Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Pèsè fun Ọjọ́ Ọ̀la Pẹlu Ọgbọ́n Ti O Ṣeemulo

Pèsè fun Ọjọ́ Ọ̀la Pẹlu Ọgbọ́n Ti O Ṣeemulo

Orí 87

Pèsè fun Ọjọ́ Ọ̀la Pẹlu Ọgbọ́n Ti O Ṣeemulo

JESU ṣẹ̀ṣẹ̀ parí sísọ ìtàn ọmọkunrin onínàákúnàá fun ogunlọgọ kan tí ó ní ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn agbowó-orí alábòsí ati awọn ẹlẹ́ṣẹ̀ miiran tí gbogbo eniyan mọ̀, ati awọn akọwe ofin ati awọn Farisi. Nisinsinyi, ní bíbá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ sọ̀rọ̀, o sọ àkàwé nipa ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan tí ó gba ìròhìn aláìbáradé kan nipa olùbójútó ilé, tabi ìríjú rẹ̀.

Gẹgẹ bi Jesu ti wí, ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa pe ìríjú rẹ̀ ó sì sọ fun un pe oun yoo lé e lọ. “Ewo ni emi yoo ṣe? Nitori ti Oluwa mi gba iṣẹ iriju lọwọ mi?” ni ìríjú naa ṣe kàyéfì. “Emi kò lágbára lati walẹ̀; lati ṣagbe oju nti mi. Mo mọ eyi ti emi yoo ṣe, nigba ti a ba mu mi kuro nibi iṣẹ iriju, ki wọn ki o lè gbà mi sinu ile wọn.”

Ki ni ìwéwèé ìríjú naa? Ó pè awọn wọnni tí wọn jẹ ọ̀gá rẹ̀ ní gbèsè. “Eélòó ni iwọ jẹ?” ni oun beere.

Ẹni àkọ́kọ́ dáhùn, ‘Ọgọrun-un oṣuwọn òróró.’

‘Mu iwe rẹ, si jokoo nisinsinyi ki o sì kọ aadọta,’ ni ó sọ fun un.

Ó beere lọwọ ẹlomiran pe: ‘Eélòó ni iwọ jẹ?’

Ó sọ pe, ‘Ọgọrun-un oṣuwọn àlìkámà.’

‘Mu iwe rẹ, ki o sì kọ ọgọrin.’

Ìríjú naa kò rekọja ẹ̀tọ́ rẹ̀ ni dídín owó ti awọn eniyan jẹ ọ̀gá rẹ̀ kù, niwọn bi ó ti jẹ́ pe oun sibẹsibẹ ṣì wà nídìí àbójútó awọn àlámọ̀rí inawo ọ̀gá rẹ̀. Nipa dídín owó naa kù, oun ńbá awọn tí wọn lè san ojúrere pada fun un nigba ti ó bá pàdánù iṣẹ́ rẹ̀ ṣọ̀rẹ́.

Nigba ti ọ̀gá naa gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ, a ṣí i lórí. Nitootọ, ó “yin alaiṣootọ ìríjú naa, nitori o fi ọgbọ́n [“ọgbọ́n ti o ṣeémúlò,” NW] huwa.” Nitootọ, Jesu fikun un pe: “Awọn ọmọ aye yii ṣaa gbọ́n ni iran wọn ju awọn ọmọ imọlẹ lọ.”

Nisinsinyi, ní fífa ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n naa yọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Jesu fun wọn ni iṣiri pe: “Ẹ fi mammoni aiṣootọ yan ọ̀rẹ́ fun ara yin pe, nigba ti yoo ba yẹ̀, ki wọn ki o lè gba yin si ibujokoo wọn titi aye.”

