Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orílẹ̀-èdè kan Sọnù, Ṣugbọn Kii Ṣe Gbogbo Rẹ̀

Orílẹ̀-èdè kan Sọnù, Ṣugbọn Kii Ṣe Gbogbo Rẹ̀

Orí 79

Orílẹ̀-èdè kan Sọnù, Ṣugbọn Kii Ṣe Gbogbo Rẹ̀

KÉTÉ lẹhin ìjíròrò Jesu pẹlu awọn wọnni tí wọn kórajọ lẹhin òde ilé Farisi kan, awọn kan bayii sọ fun un “nipa awọn ara Galili ẹ̀jẹ̀ awọn ẹni tí [Gomina Roomu naa Pọntu] Pilatu ti pòpọ̀ mọ́ awọn ẹbọ wọn.” Awọn ara Galili wọnyi ni ó ṣeeṣe kí wọn jẹ́ awọn ẹni tí a pa nigba ti ẹgbẹẹgbẹrun awọn Juu tako lílò tí Pilatu lo owó lati inú ìṣúra tẹmpili lati kọ́ ipa-ọ̀nà-omi àtọwọ́dá lati mú omi wá sínú Jerusalẹmu. Awọn wọnni tí wọn ńròhìn ọ̀ràn yii fun Jesu lè maa dámọ̀ràn pe awọn ará Galili wọnni jìyà àjálù ibi naa nitori awọn ìṣe burúkú tiwọn fúnraawọn.

Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, tọ́ wọn sọ́nà, ní bibeere pe: “Ẹyin ha wòye pe awọn ara Galili wọnyi ni a fẹ̀rí hàn pe wọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo awọn ara Galili yooku nitori pe wọn ti jìyà nǹkan wọnyi? Bẹẹkọ, nitootọ,” ni Jesu dáhùn. Lẹhin naa ó lo ìṣẹ̀lẹ̀ naa lati kìlọ̀ fun awọn Juu pe: “Àyàfi bí ẹ bá ronúpìwàdà, gbogbo yin yoo parun bẹẹ gẹ́gẹ́.”

Ní bíbá a nìṣó, Jesu rántí ọ̀ràn ìbìnújẹ́ miiran ní àdúgbò naa, boya tí ó tún ní ìsopọ̀ pẹlu iṣẹ́ kíkọ́ ipa-ọ̀nà-omi àtọwọ́dá. O beere pe: “Tabi awọn mejidinlogun wọnni awọn ẹni tí ilé-ìṣọ́ Siloamu ṣubú lélórí, tí ó tipa bayii pa wọn, ẹyin ha ronú pe a fi wọn hàn ní ajigbèsè ju gbogbo awọn ọkunrin yooku tí ńgbé Jerusalẹmu?” Ó tì, kii ṣe nitori ìwà buburu awọn ẹni wọnyi ni ó fi ṣẹlẹ̀ pe wọn kú, ni Jesu wí. Kàkà bẹẹ, “ìgbà ati èèṣì” ni ó maa ńjẹ́ okùnfà ní gbogbogboo fun irúfẹ́ awọn ọ̀ràn ìbìnújẹ́ bẹẹ. Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, lẹẹkan sí i lo àkókò naa lati kìlọ̀ pe: “Ṣugbọn, àyàfi bí ẹ bá ronúpìwàdà, gbogbo yin yoo parun ní ọ̀nà kan naa.”

Jesu lẹhin naa nbaa lọ lati funni ní àkàwé tí ó yẹ kan, ní ṣíṣàlàyé pe: “Ọkunrin kan bayii gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ kan sínú ọgbà àjàrà rẹ̀, ó sì wá ńwá èso kiri lórí rẹ, ṣugbọn kò rí ọ̀kan. Nigba naa ni ó wí fun olùrẹ́ ọwọ́ àjàrà pe, ‘Ọdun mẹta niyii tí mo ti ńwá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yii, ṣugbọn emi kò rí ọ̀kan. Gé e lulẹ̀! Eeṣe niti gidi tí o fi nilati sọ ilẹ̀ naa di aláìwúlò?’ Ní ìfèsìpadà ó wí fun un pe, ‘Ọ̀gá, fisílẹ̀ ní ọdun yii pẹlu, títí emi yoo fi walẹ̀ yí i ká kí emi sì fi ìlẹ̀dú sí i; nigba naa bí ó bá sì so èso ní ẹ̀hìn-ọ̀la, ó dára; ṣugbọn bí bẹẹkọ iwọ yoo gé e lulẹ̀.’”

