Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwá Eyi Tí Ó Sọnù Kiri

Wíwá Eyi Tí Ó Sọnù Kiri

Orí 85

Wíwá Eyi Tí Ó Sọnù Kiri

JESU ní ìháragàgà lati wá kí ó sì rí awọn wọnni tí wọn yoo fi tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀ ṣiṣẹ́sìn Ọlọrun. Nitori naa ó ńwákiri ó sì ńbá olukuluku eniyan sọ̀rọ̀ nipa Ijọba naa, tí ó ní ninu awọn ẹlẹ́ṣẹ̀ olókìkí burúkú. Irú awọn ẹni bẹẹ sunmọtosi nisinsinyi lati fetisilẹ sí i.

Ní ṣíṣàkíyèsí eyi, awọn Farisi ati awọn akọwe ofin tako Jesu fun kíkẹ́gbẹ́ pẹlu awọn eniyan tí wọn kà sí aláìyẹ. Wọn sọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pe: “Ọkunrin yii gbà ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ńbá wọn jẹun.” Bawo ni iyẹn ṣe rẹlẹ̀ sí iyì wọn tó! Awọn Farisi ati awọn akọwe ofin ńhùwà sí awọn eniyan gbáàtúù gẹgẹ bi ìdọ̀tí lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn. Niti tootọ, wọn lò ọ̀rọ̀ Heberu naa ‛am ha·’aʹrets, “awọn eniyan ilẹ̀ [ilẹ̀-ayé],” lati fi ìtẹ́ḿbẹ́lú tí wọn ní fun irúfẹ́ awọn ẹni bẹẹ hàn.

Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, Jesu huwa si olukuluku eniyan pẹlu iyì, inurere, ati iyọnu. Gẹgẹ bi iyọrisi, ọpọ awọn onirẹlẹ wọnyi ti o ni ninu awọn eniyan ti wọn gbajumọ fun ṣiṣe ohun ti o buru bi àṣà, nharagaga lati fetisilẹ si i. Ṣugbọn ki ni nipa ti atako awọn Farisi pe Jesu nṣe afikun isapa niha ọdọ awọn ti wọn kà si aláìyẹ?

Jesu dáhùn àtakò wọn nipa lílò àkàwé kan. Oun sọ̀rọ̀ lati ọ̀nà ojú ìwòye ti awọn Farisi fúnraawọn, bí ẹni pe wọn jẹ́ olódodo, wọn sì wà láìléwu ninu ọgbà ẹran Ọlọrun, tí awọn òkúùgbẹ́ ‛am ha·’aʹrets ti ṣakolọ tí wọn sì ti wà ninu ipò ẹni tí ó sọnù. Fetisilẹ bí oun ti nbeere pe:

“Ọkunrin wo ninu yin, tí ó ní ọgọ́rùn-ún àgùtàn, bi o ba sọ ọ̀kan nù ninu wọn, tí ki yoo fi mọkandinlọgọrun-un iyoku silẹ ní iju, tí kí yoo sì tọsẹ eyi ti o nù lọ titi yoo fi rí i? Nigba ti ó sì ti rí i tán, ó gbé e lé èjìká rẹ̀ ó ńyọ̀. Nigba ti ó sì dé ilé, ó pe awọn ọ̀rẹ́ ati aládùúgbò rẹ̀ jọ, ó sì wí fun wọn pe: ‘Ẹ bá mi yọ̀; nitori ti mo rí àgùtàn mi tí ó nù.’”

Jesu lẹhin naa sọ itumọ ìtàn rẹ̀ ní ṣíṣàlàyé pe: “Mo wí fun yin, gẹgẹ bẹẹ ni ayọ yoo wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà, jù lórí olóòótọ́ mọkandinlọgọrun-un, tí kò ṣe aini ìrònúpìwàdà.”

Awọn Farisi ka araawọn sí olóòótọ́ ti wọn kò sì tipa bayii nílò ìrònúpìwàdà. Nigba ti diẹ lára wọn ṣe lámèyítọ́ Jesu ní ọdun melookan ṣaaju fun jíjẹun pẹlu awọn agbowó-orí ati awọn ẹlẹ́ṣẹ̀, oun sọ fun wọn pe: “Emi kò wá lati pe awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.” Awọn Farisi tí wọn jẹ́ olódodo lójú araawọn, tí wọn kùnà lati rí àìní wọn lati ronúpìwàdà, kò mú ayọ̀ kankan wá ní ọrun. Ṣugbọn awọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọn ronúpìwàdà nitootọ ṣe bẹẹ.

Lati mú kókó naa lágbára ní ìlọ́po meji pe ìmúpadàsípò awọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọn sọnù maa nṣokunfa ayọ̀ pupọ, Jesu sọ àkàwé miiran. Oun sọ pe: “Tabi obinrin wo ni ó ní fadaka mẹ́wàá, bí ó bá sọ ọ̀kan nù, ti ki yoo tan fìtílà, kí ó sì gbá ilé, kí ó sì wá a gidigidi títí yoo fi rí i? Nigba ti ó sì rí i, ó pe awọn ọ̀rẹ́ ati awọn aládùúgbò rẹ jọ, o wipe, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nitori mo rí fadaka tí mo ti sọnù.’”

Jesu lẹhin naa fúnni ní ìfisílò tí ó farajọra. Ó nbaa lọ lati wipe: “Mo wi fun yin, gẹgẹ bẹẹ ni ayọ̀ nbẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”

Ẹ wo bi ìdàníyàn onífẹ̀ẹ́ tí awọn angẹli Ọlọrun ni fun ìmúpadà bọ̀sípò awọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọn ti sọnù ṣe pẹtẹrí tó! Pàápàá ní pàtàkì ni eyi fi jẹ́ bẹẹ niwọn bi ‛am ha·’aʹrets rírẹlẹ̀, tí a ti tẹmbẹlu lẹẹkan rí yii ti wá sí ìlà ní àsẹ̀hìnwá àsẹ̀hìnbọ̀ fun jíjẹ́ mẹmba Ijọba ọ̀run ti Ọlọrun. Gẹgẹ bi ìyọrísí rẹ̀, wọn dé ipò kan ní ọ̀run tí ó ga jù ti awọn angẹli fúnraawọn! Ṣugbọn kàkà kí wọn nímọ̀lára owú tabi pe a fojúbù wọn kéré, awọn angẹli fi ìrẹ̀lẹ̀ mọrírì pe awọn ẹ̀dá-ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ wọnyi ti dojúkọ wọn sì ti borí awọn ipò ninu igbesi-aye tí yoo mú wọn gbaradì lati ṣiṣẹ́sìn gẹgẹ bi awọn alufaa ati awọn ọba ọ̀run aláàánú ati abánikẹ́dùn. Luuku 15:1-10, NW; Matiu 9:13; 1 Kọrinti 6:2, 3; Iṣipaya 20:6.

▪ Eeṣe tí Jesu fi kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹlu awọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí a mọ̀ dunjú, lámèyítọ́ wo ni oun sì fayọ lati ọ̀dọ̀ awọn Farisi?

▪ Ojú wo ni awọn Farisi fi nwo awọn eniyan gbáàtúù?

▪ Awọn àkàwé wo ni Jesu lò, kí sì ni a lè kẹ́kọ̀ọ́ lati inú wọn?

▪ Eeṣe tí ayọ awọn angẹli fi pẹtẹrí?