Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

O Lóyún Ṣugbọn Kò Ṣe Igbeyawo

O Lóyún Ṣugbọn Kò Ṣe Igbeyawo

Orí 4

O Lóyún Ṣugbọn Kò Ṣe Igbeyawo

OYÚN Maria ti di oṣu mẹta. Iwọ yoo ranti pe o lo apa akọkọ akoko ìlóyún rẹ̀ ni ṣiṣe ibẹwo si ọ̀dọ̀ Elisabẹti, ṣugbọn nisinsinyi oun ti pada wá sí ile ni Nasarẹti. Laipẹ ipo rẹ̀ yoo di eyi ti gbogbo eniyan mọ̀ ni ilu ibilẹ rẹ. Oun, nitootọ, wà ninu hílàhílo!

Ohun ti o mú ipo naa buru siwaju sii ni wipe Maria wà ninu adehun igbeyawo lati di iyawo Josẹfu gbẹ́nàgbẹ́nà. Oun sì mọ̀ pe, labẹ ofin Ọlọrun fun Isirẹli, obinrin kan ti o wà ninu adehun igbeyawo pẹlu ọkunrin kan ṣugbọn ti o finnufindọ ni ibalopọ takọtabo pẹlu ọkunrin miiran ni a nilati sọ ni okuta pa. Bawo ni oun ṣe lè ṣalaye oyún rẹ̀ fun Josẹfu?

Niwọn bi Maria ti lọ fun oṣu mẹta, awa lè ni idaniloju pe Josẹfu ti nharagaga lati rí i. Nigba ti wọn ríra, o ṣeeṣe kí Maria sọ irohin naa fun un. Oun lè sa gbogbo ipá rẹ̀ lati ṣalaye pe nipasẹ ẹmi mimọ Ọlọrun ni oun gbà lóyún. Ṣugbọn, gẹgẹ bi iwọ ti lè mọ̀, eyi jẹ́ ohun ti o nira gidigidi fun Josẹfu lati gbàgbọ́.

Josẹfu mọ orukọ rere ti Maria ní. O sì han kedere pe oun nifẹẹ rẹ̀ gidigidi. Sibẹ, laika ohun ti Maria lè sọ sí, o dabi ẹni pe ọkunrin kan ni o fun un lóyún niti gidi. Ani bi o tilẹ ri bẹẹ, Josẹfu kò fẹ́ kí a sọ ọ́ ni okuta pa tabi ki a dójú tì í ni gbangba. Nitori naa o pinnu lati kọ̀ ọ́ silẹ níkọ̀kọ̀. Ní awọn ọjọ́ wọnni, awọn eniyan ti o wà ninu adehun igbeyawo ni a ńwò gẹgẹ bi tọkọtaya, ikọsilẹ ni a sì beere fun lati fi opin si adehun igbeyawo kan.

Lẹhin naa, bí Josẹfu ti nronu nipa awọn ọran wọnyi sibẹ, o lọ lati sùn. Angẹli Jehofa farahan an ninu àlá ó sì sọ fun un pe: “Ma fòyà lati mú Maria aya rẹ̀ sí ọ̀dọ̀; nitori eyi tí ó yún ninu rẹ̀, lati ọwọ́ Ẹmi Mimọ ni. Yoo sì bí ọmọkunrin kan, Jesu ni iwọ yoo pe orukọ rẹ̀: nitori oun ni yoo gba awọn eniyan rẹ̀ là kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

Nigba ti Josẹfu tají, bawo ni ọpẹ́ rẹ̀ ti tó! Láìjáfara ó ṣe gẹgẹ bi angẹli naa ti wi fun un. O mú Maria wá sí ile rẹ̀. Igbesẹ itagbangba yii ṣiṣẹ, bí ó ti rí, gẹgẹ bi ayẹyẹ igbeyawo, ni fifunni ni afiyesi pe Josẹfu ati Maria nisinsinyi ti ṣe igbeyawo lọna àṣẹ. Ṣugbọn Josẹfu kò ní ibalopọ takọtabo pẹlu Maria ní gbogbo akoko ti o fi wà ninu oyún Jesu.

Sawoo! Akoko ti fẹrẹẹ tó fun Maria lati bímọ, sibẹ Josẹfu ngbe e sori kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan. Nibo ni wọn nlọ, eeṣe ti wọn sì fi nrin irin ajo nigba ti asiko ti fẹrẹẹ tó fun Maria lati bímọ? Luuku 1:39-41, 56; Matiu 1:18-25; Deutaronomi 22:23, 24.

▪ Ipo wo ni ọkan Josẹfu wà nigba ti o gbọ́ nipa oyún Maria, eesitiṣe?

▪ Bawo ni Josẹfu ṣe lè kọ Maria silẹ niwọn bi wọn kò tii ṣe igbeyawo sibẹ?

▪ Igbesẹ itagbangba wo ni o ṣiṣẹ gẹgẹ bi ayẹyẹ igbeyawo Josẹfu ati Maria?