Jesu ti lò ohun tí ó ju ọdun mẹta lọ ni gbígbìyànjú lati mú ìgbàgbọ́ dàgbà láàárín orílẹ̀-èdè Juu. Ṣugbọn iwọnba ọgọrun-un diẹ awọn ọmọ-ẹhin ni a lè kà gẹgẹ bi èso awọn làálàá rẹ̀. Nisinsinyi, láàárín ọdun kẹrin iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ yii, oun mú awọn ìsapá rẹ̀ gbónájanjan sí i, ní wíwalẹ̀ ati fífi ìlẹ̀dú ìṣàpẹẹrẹ yíká igi ọ̀pọ̀tọ́ Juu naa nipa fífi tìtaratìtara waasu kí ó sì maa kọ́ni ní Judia ati Peria. Sibẹ pàbó ni ó jásí! Orílẹ̀-èdè naa kọ̀ lati ronúpìwàdà ati nitori naa ó wà ní ìlà fun ìparun. Kìkì aṣẹ́kù kan lati inú orílẹ̀-èdè naa ni ó dáhùnpadà.

Kò pẹ́ lẹhin naa Jesu ńkọ́ni ninu sinagọgu ní Sabaati kan. Nibẹ ni ó ti rí obinrin kan ẹni tí, nitori ẹ̀mí-èṣù kan tí ó ńpọ́n ọn lójú, ti tẹ̀hìnpo fun 18 ọdun. Pẹlu ìyọ́nú, Jesu darí àfiyèsí sí i pe: “Obinrin, a tú ọ silẹ ninu àìlera rẹ.” Bí ó ṣe sọ iyẹn ó gbé awọn ọwọ́ rẹ̀ lé e, ati ní ìṣẹ́jú-akàn ó nàró ṣánṣán ó sì bẹrẹsii yin Ọlọrun lógo.

Òṣìṣẹ́ olóyè ti nṣabojuto ni sinagọgu naa, bí ó ti wù kí ó rí, binu. “Ọjọ́ mẹfa ní nbẹ ninu eyi tí a nilati ṣe iṣẹ́,” ni oun ṣatako. “Nitori naa, ẹ wá ninu wọn kí a sì wò yin sàn. Kii sii ṣe ni sabaati.” Òṣìṣẹ́ olóyè naa tipa bayii mọ agbára Jesu lati ṣè ìmúláradá ṣugbọn ó dá awọn eniyan naa lẹ́bi fun wíwá fun ìmúláradá ní Sabaati!

“Ẹyin àgàbàgebè,” ni Jesu dáhùn, “olukuluku yin ní sabaati kò ha ńtú akọmàlúù rẹ̀ tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ silẹ ní ilé ẹran kí ó sì mú un lọ lati fun un ní omi? Kò ha yẹ, nigba naa, fun obinrin yii ẹni tí ó jẹ́ ọmọbinrin Aburahamu, ẹni tí Satani dè, wòó! fun ọdun mejidinlogun, kí a tú u silẹ ninu ìdè yii ní sabaati?”

Tóò, bí wọn ṣe gbọ́ eyi, awọn wọnni tí wọn ṣàtakò Jesu bẹrẹsii nímọ̀lára ìtìjú. Ogunlọgọ naa, bí ó ti wù kí ó rí, yọ̀ sí gbogbo awọn nǹkan ológo tí wọn rí tí Jesu ṣe. Ní ìdáhùnpadà Jesu tún awọn àkàwé alasọtẹ́lẹ̀ meji sọ nipa Ijọba Ọlọrun, awọn tí ó sọ ninu ọkọ̀ kan lórí Òkun Galili ní nǹkan bíi ọdun kan ṣaaju. Luuku 13:1-21, NW; Oniwaasu 9:11; Matiu 13:31-33.

▪ Awọn ọ̀ràn ìbìnújẹ́ wo ni a mẹ́nukàn níhìn-ín, ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni Jesu sì fàyọ lati inú wọn?

▪ Ìfisílò wo ni a lè ṣe nipa igi ọ̀pọ̀tọ́ aláìlèsèso naa, ati bakan naa awọn ìgbìdánwò lati mú un mésojáde?

▪ Bawo ni òṣìṣẹ́ olóyè ti nṣabojuto naa ṣe mọ agbara Jesu lati ṣe imularada lamọjẹwọ, sibẹ bawo ni Jesu ṣe tudii aṣiri àgàbàgebè ọkunrin naa?