Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Jesu Jẹ́ Niti Gidi?

Ta Ni Jesu Jẹ́ Niti Gidi?

Orí 59

Ta Ni Jesu Jẹ́ Niti Gidi?

NIGBA ti ọkọ̀ ti o gbé Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gúnlẹ̀ sí èbúté Bẹtisaida, awọn eniyan gbé ọkunrin afọ́jú kan tọ̀ ọ́ wá wọn sì bẹ̀bẹ̀ pe kí ó fọwọ́kàn ọkunrin naa kí ó sì mú un láradá. Jesu fà ọkunrin naa jáde si ẹhin ode ìletò naa ati, lẹhin títutọ́ sí i ní ojú, ó beere pe: “Iwọ rí ohunkohun?”

“Mo rí awọn eniyan,” ni ọkunrin naa dáhùn, “nitori mo ṣàkíyèsí ohun tí ó dabi igi, ṣugbọn wọn ńrìn kaakiri.” Ní gbígbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú ọkunrin naa, Jesu mú agbára ìríran rẹ̀ padàbọ̀sípò tí ó fi jẹ́ pe ó lè ríran kedere. Jesu lẹhin naa rán ọkunrin naa padà sí ilé pẹlu ìtọ́ni lati maṣe wọnú ìlú naa.

Nisinsinyi Jesu ati awọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ fi ibẹ̀ silẹ lọ si abúlé Kesaria ti Filipi, ní ìpẹ̀kun àríwá Palẹsitini. Ó jẹ́ òkè gígùn kan tí ó kárí nǹkan bii 30 ibùsọ̀ títílọ dé ibi ẹlẹ́wà Kesaria ti Filipi naa, ti o fi nǹkan bii 1,150 ẹsẹ̀ bàtà ga ju ìtẹ́bẹẹrẹ ojú òkun. Àfàìmọ̀ kí ìrìn àjò naa má gbà awọn ọjọ melookan.

Ní ojú ọ̀nà, Jesu lọ ni oun nikan lati gbadura. Nǹkan bii oṣu mẹ́sàn-án tabi mẹ́wàá péré ni ó ṣẹ́kù ṣaaju ikú rẹ̀, ó sì ńdàníyàn nipa awọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀. Ṣaaju isinsinyi ọpọlọpọ ti dẹ́kun títọ̀ ọ́ lẹ́hìn. Lọna ti o han gbangba awọn miiran ti ní ìdàrú ọkan ati ìjákulẹ̀ nitori pe ó ṣá ìsapá awọn eniyan naa tì lati sọ ọ́ di ọba ati nitori pe oun kò pèsè àmì kan lati ọ̀run lati fi ipò ọba rẹ̀ hàn nigba ti awọn ọ̀tá rẹ̀ pè é níjà. Ki ni awọn apọsiteli rẹ̀ gbàgbọ́ nipa ẹni tí oun jẹ́? Nigba ti wọn rékọjá sí ibi tí ó ti ńgbàdúrà, Jesu wádìí lọwọ wọn pe: “Ta ni awọn ogunlọgọ eniyan wipe mo jẹ́?”

“Awọn kan wipe Johanu Onírìbọmi,” ni wọn dáhùn, “awọn miiran Elija, sibẹ awọn miiran Jeremaya tabi ọ̀kan ninu awọn wolii.” Bẹẹni, awọn eniyan naa ronú pe Jesu jẹ́ ọ̀kan ninu awọn ọkunrin wọnyi tí a ti ti jí dìde lati inú òkú!

“Ṣugbọn ẹyin ńkọ́, ta ni ẹyin wipe mo jẹ́?” ni Jesu beere.

Laijafara Peteru dáhùnpadà pe: “Iwọ ni Kristi, Ọmọkunrin Ọlọrun alààyè.”

Lẹhin titẹwọgba ìdáhùnpadà Peteru, Jesu wipe: “Mo wí fun ọ, Iwọ ni Peteru, lórí agbasà yii ni emi yoo sì kọ́ ijọ mi, ẹnu-ọ̀nà Hédíìsì kì yoo sì borí rẹ̀.” Níhìn-ín ni Jesu ti kọ́kọ́ ṣèfilọ̀ pe oun yoo kọ́ ijọ kan ati pe ikú pàápàá kì yoo lè mú awọn mẹmba rẹ̀ ní òǹdè lẹhin ipa-ọ̀nà olóòótọ́ wọn lórí ilẹ̀-ayé. Lẹhin naa ni ó sọ fun Peteru pe: “Emi yoo fun ọ ní awọn kọ́kọ́rọ́ ijọba awọn ọ̀run.”

