Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Yíyan Awọn Apọsiteli Rẹ̀

Yíyan Awọn Apọsiteli Rẹ̀

Orí 34

Yíyan Awọn Apọsiteli Rẹ̀

ÓTI tó nǹkan bíi ọdun kan ati aabọ lati ìgbà tí Johanu Arinibọmi ti sọ ẹni tí Jesu jẹ́ gẹgẹ bi Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọrun tí Jesu sì bẹrẹ iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ ní gbangba. Ní àkókò yẹn Anderu, Simoni Peteru, Johanu, ati boya Jakọbu (arakunrin Johanu), ati bakan naa Filipi ati Nataniẹli (ẹni tí a tún ńpè ní Batolomiu), ti di awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ àkọ́kọ́. Laipẹ ọ̀pọ̀ awọn miiran darapọ̀ mọ́ wọn ní títẹ̀lé Kristi.

Nisinsinyi Jesu múratán lati ṣàṣàyàn awọn apọsiteli rẹ̀. Awọn wọnyi yoo jẹ́ kòríkòsùn olùbákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tí oun yoo fun ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe. Ṣugbọn ṣaaju ṣiṣe àṣàyàn wọn, Jesu lọ sí òkè-ńlá kan ó sì lo gbogbo òru ní gbígbàdúrà, ó ṣeeṣe ki o maa beere fun ọgbọ́n ati ibukun Ọlọrun. Nigbati ilẹ̀ mọ́, ó pe awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ó sì yan awọn 12 ninu wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, niwọn bi wọn ti nbaa lọ lati jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Jesu, a ṣì ńpè wọn sibẹ ní ọmọ-ẹhin bakan naa.

Awọn mẹfa tí Jesu ṣàyàn, tí a dárúkọ wọn lókè, ni awọn tí wọn di ọmọ-ẹhin rẹ̀ àkọ́kọ́. Matiu, ẹni tí Jesu pè lati ibi iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ńgba owó orí, ni a ṣàyàn pẹlu. Awọn márùn-ún miiran tí ó yàn ni Judasi (ẹni tí a tún ńpè ní Tadeọsi), Judasi Isikariọtu, Simoni Onítara, Tomasi, ati Jakọbu ọmọkunrin Alfausi. Jakọbu yii ni a tún ńpè ní Jakọbu Kíkéré, boya nitori o ri kóńkóló jù ní ìrísí tabi kíkéré ní ọjọ́ orí ju apọsiteli Jakọbu keji.

Ni àkókò yii awọn 12 wọnyi ti wà pẹlu Jesu fun ìgbà diẹ, oun sì mọ̀ wọn dáadáa. Niti tootọ, ọ̀pọ̀ ninu wọn jẹ́ ìbátan tirẹ̀ fúnraarẹ̀. Jakọbu ati arakunrin rẹ̀ Johanu lọna tí ó hàn gbangba jẹ́ awọn mọ̀lẹ́bí Jesu. Alfausi ni ó sì ṣeeṣe kí ó jẹ́ arakunrin Josẹfu, baba alagbatọ Jesu. Nitori naa ọmọkunrin Alfausi, apọsiteli Jakọbu, pẹlu yoo jẹ́ mọ̀lẹ́bí Jesu.

Jesu, dajudaju, kò ní ìṣòro ní rírántí orukọ awọn apọsiteli rẹ̀. Ṣugbọn njẹ iwọ lè ranti wọn? Ó dára, ṣáà ti ranti pe awọn meji ni wọn ńjẹ́ Simoni, awọn meji ńjẹ́ Jakọbu, awọn meji sì ńjẹ́ Judasi, ati pe Simoni ní arakunrin kan Anderu, Jakọbu sì ní arakunrin kan Johanu. Iyẹn ni kọ́kọ́rọ́ lati maa fi ranti awọn apọsiteli mẹjọ. Awọn mẹrin yooku ní ninu agbowó-orí kan (Matiu), ẹnikan tí ó wá ṣiyèméjì lẹ́hìn-ò-rẹ̀hìn (Tomasi), ẹnikan tí a pè lati abẹ́ igi (Nataniẹli), ati ọ̀rẹ́ rẹ̀ Filipi.

Mọkanla ninu awọn apọsiteli naa wá lati Galili, àgbègbè ilé Jesu. Nataniẹli wá lati Kana. Filipi, Peteru, ati Anderu wá lati Bẹtisaida ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, nigba tí ó ya Peteru ati Anderu ṣílọ sí Kapanaomu, níbi tí ó farahàn pe Matiu ńgbé. Jakọbu ati Johanu nṣe iṣẹ́ ẹja pípa ó sì jọ pe wọn gbé ní tabi nítòsí Kapanaomu. Ó jọ pe Judasi Isikariọtu, ẹni tí ó da Jesu nikẹhin, ni apọsiteli kanṣoṣo naa tí ó wá lati Judia. Maaku 3:13-19; Luuku 6:12-16.

▪ Awọn apọsiteli wo ni wọn ti lè jẹ́ ìbátan Jesu?

▪ Awọn wo ni apọsiteli Jesu, bawo sì ni iwọ ṣe lè ranti orukọ wọn?

▪ Lati àgbègbè wo ni awọn apọsiteli naa ti wá?