹ́nà kan ni a mọ Jesu si. Ṣugbọn nisinsinyi oun ni a mọ̀ jakejado gẹgẹ bi oṣiṣẹ oniṣẹ iyanu kan. Awọn ara adugbo nharagaga lati ríi ki o ṣe diẹ lara awọn ohun agbayanu wọnyi laaarin wọn.

Ifojusọna wọn ga soke nigba ti Jesu, gẹgẹ bi àṣà rẹ̀, lọ sinu sinagọgu adugbo. Ni akoko isin, oun duro lati kawe, iwe kíká wolii Aisaya ni a sì fi lé e lọwọ. Oun rí ibi naa ti a ti sọ nipa Ẹni ti a fi ẹmi Jehofa yàn, ibi yii ninu Bibeli wa lonii ni Ais ori 61.

Lẹhin kika nipa bi Ẹni yii yoo ṣe waasu idasilẹ fun awọn ìgbèkùn, àtúnríran fun awọn afọju, ati nipa ọdun itẹwọgba Jehofa, Jesu dá iwe kíká naa pada sí ọwọ́ iranṣẹ olutọju naa ó sì jokoo. Gbogbo oju sì wà lara rẹ̀. Lẹhin naa oun sọ̀rọ̀, afaimọ ki o má jẹ́ fun akoko pipẹ diẹ, ni ṣiṣalaye pe: “Lonii ni iwe mimọ yii ṣẹ ni etí yin.”

Awọn eniyan naa ni háà ṣe nitori “awọn ọ̀rọ̀ oore ọ̀fẹ́” ti njade lati ẹnu rẹ̀ wọn sì wí fun araawọn pe: “Ọmọ Josẹfu kọ yii?” Ṣugbọn ní mimọ pe wọn fẹ́ lati rí oun ki oun ṣe awọn iṣẹ iyanu, Jesu nbaa lọ pe: “Loootọ ni ẹyin yoo pa owe yii si mi pe, Oniṣegun, wo ara rẹ̀ san: ohunkohun ti awa gbọ́ pe o ti ọwọ́ rẹ ṣe ni Kapanaomu, ṣe é nihinyii pẹlu ni ilẹ ara rẹ̀.” Bi o ti han gbangba, awọn aladuugbo Jesu tẹlẹri naa nimọlara pe imularada yẹ ki o bẹ̀rẹ̀ ni ile, fun anfaani awọn eniyan oun tìkáraarẹ̀ lakọọkọ. Nitori naa wọn nimọlara pe Jesu kò kà wọn sí.

Ni mimọ ero wọn, Jesu rohin awọn itan kan ti o ba ipo naa mu. Ọpọlọpọ awọn opó ni nbẹ ni Isirẹli ni awọn ọjọ Elija, ni oun ṣalaye, ṣugbọn a kò rán Elija sí ọkankan ninu awọn wọnyi. Kaka bẹẹ, oun lọ sọdọ opó ti kii ṣe ọmọ Isirẹli kan ni Sidoni, nibi ti o ti ṣe iṣẹ iyanu kan ti o gba ẹmi là. Ati ni awọn ọjọ Eliṣa, ọpọlọpọ awọn adẹtẹ ni nbẹ, ṣugbọn Namaani lati Siria nikanṣoṣo ni Eliṣa wẹ̀nùmọ́.

Bi inu ti bi wọn sí awọn ifiwera ọlọ́rọ̀ ìtàn ti kò barade ti o tudii aṣiri imọtara ẹni nikan wọn ati aini igbagbọ wọn, awọn wọnni ti nbẹ ninu sinagọgu dide wọn sì ti Jesu sode sí ẹ̀hìn ode ilu naa. Nibẹ, ni bèbè oke ninu eyi ti a kọ Nasarẹti sí, wọn gbiyanju lati jù ú gba ori bèbè naa. Ṣugbọn Jesu ja àjàbọ́ kuro lọwọ wọn ó sì lọ laisewu. Luuku 4:16-30; 1 Ọba 17:8-16; 2 Ọba 5:8-14.

▪ Eeṣe ti irusoke fi wà ni Nasarẹti?

▪ Ki ni awọn eniyan rò nipa ọ̀rọ̀ Jesu, ṣugbọn ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀ ki ni o mú ki inu bi wọn tobẹẹ?

▪ Ki ni awọn eniyan naa gbiyanju lati ṣe fun Jesu?