Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Yíya Ọkà ní Sabaati

Yíya Ọkà ní Sabaati

Orí 31

Yíya Ọkà ní Sabaati

LÁÌPẸ́ Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fi Jerusalẹmu silẹ lati padà sí Galili. Ìgbà ìrúwé ni, awọn ṣírí ọkà sì yọ lára awọn pòròpórò ní pápá. Ebi ńpa awọn ọmọ-ẹhin. Nitori naa wọn ya ọkà wọn sì jẹ ẹ́. Ṣugbọn niwọn bi ó ti jẹ́ Sabaati, ohun ti wọn ṣe kò lọ láìkíyèsí.

Awọn aṣaaju isin ní Jerusalẹmu ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ọ̀nà lati pa Jesu fun ẹ̀sùn riru òfin Sabaati. Nisinsinyi awọn Farisi mú ẹ̀sùn kan wá. “Wòó! Awọn ọmọ-ẹhin rẹ ńṣe eyi tí kò bá òfin mu ní sabaati,” ni wọn fi wọn sùn.

Awọn Farisi sọ pe jíjá ọkà ati fífi awọn ọwọ́ ra á lati jẹ jẹ́ kíkórè ati pípakà. Ṣugbọn itumọ wọn aláìgbagbẹ̀rẹ́ niti ohun tí ó pilẹ̀jẹ́ iṣẹ́ ti sọ Sabaati di ẹrù ìnira, nigba tí ó jẹ́ pe ohun tí a nílọ́kàn ni pe kí ó jẹ́ àkókò aláyọ̀ ti o sì ńgbéniró nipa tẹ̀mí. Nitori naa Jesu fi awọn apẹẹrẹ Iwe Mimọ takò ó lati fihàn pe Jehofa Ọlọrun kò pete irúfẹ́ ìfisílò lilekoko aláṣejù kan bẹẹ fun òfin Sabaati rẹ̀.

Jesu sọ pe nigba ti ebi ńpa Dafidi ati awọn ọkunrin rẹ̀, wọn dúró níbi àgọ́-ìsìn wọn sì jẹ awọn ìṣù burẹdi ìmúwá síwájú. Awọn ìṣù burẹdi wọnni ni a ti gbé kúrò ní iwaju Jehofa tẹ́lẹ̀ tí a sì fi awọn ti a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe rọ́pò wọn, eyi tí ó sì jẹ́ pe bí ó ti saba maa ńjẹ́ a maa ńfi wọn pamọ́ de awọn alufaa lati jẹ. Sibẹ, lábẹ́ awọn àyíká ipò naa, Dafidi ati awọn ọkunrin rẹ̀ ni a kò dá lẹ́bi fun jíjẹ wọn.

Ní pípèsè apẹẹrẹ miiran, Jesu sọ pe: “Ẹyin kò ha ti kà á ninu Òfin pe ní awọn sabaati awọn alufaa tí nbẹ ninu tẹmpili lo sabaati bí eyi tí kii ṣe mímọ́ wọn sì ńbá a nìṣó láìjẹ̀bi?” Bẹẹni, àní ní Sabaati pàápàá awọn alufaa nbaa lọ lati maa kun awọn ẹran ati lati maa ṣe awọn iṣẹ́ miiran ní tẹmpili ní mimura irubọ ẹran silẹ! “Ṣugbọn emi sọ fun yin,” ni Jesu wí, “pe ohun tí ó tóbi jù tẹmpili wà níhìn-ín.”

Ní ṣíṣí awọn Farisi létí, Jesu nbaa lọ: “Ìbáṣepé ẹyin ti lóye ohun tí eyi tumọsi, ‘Emi fẹ́ àánú, kìí sìí ṣe ẹbọ,’ ẹyin kì bá ti dá awọn aláìjẹ̀bi lẹ́bi.” Lẹhin naa ni ó pari ọ̀rọ̀ rẹ̀ pe: “Nitori Oluwa sabaati ni ohun tí Ọmọkunrin ènìyàn jẹ́.” Ki ni ohun tí Jesu ní lọ́kàn pẹlu iyẹn? Jesu ńtọ́kasí ìṣàkóso Ijọba rẹ̀ alalaafia ti ẹgbẹ̀rún ọdun.

Fun 6,000 ọdun bayii, ìran eniyan ti ńjìyà ìsìnrú rírorò lábẹ́ Satani Eṣu, pẹlu ìwà-ipá ati ogun tí ó ti di àṣà ìgbàlóde. Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, ìṣàkóso Sabaati ńlá ti Kristi yoo jẹ́ àkókò isinmi kan kuro lọwọ gbogbo irúfẹ́ ìjìyà ati ìnilára bẹẹ. Matiu 12:1-8; Lefitiku 24:5-9; 1 Samuẹli 21:1-6; Numeri 28:9; Hosea 6:6.

▪ Ẹ̀sùn wo ni wọn fi kan awọn ọmọ-ẹhin Jesu, bawo sì ni Jesu ṣe dáhùn rẹ̀?

▪ Ìkùnà awọn Farisi wo ni Jesu fihàn?

▪ Ní ọ̀nà wo ni Jesu gbà jẹ́ “Oluwa sabaati”?