Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orísun Ayọ̀

Orísun Ayọ̀

Orí 75

Orísun Ayọ̀

LÁKÒÓKÒ iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Galili, Jesu ṣe awọn iṣẹ́-ìyanu, oun nisinsinyi tún ṣe iwọnyi ní Judia. Fun apẹẹrẹ, ó lé ẹ̀mí-èṣù jáde lára ọkunrin kan tí ó ti ṣe ìdíwọ́ fun un lati sọ̀rọ̀. Ogunlọgọ naa ni kàyéfì ṣe, ṣugbọn awọn lámèyítọ́ gbé àtakò kan naa dìde iru eyi tí wọn gbé dìde ní Galili. “Ó ńlé awọn ẹ̀mí-èṣù jáde nipasẹ Belisebubu alákòósó awọn ẹ̀mí-èṣù,” ni wọn sọ. Awọn miiran ńfẹ́ ẹ̀rí tí ó tóbi jù iwọnyi lọ lati ọ̀dọ̀ Jesu nipa ẹni tí oun jẹ́, wọn sì ńgbìyànjú lati dán an wò nipa bibeere fun àmì kan lati ọ̀run wá.

Ní mímọ ohun tí wọn ńrò, Jesu fi ìdáhùn kan naa fun awọn lámèyítọ́ rẹ̀ ní Judia bi oun ti fifún awọn tí ó wà ní Galili. Ó ṣàlàyé pe gbogbo ijọba tí ó yapa lòdìsí araarẹ̀ yoo ṣubú. “Nitori naa,” ni ó beere, “bí Satani bá yapa sí araarẹ̀, bawo ni ijọba rẹ̀ yoo ṣe dúró?” Oun ńfi ipò eléwu tí awọn lámèyítọ́ rẹ̀ wà hàn nipa wiwi pe: “Bí ó bá jẹ́ nipasẹ ìka Ọlọrun ni mo lé awọn ẹ̀mí-èṣù jáde, niti gidi ijọba Ọlọrun ti lé yin bá.”

Awọn wọnni tí wọn ńkíyèsí awọn iṣẹ́-ìyanu Jesu nilati dáhùnpadà sí wọn ní ọ̀nà kan naa gẹgẹ bi awọn wọnni tí wọn rí Mose tí ó mú iṣẹ́-ìyanu kan naa ṣe ní awọn ọ̀rúndún ṣaaju. Wọn ṣe sáàfúlà pe: “Ìka Ọlọrun ni eyi!” “Ìka Ọlọrun” pẹlu ni ó gbẹ́ awọn Òfin-àṣẹ Mẹ́wàá sórí wàláà òkúta. Ati pe “ìka Ọlọrun”—ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tabi ipá agbékánkánṣiṣẹ́—ni ohun tí ó fun Jesu lágbára lati lé awọn ẹ̀mí-èṣù jáde ati lati wo awọn aláìsàn sàn. Nitori naa Ijọba Ọlọrun nitootọ ti lé awọn lámèyítọ́ wọnyi bá, niwọn bi ó ti jẹ́ pe Jesu, Ọba Ijọba naa tí a ti yànsípò, wà láàárín wọn nibẹ gan-an.

Jesu lẹhin naa ṣàkàwé pe agbára rẹ̀ lati lé awọn ẹ̀mí-èṣù jáde jẹ́ ẹ̀rí agbára rẹ̀ lórí Satani, kódà gẹgẹ bi ìgbà tí ọkunrin kan tí ó lágbára jù wá lati ibòmíràn tí ó sì borí agbára ọkunrin kan tí ó dìhámọ́ra daradara tí ó ńṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ààfin rẹ̀. O tún ṣe àtúnwí àkàwé naa tí ó sọ ní Galili nipa ẹ̀mí àìmọ́ kan. Ẹmi fi ọkunrin kan silẹ, ṣugbọn nigba ti ọkunrin naa kò fi awọn ohun dídára kún ààyè naa, ẹ̀mí naa padà bọ̀ pẹlu awọn méje miiran, ipò ọkunrin naa sì wá burú jù ti àkọ́kọ́ lọ.

Bí wọn ti nfetisilẹ sí awọn ẹ̀kọ́ wọnyi, obinrin kan láàárín awọn ogunlọgọ naa ni a sún lati ké sáàfúlà soke pe: “Aláyọ̀ ni inú tí ó lóyún rẹ ati awọn ọmú tí iwọ mu!” Niwọn bi ó ti jẹ́ pe ìfẹ́-ọkàn gbogbo obinrin Juu ni lati jẹ́ ìyá wolii kan ati ní pàtàkì Mesaya naa, ó jẹ́ ohun tí ó ṣeé lóye pe obinrin naa yoo sọ eyi. Lọna ti o han gbangba obinrin naa ronú pe Maria ní pàtàkì lè jẹ́ aláyọ̀ nitori pe ó jẹ́ ìyá Jesu.

Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu ní kíákíá tọ́ obinrin naa sọ́nà nipa orísun tootọ fun ayọ̀. “Bẹẹkọ,” ni ó dáhùnpadà, “kàkà bẹẹ, Aláyọ̀ ni awọn wọnni tí ńgbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí wọn sì ńpa á mọ́!” Jesu kò fi ìgbà kan pẹ́ ẹ sọ lae pe ìyá rẹ̀, Maria, ni a nilati fun ní ọlá àkànṣe. Dípò bẹẹ, ó fihàn pe ayọ̀ tootọ ni a ńrí ninu jíjẹ́ olùṣòtítọ́ iranṣẹ Ọlọrun, kii ṣe ninu awọn ìdè ti ara eyikeyii tabi awọn àṣeyọrí.

Gẹgẹ bi ó ti ṣe ní Galili, Jesu pẹlu nbaa nìṣó lati bá awọn eniyan ni Judia wí lọna lílekoko fun bibeere àmì kan lati ọ̀run wá. Ó sọ fun wọn pe kò sí àmì kankan tí a o fifúnni àyàfi àmì Jona. Jona di àmì kan nipasẹ ọjọ́ mẹta rẹ̀ ninu ẹja ati nipasẹ iwaasu onígboyà rẹ̀, tí ó sún awọn ara Ninefe lati ronúpìwàdà. “Ṣugbọn, wòó!” ni Jesu wí, “ohun kan tí ó ju Jona wà níhìn-ín.” Ní ìfarajọra, ẹnu ya ayaba Ṣẹba nitori ọgbọ́n Solomoni. “Ṣugbọn, wòó!” ni Jesu wí pẹlu, “ohun kan tí ó ju Solomoni wà níhìn-ín.”

Jesu ṣàlàyé pe nigba ti ẹnikan bá tan fìtílà, oun kìí gbé e sínú ihò abẹ́lẹ̀ tabi sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ kan ṣugbọn sórí ọ̀pá fìtílà kí gbogbo eniyan lè rí ìmọ́lẹ̀ naa. Boya oun ńfihàn ní kedere pe ikọni ati mímú awọn iṣẹ́-ìyanu ṣe niwaju awujọ awọn eniyan olóríkunkun rẹ̀ wọnyi ṣeé fiwe bíbo ìmọ́lẹ̀ fìtílà kan mọ́lẹ̀. Ojú ìríran irúfẹ́ awọn ti oluṣakiyesi bẹẹ kò gbébìkan, tabi kórí àfiyèsí jọ, nitori naa ète awọn iṣẹ́-ìyanu rẹ̀ ni a kò ṣàṣeyọrí.

Jesu ṣẹ̀ṣẹ̀ lé ẹ̀mí-èṣù kan jáde ti ó sì mú kí ọkunrin kan tí ó yadi sọ̀rọ̀. Eyi nilati sún awọn eniyan tí wọn ní awọn ojú ìríran tí ó gbébìkan, tabi tí o kórí àfiyèsí jọ, lati yin iṣẹ agbara ológo yii kí wọn sì pòkìkí ihinrere naa! Sibẹsibẹ, eyi kii ṣe ohun tí ó ṣẹlẹ̀ laaarin awọn alámèyítọ́ wọnyi. Nitori naa Jesu pari ọ̀rọ̀ naa pe: “Nitori naa, wà lójúfò ní kíkún. Boya ìmọ́lẹ̀ tí nbẹ ninu rẹ jẹ́ òkùnkùn. Nitori naa bí gbogbo ara rẹ bá tànmọ́lẹ̀ láìsí apá kankan rárá tí ó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ yoo mọ́lẹ̀ gẹgẹ bi ìgbà tí fìtílà kan bá ńfún ọ ní ìmọ́lẹ̀ nipa awọn ìtànṣán ìmọ́lẹ̀.” Luuku 11:14-36, NW; Ẹkisodu 8:18, 19; 31:18; Matiu 12:22, 28.

▪ Ki ni ìdáhùnpadà sí ìmúláradá tí Jesu ṣe fun ọkunrin naa?

▪ Ki ni “ìka Ọlọrun” jẹ́, bawo sì ni Ijọba Ọlọrun ti ṣe lé awọn olùgbọ́ Jesu bá?

▪ Ki ni orísun ayọ̀ tootọ?

▪ Bawo ni ẹnikan ṣe lè ní ojú ìríran tí ó gbébìkan?