Nipa bayii Jesu ṣíi payá pe Peteru yoo gba awọn àǹfààní àkànṣe. Bẹẹkọ kii ṣe ipò àkọ́kọ́ láàárín awọn apọsiteli ni a fi fun Peteru, bẹẹ sì ni a kò fi i ṣe ìpilẹ̀ ijọ naa. Jesu fúnraarẹ̀ ni Agbasà lórí eyi tí a o kọ́ ijọ naa. Ṣugbọn Peteru ni a o fun ní awọn kọ́kọ́rọ́ mẹta eyi tí oun yoo fi ṣí, gẹgẹ bi ẹni pe ó jẹ́ bẹẹ niti gidi, àǹfààní fun àwùjọ awọn ènìyàn lati wọ Ijọba awọn ọ̀run.

Peteru yoo lò kọ́kọ́rọ́ àkọ́kọ́ ní Pẹntikọsi 33 C.E. lati fihàn awọn Juu olùronúpìwàdà ohun tí wọn gbọdọ ṣe lati ní ìgbàlà. Oun yoo lò ekeji ní gẹ́lẹ́ lẹhin naa lati ṣí àǹfààní silẹ fun awọn ara Samaria tí wọn gbàgbọ́ lati wọ inú Ijọba Ọlọrun. Lẹhin naa, ní 36 C.E. oun yoo lò kọ́kọ́rọ́ kẹta lati fi ṣi àǹfààní kan-naa silẹ fun awọn Keferi aláìkọlà, Kọniliu ati awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Jesu nba ìjíròrò rẹ̀ nìṣó pẹlu awọn apọsiteli rẹ̀. Oun já wọn kulẹ̀ nipa sísọ̀rọ̀ lórí awọn ìjìyà ati ikú tí oun yoo dojúkọ láìpẹ́ ní Jerusalẹmu. Ní kíkùnà lati lóye pe Jesu ni a o ji dide sí iwalaaye ti ọ̀run, Peteru pe Jesu sẹgbẹẹkan. “Ṣàánú araàrẹ, Oluwa,” ni oun wí. “Iwọ kì yoo ní kádàrá yii rárá.” Ní yíyí ẹ̀hìn rẹ̀ dà, Jesu dáhùn pe: “Kúrò niwaju mi, Satani! Òkúta ìkọ̀sẹ̀ ni iwọ jẹ́ fun mi, nitori iwọ ńrò, kii ṣe awọn ìrò-inú Ọlọrun, bikoṣe ti eniyan.”

Lọna ti o han gbangba, awọn miiran yàtọ̀ sí awọn apọsiteli ńrìnrìn àjò pẹlu Jesu, nitori naa o pè wọn nisinsinyi lati ṣàlàyé fun wọn pe kì yoo rọrùn lati jẹ́ ọmọlẹhin oun. “Bí ẹnikẹni bá fẹ́ tẹle mi,” ni oun wí, “jẹ́ kí ó kọ araarẹ̀ silẹ kí ó sì gbé òpó-igi ìdálóró rẹ̀ kí ó sì maa tọ̀ mi lẹ́hìn nigba gbogbo. Nitori ẹni yoowu tí ó bá fẹ́ gbá ọkàn rẹ̀ là yoo sọ ọ́ nù; ṣugbọn ẹni yoowu tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nitori mi ati ihinrere yoo gbà á là.”

Bẹẹni, awọn ọmọlẹhin Jesu gbọdọ ní ìgboyà kí wọn sì jẹ́ olùfara-ẹni-rúbọ bí wọn yoo bá fi araawọn hàn bí ẹni tí ó tóótun fun ojúrere rẹ̀. O sọ pe: “Nitori ẹni yoowu tí ó bá tijú mi ati awọn ọ̀rọ̀ mi ní ìran-ènìyàn oníwà-panṣágà ati ẹlẹ́ṣẹ̀ yii, Ọmọkunrin eniyan pẹlu yoo tijú rẹ̀ nigba ti ó bá dé inú ògo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli mímọ́.” Maaku 8:22-38; Matiu 16:13-28; Luuku 9:18-27, NW.

▪ Eeṣe tí Jesu fi dàníyàn nipa awọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀?

▪ Ojú ìwòye wo ni awọn eniyan ní nipa ẹni tí Jesu jẹ́?

▪ Awọn kọ́kọ́rọ́ wo ni a fun Peteru, bawo ni ó sì ṣe lò wọn?

▪ Ìtọ́sọ́nà wo ni Peteru gbà, eesitiṣe?