Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọn Kùnà Lati Dẹkùn Mú Jesu

Wọn Kùnà Lati Dẹkùn Mú Jesu

Orí 108

Wọn Kùnà Lati Dẹkùn Mú Jesu

NITORI Jesu ti ńkọ́ni ninu tẹmpili tí ó sì ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àkàwé mẹta fun awọn ọ̀tá rẹ̀ onisin tí ó túdìí àṣírí ìwà burúkú wọn, awọn Farisi binu, wọn sì gbìmọ̀pọ̀ lati mú kí ó sọ ohun kan ti wọn lè tipasẹ̀ rẹ̀ fàṣẹ ọba mú un. Wọn hùmọ̀ rìkíṣí kan wọn sì rán awọn ọmọ-ẹhin wọn, papọ pẹlu awọn ọmọlẹhin ẹgbẹ́ Hẹrọdu, lati gbiyanju lati mú un ṣe àṣìṣe ninu ọ̀rọ̀ sísọ.

Awọn ọkunrin wọnyi wipe: “Olukọ, awa mọ̀ pe iwọ jẹ́ olùṣòtítọ́ iwọ sì ńkọ́ni ni ọ̀nà Ọlọrun ni otitọ, iwọ kò sì bikita fun ẹnikẹni, nitori iwọ kìí wò ìrísí ode awọn eniyan. Nitori naa, sọ fun wa, Ki ni iwọ rò? Ó ha bófinmú lati san owó-orí fun Kesari tabi bẹẹkọ?”

Àpọ́nlé naa kò mú Jesu hùwà bí òmùgọ̀. Ó mọ pe bí oun bá sọ pe, ‘Bẹẹkọ, kò bófinmu tabi tọ̀nà lati san owó-orí yii,’ oun yoo jẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ sí ijọba Roomu. Sibẹ, bí oun bá wipe, ‘Bẹẹni, ẹyin nilati san owó-orí yii,’ awọn Juu, tí wọn ńtẹ́ḿbẹ́lú ìtẹ̀lóríba wọn fun Roomu, yoo koriira rẹ̀. Nitori naa ó dahun pe: “Eeṣe ti ẹ fi ńdán mi wò, ẹyin àgàbàgebè? Ẹ fi ẹyọ-owó kan hàn mi.”

Nigba ti wọn mú ọ̀kan wá fun un, ó beere pe: “Àwòrán ati àkọlé ta ni eyi?”

“Ti Kesari ni,” ni wọn fèsìpadà.

“Nitori naa, ẹ san awọn ohun ti Kesari padà fun Kesari, ṣugbọn awọn ohun ti Ọlọrun fun Ọlọrun.” Tóò, nigba ti awọn ọkunrin wọnyi gbọ idahun titayọlọla yii, ẹnu yà wọn. Wọn lọ kuro wọn sì fi i silẹ jẹ́jẹ́.

Ní rírí ìkùnà awọn Farisi lati rí ohun kan lodisi Jesu, awọn Sadusi, tí wọn sọ pe ajinde kò sí, sunmọ ọn wọn sì beere pe: “Olukọ, Mose wipe, ‘Bí ọkunrin eyikeyii kan bá kú láìní awọn ọmọ, arakunrin rẹ̀ gbọdọ gbé aya rẹ̀ ni iyawo kí ó sì gbé ọmọ-inú dide fun arakunrin rẹ̀.’ Nisinsinyi awọn arakunrin meje ti wà lọ́dọ̀ wa; ekinni sì gbéyàwó o sì kú, bí ko sì ti ní ọmọ, o fi aya rẹ̀ silẹ fun arakunrin rẹ̀. Ó ṣẹlẹ̀ ni ọ̀nà kan naa pẹlu sí ekeji ati ẹkẹta, títí dé ọ̀dọ̀ awọn mejeeje. Ní ikẹhin gbogbo wọn obinrin naa kú. Nitori naa, ní ajinde, aya ti ta ni yoo jẹ́ ninu awọn mejeeje? Nitori gbogbo wọn ti fẹ́ ẹ.”

