Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Pípe Matiu

Pípe Matiu

Orí 27

Pípe Matiu

KÉTÉ lẹhin mímú alárùn ẹ̀gbà naa láradá, Jesu jáde lọ kuro ní Kapanaomu sí Òkun Galili. Lẹẹkan sí i ogunlọgọ awọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá, ó sì bẹrẹsii kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Bí ó ti ńrìn lọ, ó rí Matiu, ẹni tí ó tún ńjẹ́ Lefi, tí ó jókòó ní ilé iṣẹ́ awọn agbowó-orí. “Di ọmọlẹhin mi,” ni ìkésíni Jesu.

Ó ṣeeṣe kí Matiu ti mọ awọn ẹ̀kọ́ Jesu dunjú tẹlẹ, àní gẹgẹ bii Peteru, Anderu, Jakọbu, ati Johanu nigba ti a pè wọn. Ati gẹgẹ bii wọn, Matiu lẹsẹkẹsẹ dáhùn sí ìkésíni naa. Ó dìde, ó fi awọn ẹrù-iṣẹ́ rẹ̀ gẹgẹ bi agbowó-orí silẹ sẹhin, ó sì tẹle Jesu.

Lẹhin ìgbà naa, boya lati ṣàjọyọ̀ títẹ́wọ́gbà pípè tí a pè é, Matiu se àsè ìṣenilálejò gbígbórín kan ninu ilé rẹ̀. Ní àfikún sí Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin Rẹ̀, awọn olùbákẹ́gbẹ́ Matiu àtijọ́ wà níbẹ̀. Awọn ọkunrin wọnyi ni awọn Juu ẹlẹgbẹ́ wọn maa ńtẹ́ḿbẹ́lú ní ọ̀pọ̀ ìgbà nitori wọn ńgba owó-orí fun awọn aláṣẹ Roomu tí wọn kórìíra. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn maa ńfi pẹlu àbòsí fi ọranyan beere owó pupọ sii lati ọ̀dọ̀ awọn ènìyàn ju iye owó-orí tí ó yẹ kí wọn san.

Ní fífi ìṣọ́ra kíyèsí Jesu ní ibi àsè naa pẹlu irú awọn ènìyàn bẹẹ, awọn Farisi beere lọwọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Eeṣe tí olùkọ́ yin fi njẹun pẹlu awọn agbowó-orí ati awọn ẹlẹ́ṣẹ̀?” Bí ibeere naa ti ta sí i létí, Jesu dá awọn Farisi naa lóhùn: “Awọn ènìyàn tí ara wọn lé kò nílò oníṣègùn, ṣugbọn awọn tí ńṣòjòjò fẹ́ ẹ. Ẹ lọ, nigba naa, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí eyi tumọsi, ‘Emi fẹ́ àánú, kìí sìí ṣe ẹbọ.’ Nitori emi wá lati pè, kii ṣe awọn ènìyàn olódodo, bikoṣe awọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

Lọna ti o hàn kedere, Matiu késí awọn agbowó-orí wọnyi wá sínú ilé rẹ̀ kí wọn lè fetisilẹ sí Jesu kí wọn sì rí ìmúláradá nipa tẹ̀mí gbà. Nitori naa Jesu bá wọn kẹ́gbẹ́ lati ràn wọn lọwọ kí ọwọ́ wọn lè tẹ ìbátan onílera kan pẹlu Ọlọrun. Jesu kò tẹ́ḿbẹ́lú irú awọn ẹni bẹẹ, gẹgẹ bi awọn Farisi aṣòdodo lójú ara-ẹni ti ṣe. Kàkà bẹẹ, bí a ti sún un pẹlu ìyọ́nú, niti tootọ, ó ṣiṣẹ́ gẹgẹ bi oníṣègùn kan nipa tẹ̀mí fun wọn.

Nipa bayii lílò tí Jesu lo àánú fun awọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kii ṣe fifayegba awọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn ṣugbọn o fi awọn ìmọ̀lára onípẹ̀lẹ́tù kan naa tí ó fihàn kedere fun awọn tí wọn ńṣàmódi nipa ti ara hàn. Rántí, fun apẹẹrẹ, nigba ti ó fi pẹlu ìyọ́nú fi ọwọ́ kan adẹ́tẹ̀ naa, ní wiwi pe: “Mo fẹ́. Di mímọ́ tónítóní.” Njẹ kí awa bakan naa fi àánú hàn nipasẹ ríran awọn ènìyàn tí wọn jẹ́ aláìní lọwọ, pàápàá ní pàtàkì ní ṣíṣèrànwọ́ fun wọn ní ọ̀nà tẹ̀mí. Matiu 8:3; 9:9-13; Maaku 2:13-17; Luuku 5:27-32.

▪ Nibo ni Matiu wà nigba ti Jesu rí i?

▪ Ki ni iṣẹ́ Matiu, eeṣe tí awọn Juu yooku fi tẹ́ḿbẹ́lú irú awọn ènìyàn bẹẹ?

▪ Ìráhùn wo ni a ṣe lòdìsí Jesu, bawo sì ni oun ṣe dáhùnpadà?

▪ Eeṣe tí Jesu fi bá awọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́?