Jesu kò yìn ìríjú naa fun aiṣootọ rẹ̀ ṣugbọn fun ọgbọ́n ti o ṣeémúlò rẹ̀ tí ó ríran jìnnà. Ní ọpọ ìgbà “awọn ọmọ aye yii” pẹlu ọgbọ́n maa ńlò owó tabi àyè wọn lati dọ́rẹ̀ẹ́ pẹlu awọn wọnni tí wọn lè san ojúrere pada fun wọn. Nitori naa awọn iranṣẹ Ọlọrun, “awọn ọmọ ìmọ́lẹ̀,” pẹlu nílò lati lò awọn ohun ìní nipa ti ara, “mammoni aiṣootọ” wọn, lọna ọgbọ́n lati mú àǹfààní ba araawọn.

Ṣugbọn gẹgẹ bi Jesu ti sọ, wọn nilati fi awọn mammoni wọnyi dọ́rẹ̀ẹ́ pẹlu awọn wọnni tí wọn lè gbà wọn “sí ibujokoo wọn titi aye.” Fun awọn mẹmba agbo kekere, ibujokoo yii wà ní ọ̀run; fun awọn “àgùtàn miiran,” wọn wà ni Paradise ilẹ̀-ayé. Niwọn bi ó ti jẹ́ pe kìkì Jehofa Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀ ni ó lè gbà awọn eniyan sínú awọn ibujokoo wọnyi, a nilati jẹ́ aláápọn ni mimu ibadọrẹẹ dagba pẹlu wọn nipa lílò “mammoni aiṣootọ” eyikeyii tí a lè ní lati ṣètìlẹhìn fun ire Ijọba. Nigba naa, nigba ti awọn ọrọ̀ nipa ti ara bá kùnà tabi ṣègbé, bí wọn yoo ti ṣe dajudaju, ọjọ́ ọ̀la ayeraye wa ni a mú dájú.

Jesu nbaa lọ lati sọ pe awọn ènìyàn tí wọn bá jẹ́ oloootọ ni bíbójútó kódà awọn ohun ti ara, tabi ohun kínkínní yoo jẹ́ oloootọ pẹlu ni bíbójútó awọn ọ̀ràn tí ó ṣe pataki gidi paapaa. “Njẹ,” ni oun nbaa lọ, “bí ẹyin kò ba ti jẹ oloootọ ni mammoni aiṣootọ, ta ni yoo fi ọrọ̀ tootọ [iyẹn ni, awọn ire tẹ̀mí, tabi ti Ijọba], ṣú yin? Bí ẹyin kò ba sì ti jẹ olootọ ni ohun ti nṣe ti ẹlomiran [ire Ijọba tí Ọlọrun fi sí ìkáwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀], ta ni yoo fun yin ní ohun tí nṣe ti ẹyin tikaraayin [èrè ìyè ninu awọn ibujokoo wọn titi aye]?”

A kò wulẹ lè jẹ́ iranṣẹ tootọ fun Ọlọrun ati lẹsẹkan naa kí a sì jẹ́ ẹrú fun mammoni aiṣootọ, awọn ọrọ̀ nipa ti ara, gẹgẹ bi Jesu ṣe pari ọ̀rọ̀ rẹ̀ pe: “Kò sí iranṣẹ kan ti o lè sìn oluwa meji, àyàṣebí yoo koriira ọkan, yoo sì fẹ́ ekeji; tabi yoo fi ara mọ́ ọ̀kan, yoo sì yan keji ni ìpọ̀sì. Ẹyin kò lè sin Ọlọrun pẹlu mammoni.” Luuku 15:1, 2; 16:1-13; Johanu 10:16.

▪ Bawo ni ìríjú inú àkàwé Jesu ṣe dọ́rẹ̀ẹ́ pẹlu awọn wọnni tí wọn lè ràn án lọwọ lẹhin àkókò naa?

▪ Ki ni “awọn mammoni aiṣootọ” jẹ́, bawo ni a sì ṣe lè dọ́rẹ̀ẹ́ nipasẹ wọn?

▪ Ta ni ó lè gbà wá “sí awọn ibujokoo wọn titi aye,” awọn ibi wo sì ni iwọnyi?