Ní fífèsìpadà Jesu wipe: “Eyi ha kọ ni ìdí ti ẹyin fi ṣe àṣìṣe, mímọ̀ tí ẹ kò mọ̀ Iwe Mimọ tabi agbára Ọlọrun? Nitori nigba ti wọn bá dide kuro ninu òkú, awọn ọkunrin kìí gbéyàwó bẹẹni a kìí fi awọn obinrin funni ni ìgbeyàwó, ṣugbọn wọn dabi awọn angẹli ninu awọn ọ̀run. Ṣugbọn niti awọn òkú, pe a ńgbé wọn dide, ẹyin kò ha ti kà ninu iwe Mose, ninu àkọsílẹ̀ nipa igbó ẹ̀gún, bí Ọlọrun ti wi fun un pe, ‘Emi ni Ọlọrun Aburahamu ati Ọlọrun Isaki ati Ọlọrun Jakọbu’? Oun jẹ́ Ọlọrun, kìí ṣe ti awọn òkú, bikoṣe ti awọn alààyè. Ẹyin ṣe àṣìṣe pupọ.”

Lẹẹkan sii awọn ogunlọgọ naa ni háà ṣe sí idahun Jesu. Koda diẹ lara awọn akọ̀wé òfin jẹ́wọ́ pe: “Olukọ, o sọ̀rọ̀ daradara.”

Nigba ti awọn Farisi rí i pe Jesu ti pa awọn Sadusi lẹnu mọ́, wọn tọ̀ ọ́ wá ni awujọ kanṣoṣo. Lati dán an wò siwaju sii, akọwe ofin kan ninu wọn beere pe: “Olukọ, ewo ni òfin tí ó tobi julọ ninu Ofin?”

Jesu fèsì pe: “Ekinni ni, ‘Gbọ, Óò Isirẹli, Jehofa Ọlọrun wa Jehofa kan ni, iwọ sì gbọdọ nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ ati pẹlu gbogbo ọkàn rẹ ati pẹlu gbogbo èrò-inú rẹ ati pẹlu gbogbo okun rẹ.’ Ekeji ni eyi, ‘Iwọ gbọdọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ̀ gẹgẹ bi araarẹ.’ Kò si òfin miiran tí ó tobi ju iwọnyi.” Nitootọ, Jesu fikun un pe: “Lori òfin meji wọnyi ni gbogbo Òfin rọ̀ mọ́, ati awọn Wolii.”

“Olukọ, iwọ wi daadaa ni ibamu pẹlu otitọ,” ni akọ̀wé òfin naa gba. “‘Oun jẹ Ọ̀kan, kò sì sí ẹlomiran ju Oun lọ’; ati nínífẹ̀ẹ́ rẹ̀ yii pẹlu gbogbo ọkàn-àyà ẹni ati gbogbo òye ẹni ati pẹlu gbogbo okun ẹni ati nínífẹ̀ẹ́ aládùúgbò ẹni yii gẹgẹ bi ara-ẹni ṣeyebíye pupọ jìnnà jù gbogbo ọrẹ ẹbọ sísun ati awọn ẹbọ.”

Ní mímọ̀ pe akọ̀wé òfin naa ti dahun pẹlu ọgbọ́n, Jesu sọ fun un pe: “Iwọ kò jinna sí ijọba Ọlọrun.”

Fun ọjọ́ mẹta nisinsinyi—Sunday, Monday, ati Tuesday—Jesu ti ńkọni ni tẹmpili. Awọn eniyan naa ti fetisilẹ si i pẹlu idunnu, sibẹ awọn aṣaaju isin ńfẹ́ lati pa á, ṣugbọn titi di àkókò yii ìsapá wọn ni a ti mú jákulẹ̀. Matiu 22:15-40; Maaku 12:13-34; Luuku 20:20-40, NW.

▪ Rìkíṣí wo ni awọn Farisi pète lati fi mú Jesu, ki ni yoo sì yọrisi bí oun bá nilati funni ni idahun bẹẹni tabi bẹẹkọ?

▪ Bawo ni Jesu tún ṣe peékan ìgbìdánwò awọn Sadusi lati mú un?

▪ Ìgbìdánwò siwaju sii wo ni awọn Farisi ṣe lati dán Jesu wò, kí sì ni àbárèbábọ̀ rẹ̀?

▪ Lakooko iṣẹ́-òjìṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ̀hìn ni Jerusalẹmu, ọjọ́ meloo ni Jesu fi kọni ni tẹmpili, pẹlu iyọrisi wo sì ni?