Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Olùṣàkóso Ti O Ju Ẹda Eniyan Lọ kan Tí A Nífẹ̀ẹ́ Sí

Olùṣàkóso Ti O Ju Ẹda Eniyan Lọ kan Tí A Nífẹ̀ẹ́ Sí

Orí 53

Olùṣàkóso Ti O Ju Ẹda Eniyan Lọ kan Tí A Nífẹ̀ẹ́ Sí

NIGBA ti Jesu fi pẹlu iṣẹ́-ìyanu bọ́ ẹgbẹẹgbẹrun, kayefi ṣe awọn eniyan. “Dajudaju eyi ni wolii naa tí ó nilati wá sí ayé,” ni wọn wí. Wọn parí-èrò sí pe kii ṣe kìkì pe Jesu gbọdọ jẹ́ wolii yẹn tí ó tóbi jù Mose lọ nikan ni ṣugbọn pe oun nilati jẹ́ olùṣàkóso kan tí a nífẹ̀ẹ́ sí jùlọ. Nitori naa wọn wéwèé lati fi agbára mú un kí wọn sì fi i jẹ ọba.

Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, mọ̀ ohun tí wọn ńwéwèé rẹ̀. Nitori naa oun yára lọ kuro lati lè yẹra fún ìfipá múni lati ọ̀dọ̀ wọn. Ó rán ogunlọgọ naa lọ, ó sì mú awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ní àpàpàǹdodo lati wọnú ọkọ̀ kí wọn sì padà sí Kapanaomu. Oun lẹhin naa tún padà lọ sí orí òkè lati gbàdúrà. Ní gbogbo òru yẹn Jesu dánìkan wà nibẹ.

Ní kété ṣaaju ọ̀yẹ̀ Jesu najú síta lati ibi gíga sókè tí ó ti ni àǹfààní lati rí àyíká rẹ̀ ó sì ṣàkíyèsí bí ẹ̀fúùfù líle kan ti ńru ìgbì sókè. Ninu ìmọ́lẹ̀ òṣùpá tí ó fẹrẹẹ jẹ́ àrànmọ́jú, niwọn bi Irekọja ti sunmọle, Jesu rí ọkọ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti wọn ńjìjàkadì lati tẹsiwaju la ìgbì naa kọjá. Awọn ọkunrin naa ńfi gbogbo agbára tukọ̀.

Ní rírí eyi, Jesu sọ̀kalẹ̀ lati orí òkè naa ó sì bẹrẹsii rìn síhà ọkọ̀ naa laaarin ìgbì. Ọkọ̀ naa ti lọ tó nǹkan bii ibùsọ̀ mẹta tabi mẹrin nigba ti Jesu bá a. Bí ó ti wù kí ó rí, oun ńbá ìrìn rẹ̀ lọ bí ẹni pe oun yoo kọja lara wọn. Nigba ti awọn ọmọ-ẹhin naa rí i, wọn kígbe pe: “Iwin kan ni!”

Jesu fi pẹlu ìtùnú dáhùn pe: “Emi ni; ẹ má bẹ̀rù.”

Ṣugbọn Peteru wipe: “Oluwa, bí iwọ bá ni, pàṣẹ fun mi lati wá sọ́dọ̀ rẹ lórí omi.”

“Wá!” ni Jesu dáhùn.

Láìsí ìdádúró, Peteru, ni jíjáde kuro ninu ọkọ̀ naa, rìn lórí omi síhà ọ̀dọ̀ Jesu. Ṣugbọn ní wíwò ìjì ẹ̀fúùfù naa ẹ̀rù ba Peteru, ó sì bẹrẹsii rì, ó kígbe: “Oluwa, gbà mi là!”

Lẹsẹkẹsẹ Jesu na ọwọ́ rẹ̀ jáde lati mú un, ó sì wí fun un pe: “Iwọ oní-kékeré ìgbàgbọ́, eeṣe tí o fi àyè silẹ fun iyèméjì?”

Lẹhin tí Peteru ati Jesu padà sínú ọkọ̀ naa, ẹ̀fúùfù naa sì dúró, awọn ọmọ-ẹhin sì ṣe kàyéfì. Ṣugbọn njẹ ó yẹ kí wọn ṣe bẹẹ bí? Bí wọn bá ti mòye “itumọ awọn ìṣù burẹdi naa” nipa mímọrírì iṣẹ́-ìyanu títóbi tí Jesu ṣe ní awọn wakati diẹ sẹhin nigba ti ó fi kìkì ìṣù burẹdi márùn-ún ati awọn ẹja kéékèèké meji bọ́ ẹgbẹẹgbẹrun, nigba naa kò yẹ kí ó jọ bí ẹni pe ó jẹ́ kàyéfì pe oun lè rìn lórí omi kí ó sì dá ẹ̀fúùfù naa duro. Nisinsinyi, bí ó ti wù kí ó rí, awọn ọmọ-ẹhin wárì fun Jesu wọn sì wipe: “Ọmọkunrin Ọlọrun ni ọ niti-gidi.”

Laipẹ, wọn dé Jẹnẹsareti, pẹ̀tẹ́lẹ̀ ẹlẹ́wà kan tí ó kún fun èso nítòsí Kapanaomu. Nibẹ ni wọn ti dákọ̀ró. Ṣugbọn nigba ti wọn gòkè èbúté, awọn eniyan dá Jesu mọ̀ wọn sì lọ sí ìgbèríko, wọn ńwá awọn wọnni tí ńṣàìsàn. Nigba ti a sì gbé awọn wọnyi wá lórí awọn àkéte wọn bí wọn bá wulẹ fọwọ́ kàn ìṣẹ́tí ẹ̀wù Jesu, a mú wọn láradá patapata.

Láàárín àkókò yii, ogunlọgọ naa tí wọn rí Jesu ti o fi iṣẹ-iyanu bọ́ ẹgbẹẹgbẹrun rí pe o ti fi ibẹ̀ silẹ. Nitori naa nigba ti awọn ọkọ̀ kéékèèké lati Tiberia dé, wọn wọ̀ wọn, wọn sì ṣíkọ̀ lọ sí Kapanaomu lati wá Jesu kiri. Nigba ti wọn rí i, wọn bi i leere pe: “Rabi, nigba wo ni iwọ dé ìhín?” Jesu bá wọn wi, gẹgẹ bi a o ti ríi láìpẹ́. Johanu 6:14-25; Matiu 14:22-36; Maaku 6:45-56.

▪ Lẹhin tí Jesu ti fi iṣẹ́-ìyanu bọ́ ẹgbẹẹgbẹrun, ki ni awọn eniyan naa fẹ́ lati ṣe sí i?

▪ Ki ni ohun tí Jesu rí lati orí òkè níbi tí ó padà lọ sí, ki ni ó sì ṣe lẹhin naa?

▪ Eeṣe tí kò fi yẹ kí awọn ọmọ-ẹhin ṣe kàyéfì tobẹẹ nipa awọn nǹkan wọnyi?

▪ Ki ni ó ṣẹlẹ̀ lẹhin tí wọn dé èbúté?